Ọdún ìbílẹ̀ àwọn Ohori Ije wáyé ní Benin, Gẹ̀lẹ̀dẹ́ àti Ponsere gbòde

Iroyin ko to afojuba ni ayẹyẹ ọdun ibilẹ ti awọn ọmọ ilu Ohori-ije, lorilẹede Olominira Benin, fi ọjọ mẹta ṣe laipẹ yii, nibi ti wọn ti fi awọn aṣa ibilẹ ilu naa bii ijọ Gẹlẹdẹ, ijo Ponsere, ijo babalawo atawọn mi-in dara.
Ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 yii ni wọn bẹrẹ ayẹyẹ naa ni Isaba, wọn si pari rẹ si ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kan naa.
Yatọ si awọn ijo ibilẹ, awọn to fi ọ̀be dara nipa ṣiṣa ara wọn lọbẹ ko gbẹyin pẹlu.
Bawọn ọmọ Ohori-Ije to wa ni Naijiria ṣe walẹ ni awọn to wa loke okun ko gbẹyin pẹlu.



Nibi ayẹyẹ naa ni awọn Oriade to wa nikalẹ bii: Ọba Edun Solomon Adekoya (Awèlédé kéji) tilu Ohori-ije, Ọba Ilara;Mutiu Alani Adedimeji ti gba awọn ọmọ ilu nimọran lati maa wa sile deede.
Wọn ni ki wọn ri idagbasoke ilu naa bii ohun to gbọdọ jẹ wọn logun.
Bakan naa ni Minisita fun aṣa ibilẹ, Jean Michael Abimbola, ba awọn ọmọ Ohori-ije sọrọ lori ilọsiwaju ilu naa.
Alejo pataki mi-in to tun wa nikalẹ ni ni ọmọ ile igbimọ aṣofin; Ajibade Koussonda.

























