Wo irúfẹ́ àwọn èèyàn tí ìjọba Saudi Arabia ti fàyè gbà láti maa ra ọtí mu báyìí

Eeyan meji gbe kọọbu ọti lọwọ lẹgbẹ ara wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba orilẹede Saudi Arabia ti bẹrẹ igbesẹ lati gbẹsẹ kuro lori ofin ti wọn fi de ọti tita ati mimu lorilẹede naa.

Ijọba ti bẹrẹ pẹlu fifi aye gbawọn ọlọrọ ọmọ ilẹ okeere lati le maa ra ọti mu bayii nilẹ naa.

Eyi ni igba akọkọ ti ẹnikẹni yoo lanfaani lati ra ọti lati ọdun 1952 ti ijọba ti fofin de ọti tita ati rira ni orilẹede naa.

Awọn kan gbagbọ pe awọn alaṣẹ Saudi si le gbawọn arinrin-ajo afẹ si orilẹede naa laye lati maa ra ọti mu.

Fun ọpọlọpọ ọdun ni ijọba Saudi ti fofin de ọti mimu lawọn olu ileeṣẹ orilẹede naa kaakiri agbaaye lati le pa ofin Saudi mọ.

Bo tilẹ jẹ pe ọdun 1952 ni ijọba Saudi fofin de ọti tita ati mimu ni orilẹede naa, awọn alaṣẹ ijọba ti gunle oniruuru eto atunṣe kan kawọn orilẹede agbaye le baa ri wọn bi ilu ti kii tẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ.

Fun apẹẹrẹ, ijọba ti paṣẹ ṣiṣi ile sinima pada, bakan naa ni ijọba tun ti sọ pe orilẹede naa yoo maa ṣagbatẹru ayẹyẹ orin kikọ pada labẹ ijọba Ori-ade Saudi Mohammed bin Salman.

Ijọba tun ti gbẹsẹ kuro lori ofin to fi de awọn obinrin pe wọn o le wakọ, o si tun ti din agbara awọn ọlọpaa hisba ku.

Amọ, gbigbẹsẹ kuro lori ofin ti ijọba fi de ọti mimu ati tita lawọn eeyan n sọ nipa rẹ julọ.

''Onibaara to ba fẹ ra ọti gbọdọ pa foonu rẹ ki o si fi pamọ sinu baagi ki wọn to gba a laye lati wọle''

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Loṣu Kinni ọdun 2024 ni wọn ṣi ile ọti kan niluu Riyadh, amọ, awọn ti kii ṣe musulumi atawọn aṣoju ilẹ okeere lo le ra ọti nibẹ.

Amọ labẹ ofin to ti bẹrẹ si ni ṣiṣẹ lati ipari ọdun 2025 bayii, awọn ọlọrọ ti kii ṣe musulumi ti lanfaani lati maa ra ọti nibi ti wọn ti n ta a bayii.

Alakalẹ ofin naa sọ pe ẹnikẹni to ba ni iwe igbeluu ti wọn n fi $27,000 gba gbọdọ fi ẹri han wi pe oun n gba owo oṣu ti ko din ni 50,000 riyals owo Saudi loṣu.

Ọpọ awọn onibaara to ti ra ọti ni ṣọọbu ti wọn ti n ta ọti naa ba BBC sọrọ, ṣugbọn wọn o darukọ ara wọn.

Onibaara to ba fẹ ra ọti nibẹ gbọdọ kọkọ pa foonu rẹ ki o si pamọ sinu baagi ki wọn to gba a laye lati wọle.

Ọmọ ile Gẹẹsi kan to ba BBC sọrọ ṣalaye pe iye ti wọn n ta ọti ni ṣọọbu naa wọn ju iye tawọn eeyan n ra a lọ nilẹ Yuroopu.

Ẹsin Islam ko faye gba ọti mimu ati fifi eeyan ṣe kata-kara, awọn itọni Islam yii si lawọn eeyan Saudi n tẹle.

Amọ, fifi eeyan ṣe kata-kara ti n ṣẹlẹ fun ọpọ ọdun ni Saudi bo tilẹ jẹ pe ijọba ilẹ naa fofin de e.

Ijọba Saudi ti mu ọrọ irin-ajo afẹ ni ọkunkundun bayii lati le jẹ ki ẹka mii yatọ si epo rọbi le maa pawo wọle.

Bi owo epo se walẹ laipẹ yii lọja agbaaye jẹ ki adinku ba owo to n wọle fun ijọba Saudi Arabia tori epo rọbi nikan ni koko nnkan ọrọ aje wọn.