Akẹ́kọ̀ọ́ Fáṣítì méjì dèrò ọrùn lẹ́yìn ayẹyẹ ìgbaniwọlé nílé ìtura l'Ondo

Aworan Fasiti Adekunle Ajasin, nipinle Ondo

Oríṣun àwòrán, Adekunle Ajasin University/FB

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ayẹyẹ igbaniwọle si Fasiti Adekunle Ajasin, Akungba-Akoko, nipinlẹ Ondo to waye laipẹ yii ti pada di ibanujẹ fun ẹbi awọn akẹkọọ meji kan to dero ọrun lẹyin ti wọn ri anfaani lati di akẹkọọ ni fasiti naa.

Awọn akẹkọọ meji naa; Oludare Opeyemi, ẹni ọdun mejilelogun (22) ati Adegbola Blessing ẹni ọdun mokandinlogun (19) ni a gbọ pe wọn kopa ninu ayẹyẹ igbaniwọle ọhun.

Ajọyọ igbaniwọle naa ni wọn lọ ṣe nile itura kan, nibẹ ni wọn ni wọn ti wẹ ninu adágún omi (swimming pool). Iwẹ naa lo pada gba ẹmi lẹnu wọn bi iroyin ṣe wi.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ondo, DSP Abayomi Jimoh, sọ pe iṣẹlẹ naa waye ni asale ọjọ kọkandinlogbọn, oṣu kin-in-ni ọdun 2026.

Gẹgẹ bo se wi, Blessing ni wọn kọkọ ri ninu adagun omi naa, ti ko si mọ ibi to wa mọ rara, ni nnkan bii aago mẹjọ asalẹ ti wọn ri i.

Alukoro sọ pe sugbọn wọn doola ẹmi rẹ, o si ji pada, lẹyin eyi ni awọn ọrẹ rẹ mu un lọ sile.

DSP Jimoh ṣalaye pe kete lẹyin iṣẹlẹ yii ni wọn tun ri Oludare Opeyemi ninu odo kan naa ti wọn ti ri Blessing tẹlẹ, wọn si gbe e lọ sile iwosan kan ni Ikare-Akoko, nibi ti wọn ti kede pe o ti jade laye.

Lati mọ ohun to ṣẹlẹ gan-an, ileeṣẹ ọlọpaa pe adari ile itura naa, Ayomide Badejo ati ẹni to n bojuto adagun odo naa fun ifọrọwanilẹnuwo.

Ọrọ pada di wahala gẹgẹ bo ṣe wi, lẹyin tí Blessing ti wọn ti doola rẹ tẹlẹ tun pada ku ni owurọ ọjọ keji iṣẹlẹ naa.

Ni bayii, oku awọn akẹkọọ mejeeji ti wa ni ile igbokusi to wa nileewosan ilu Ikare-Akoko.

Alukoro sọ pe iwadii n tẹsiwaju lati mọ iru iku to pa awọn akẹkọọ naa.

Kí ni àwọn aláṣẹ Fáṣítì náà sọ?

Asoju BBC YORUBA kan si Alukoro Fasiti Adekunle Ajasin, Victor Akinpelumi lati mọ kulẹkulẹ ọrọ naa, ati igbesẹ ti wọn n gbe lori rẹ.

Ṣugbọn Akinpelumi ni oun ko ni ohunkohun lati sọ mọ lori ọrọ naa, nitori o ti wa lọwọ awọn ọlọpaa.

Alukoro fasiti naa sọ pe oun gbagbo pe awọn ọlọpaa yoo se iṣẹ wọn bii isẹ lati mọ ohun to pa awọn akẹkọọ yii nile itura ti wọn lọ.