Mọ̀ nípa àṣẹ tuntun tí ilé ẹjọ́ pa lórí àyẹ̀wò DNA fún Liam ọmọ Mohbad

Ile ẹjọ gíga to wa ni Ikorodu nipinlẹ Eko ti pàṣẹ pé kí wọn lọ ṣe ayẹwo DNA lọna mẹta nilẹ okeere lati le mọ bo ya akọrin takasufe to ti dolóògbé, Ilerioluwa Aloba, t'awọn eeyan mọ sí Mohbad lo bi Liam ni toootọ.
Ilẹ ẹjọ pàṣẹ tuntun yii lẹyìn ede-aiyede to ṣẹlẹ laarin ẹbi Mohbad ati Wunmi to jẹ opo rẹ lori ọrọ ayẹwo DNA fún Liam.
Ọgbẹni Joseph Aloba farahan nile ẹjọ pẹlu agbẹjọro rẹ, Oladayo Ogungbe ẹni tó sàlàyé wi pe ede-aiyede wa lori ayẹwo DNA ti ilẹ ẹjọ pàṣẹ pé kí wọ́n lọ ṣe tẹlẹ.
Ọgbẹni Joseph Aloba farahan nile ẹjọ pẹlu agbẹjọro rẹ, Oladayo Ogungbe ẹni tó sàlàyé wi pe ede-aiyede wa lori ayẹwo DNA ti ilẹ ẹjọ pàṣẹ pé kí wọ́n lọ ṣe tẹlẹ.
Agbẹjọro Ogungbe ṣalaye pe ile ẹjọ pàṣẹ kí wọn lọ ṣe ayẹwo DNA ọhun nilẹ okeere ko ma ba si eeru kankan níbẹ.
O ni ẹbi Mohbad yoo sọ ìbí kan ninu ibi mẹta ti wọn yoo ti ṣe ayẹwo naa, iyawo Mohbad naa yóò sọ ibomiran nigba ti ile ẹjọ yóò sọ ibi kẹta ti wọn yoo ti ṣe ayẹwo naa.
Ọgbẹni Ogungbe sọ pe "esi kan naa ni ayẹwo DNA mẹtẹẹta gbọdọ ni.
Nnkan ti a tí n beere fun lati ibẹrẹ ẹjọ naa niyii, eyi to tumọ si pe a ko ni ohunkohun lati fi pamọ́.''
Agbẹjọro Ogungbe fikun ọrọ rẹ pe kii ṣe baba Mohbad lo máa sanwo fun awọn ayẹwo ọhun.
Bakan naa lo tun sọ pe gbogbo eeyan tọrọ naa kan ni yóò wa nibi ti wọn yóò ti ṣe DNA naa, ko ma baa sí eeru níbẹ.
Ẹwẹ, baba Mohbad ni aṣẹ ile ẹjọ lori ọrọ naa tẹ oun lọrun.
Ni gbogbo igba ti Wunmi ba ti n sọ pe Mohbad loun bi Liam fun ní naa baba oloogbe maa n sọ pe awọn ni lati ṣe ayẹwo DNA fún ọmọkunrin naa lati ri aridaju pe Mohbad lo bi i ni toootọ.
Adajọ ti wa sun igbejọ sọjọ kẹwaa oṣù Kejì yìí.
Ti ẹ o bá gbàgbé, ọjọ Kejìlá oṣù Kẹsan an ọdún 2023 ni Mohbad jade laye lẹni ọdun mẹtadinlogbọn.
Wọn kò sì tii sin oku rẹ titi di asiko yii.



























