Ṣé lóòótọ́ ni Amẹrika ń sọ̀rọ̀ lórí pínpín Naijiria nítorí ìṣekúpani àwọn Kristẹni? Àlàyé rèé

Oríṣun àwòrán, Nuhu Ribadu/X/Rep. Riley Moore/X
Aṣoju-ṣofin orilẹede Amẹrika, Riley Moore, to wa lara awọn aṣofin Amẹrika to n ba ijọba orilẹede Naijiria sọrọ lori ọna ati fopin si iṣekupani awọn kristẹni ni Naijiria ti sọ pe bi isẹkupani awọn kristẹni yoo ti dopin lo jẹ Amẹrika logun kii ṣe pinpin Naijiria.
Aṣofin Moore to fọrọ naa lede loju opo X rẹ ṣalaye pe oun ti rinrin ajo wa si Naijiria lati ṣe ipade pẹlu awọn aṣoju ijọba, awọn ijọ Ọlọrun ati oniruuru ẹgbẹ kaakiri Naijiria.
Moore sọ pe oun tun ṣabẹwo si agọ awọn ogunlende ni Naijiria mọ ipa ti inunibini sawọn kristẹni ni lori awọn ọmọlẹyin Kristi.
Aṣofin Moore sọ pe pinpin orilẹede Naijiria ko saba jẹyọ ninu gbogbo ijiroro atawọn ipade toun ṣe ni Naijiria.
Ọgbẹni Moore sọ pe ṣiṣe atilẹyin fawọn to n pe fun iyakuro lara Naijiria jẹ nnkan to n bawọn kristẹni lọkan jẹ papaa julọ lẹkun ariwa ati aaringbungbun orilẹede Naijiria.
''Ti orilẹede Naijiria ba daru, awọn agbesunmọmi yoo ni igboya lati maa ṣiṣẹ laabi wọn.
Eyi yoo si mu ewu dani fawọn kristẹni ni Naijiria ati kaakiri ilẹ Afirika.
Mi o ni kaarẹ akitiyan mi lati ri pe aabo to peye wa fawọn kristẹni ati fun gbogbo ọmọ Naijiria ti ikọlu awọn agbesunmọmi n ṣakoba fun kaakiri Naijiria,'' Moore lo sọ bẹẹ.
Aṣofin Moore sọ pe orilẹede Amẹrika ati Naijiria ti jọ n ṣiṣẹ pọ lẹka eto aabo.
Moore ni igbesẹ yii ṣe pataki lati wa ojutuu si iwa ipa to n ṣẹlẹ ni Naijiria ati lati jẹ ki ibaṣepọ to wa laarin Naijiria ati Amẹrika gbopan si i.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post



























