Ń kò padà sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, ipò gómìnà ìpínlẹ́ Ogun ni ojú mi wá - Iyabo Obasanjo

Aworan Iyabo Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọmọ ile igbimọ aṣofin nigba kan ri, Ọjọgbọn Iyabo Obasanjo ti wọgile erongba awọn kan ti wọn ni o fẹ pada si ile igbimọ aṣofin agbaNaijiria.

O fidi rẹ mulẹ o ṣeeṣe ki irinajo oṣelu gbe lọ lati dije fun ipo gomina ipinlẹ Ogun.

Obasanjo, ọmọ aarẹ orilẹede Nigeria nigba kan ri, Olusegun Obasanjo lo ṣo eyi di mimọ lasiko to n sọrọ lori redio, nibẹ lo ti fidi rẹ mulẹ pe oun ti pada si ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress.

O sọ, "Fun ilọsiwaju, n ko ni di kọmisana. Gẹgẹ bi mo ṣe ti sọ, n ko pada si ẹgbẹ oṣelu kana nitori mo gbagbọ ẹgbẹ naa ti dagba, ti ko si ni iwulo mọ. Bẹẹni, n ko pada si ile igbimọ aṣofin agba naa.

"Bi awọn ara Amẹrika ẹ ma n sọ, ko ni iwulo. Eyi ni mo sọ fun awọn eeyan mi, nigba ti gbogbo eyi bẹrẹ, ohun kan ti mo pada wa fun ni ipo gomina.

"A ti bẹrẹ irinajo naa, A o si ba de opin nitori a ko fi ọwọ kekere mu ọrọ yii."

Kọmisana fun eto ilera nigba kan ri nipinlẹ Ogun ni ipadabọ rẹ sinu oṣelu lo da lori ipe lati ọdọ awọn ololufẹ rẹ ti wọn kesi pe ko ma pada bọ.

Aipẹ yii ni Obasanjo darapọ ẹgbẹ oṣelu APC, to si kede rẹ sita fun araye.

Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party nipinlẹ Ogun, to jẹ ẹgbẹ ti Ọbasanjo wa tẹlẹ ni wọn ti kọ lẹta si I pe awọn fi Ọlọrun sin ninu irinajo rẹ tuntun.

Obasanjo pada sidi oṣelu lẹyin ọdun mẹdogun to ti fi oṣelu silẹ lẹyin to pari saa rẹ gẹgẹ bii ọmọ ile igbimọ aṣofin laarin ọdun 2007 si 2011.

Bakan naa lo jẹ kọmisana fun eto ilera, ko to di pe o morile ile igbimọ aṣofin agba Naijiria, lẹyin naa lo gba Amẹrika lọ lati fi imọ kun imọ rẹ .