Atiku, Bode George, ẹgbẹ oṣelu PDP, LP atawọn mii koro oju sawọn sẹnẹtọ lori atunṣe ofin idibo

Oríṣun àwòrán, President of the Senate/X
Lẹyin ọpọlọpọ atotonu, ile aṣofin agba l'Abuja ti fagile lilo ẹrọ kọmputa nikan lati kede esi idibo.
Awọn sẹnẹtọ kede igbesẹ yii lanaa Ọjọru nibi atunṣe ofin eto idibo orilẹede Naijiria ti ile jiroro le lori.
Igbesẹ naa fa awuyewuye nitori fifi ẹrọ kọmputa gbe esi idibo sita ni ọpọ gbagbọ pe o le dena eeru ninu eto idibo gbogbogbo ọdun 2027.
Awuyewuye lórí bí Ilé aṣòfin àgbà ṣe fagilé lílo ẹ̀rọ kọ̀mpútà fún èsì ìbò, aráàlú yarí
Nigba ti ile n gba ofin naa wọle, awọn sẹnẹtọ wọgile abala ọgọta, ẹka kẹta ofin naa eyi to sọ pe awọn oṣiṣẹ eleto idibo INEC gbọdọ lo ẹrọ kọmputa lati fi ko esi idibo jọ ati lati fi ranṣẹ.
Ohun to wa ninu ofin naa ni pe ajọ INEC gbọdọ lo ẹrọ kọmputa lati fi esi idibo latawọn ibudo idibo ranṣẹ sori atẹ IReV, lẹyin ti gbogbo awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu ati alakoso ajọ INEC to ṣagbatẹru eto idibo ba ti buwọlu esi idibo naa tan.
Amọ, ohun to wa ninu atunṣe ofin naa bayii ni pe oṣiṣẹ INEC to ṣagbatẹru eto idibo ni lati fi esi idibo ranṣẹ pẹlu orukọ awọn oludibo to forukọ silẹ, gẹgẹ bi alakalẹ ajọ INEC ṣe sọ.
Ile aṣofin agba tun fagile abala 22 ofin eto idibo Naijiria to sọ pe ẹwọn ọdun mẹwaa ni ijiya fun ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ pe n fi ibo ṣe kata-kara.
Ile sọ ijiya naa di ẹwọn ọdun meji, amọ, iru ẹni bẹẹ yoo maa san faini miliọnu marun un naira bayii, dipo miliọnu meji to wa ninu ofin naa tẹlẹ.
Awọn sẹnẹtọ tun buwọlu ẹrọ BVAS nikan fun iforukọsilẹ fun eto idibo ati fun ibo didi.
Bakan naa tun lawọn aṣofin tun fọntẹ lu kaadi idibo alalopẹ gẹgẹ bii ami idanimọ lawọn ibudo idibo.
Ki atunṣe yii to le di ofin, ile aṣoju-ṣofin l'Abuja ati ile aṣofin agba gbọdọ fẹnu ko lori atunṣe ofin naa ki wọn si fi ranṣẹ si Aarẹ Bola Tinubu fun ibuwọlu.
Atiku, Bode George, ẹgbẹ oṣelu PDP, LP atawọn mii koro oju sawọn sẹnẹtọ lori atunṣe ofin idibo
Ẹwẹ, igun Turaki ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, ẹgbẹ LP ati ẹgbẹ oṣelu APGA ti tako ile aṣofin agba lori bi wọn ṣe wọgile lilo ẹrọ kọmputa fun akojọpọ ati fun fifi esi idibo ranṣẹ sori atẹ IReV.
Igbakeji alaga gbogbogbo PDP tẹlẹ, Oloye Bode George ati eekan ninu ẹgbẹ APGA, Oloye Chekwas Okorie naa ti bu ẹnu ẹtẹ lu atunṣe ti ile aṣofin agba ṣe lori ofin eto idibo Naijiria.
Ninu ọrọ tiẹ, Igbakeji Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Atiku Abubakar, ṣapujuwe igbesẹ ile aṣofin agba gẹgẹ bii ọna lati ṣegbe lẹyin awọn oludije sipo ti wọn ba lori oye lọwọ lọwọ ninu eto idibo ọdun 2027.
Atiku ni ifasẹyin ni igbesẹ ile aṣofin agba yoo mu ba atunṣe ofin idibo Naijiria, ko si tun ni jẹ kawọn eeyan ni igboya ninu eto idibo mọ.
Ninu atẹjade ti oludamọran Atiku fi sita, Igbakeji Aarẹ tẹlẹ sọ pe ''lasiko ti ijọba awarawa kaakiri agbaaye n lo imọ ẹrọ lati ri pe eto oṣelu wọn fẹsẹ mulẹ daadaa, nibẹ ni ile aṣofin Naijiria ti n buwọlu ofin to faye gba ṣiṣe eeru ninu eto idibo.
Lilo ẹrọ kọmputa fun akojọpọ ati fun fifi esi idibo ranṣẹ dara tori yoo daabo bo eto idibo wa.
Yoo jẹ ki eeru ninu eto idibo dinku, eyi ni yoo si jẹ ki ero awọn oludibo wa si imuṣẹ.
Igbesẹ ile aṣofin lati fagile lilo ero kọmputa fun esi idibo tumọ si pe wọn o fẹ ki araalu mọ nnkan to n ṣẹlẹ nipa eto idibo ni Naijiria.
Ẹgbẹ oṣelu LP ni tiẹ sọ pe igbesẹ ile aṣofin tumọ si pe awọn aṣofin ti dalẹ araalu to dibo yan wọn.
Ẹgbẹ LP sọ pe igbesẹ yii wa lara awọn igbesẹ to buru julọ ti ile aṣofin agba ti gbe lati ọdun 1999 titi di akoko yii.
Ile aṣofin ko fagile lilo ẹrọ kọmputa fun akojọpọ esi idibo - Akpabio
Ẹwẹ, Aarẹ ile aṣofin agba l'Abuja, Sẹnẹtọ Godswill Akpabio, ti sọ pe ile aṣofin ko fagile lilo ẹrọ kọmputa fun akojọpọ esi idibo ninu atunṣe ofin eto idibo Naijiria ti wọn buwọlu l'Ọjọru.
Akpabio sọrọ yii lẹyin ti ile buwọlu ofin naa tan ti oniruuru eeyan si bẹrẹ si ni sọrọ lori nnkan ti wọn ṣe.
Aarẹ ile aṣofin ni aṣigbọ wa ninu ikede ti ile ṣe, o ni awọn aṣofin ko wọgile lilo ẹrọ kọmputa fun akojọpọ esi idibo.
''Awọn eeyan ti bẹrẹ si ni sọrọ lori ayelujara pe ile aṣofin agba ti wọgile lilo ẹrọ kọmputa fun akojọpọ esi ibo.
Ko si ooootọ ninu ọrọ yii o, nnkan ti a ṣe ni pe a fontẹ lu ofin 2022 lori lilo ẹrọ kọmputa fun akojọpọ esi idibo.
Nitori naa, ẹ maa jọ kawọn eeyan ṣi yin lọna, ile aṣofin agba ti mo n dari yii ko tako lilo ẹrọ kọputa fun akojọpọ esi idibo.
Ohun to wu emi gan an ni pe ki a lo ẹrọ kọmputa fun eto idibo to n bọ,'' Akpabio lo sọ bẹẹ.



























