Ṣé lóòótọ́ ni wọ́n yìnbọn pa ọmọ Gaddafi, Saif al-Islam? Ohun tí a mọ̀ rèé

Saif al-Islam Gaddafi ni ọdun 2011

Oríṣun àwòrán, Reuters

    • Author, Nick Springate & Maia Davies
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Saif al-Islam Gaddafi, ọmọ olori orilẹede Libya nigba kan ri, Col Muammar Gaddafi, ni iroyin jade pe wọn yinbọn pa.

Iku ẹni ọdun mẹtalelaadọta, ẹni ti ọpọ ro pe yoo rọpo Baba rẹ, ni olori ẹgbẹ oṣelu rẹ fidi iroyin naa mulẹ lọjọ Isẹgun, gẹgẹ bii iwe iroyin Libyan News Agency ṣe gbe sita.

Agbẹjọro rẹ sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe igbimọ ẹlẹni mẹrin lo ṣekupa oloogbe ni ile rẹ to wa ni ilu Zintan, bo ti lẹ jẹ pe wọn ko ti fidi eeyan to wa lẹyin ikọlu naa mulẹ.

Ẹwẹ, ninu iroyin mii to tun yatọ, aburo oloogbe sọ fun ileeṣẹ momaran Libya pe oloogbe naa padanu ẹmi rẹ ni ala orilẹede Libya ati Algeria.

Saif al-Islam Gaddafi jẹ ilumọka eeyan ti ọpọ bẹru lẹyin baba rẹ, ẹni to jẹ olori orilẹede naa lati odun 1969 titi wọn fi ṣekupa ni ọdun 2011.

Wọn bi ọdun 1972, to si kopa nla ni orilẹede titi wọn fi gba ijọba lọwọ baba rẹ Gaddafi.

Lẹyin ti wọn yọ baba rẹ nipi, Saif al-Islam Gaddafi - ẹni ti wọn fi ọpọ ẹsun kan pe o kopa nla ninu awọn iwa kan to tako ijọba – dero ẹwọn fun ọdun mẹfa.

Ile ẹjọ agbaye fẹ fi ẹsun kan pe o wu iwa ibajẹ si eeyan kan ni ọdun 2011.

Ni ọdun 2015, ile ẹjọ ni ki wọn lọ ṣekupa ṣugbọn o pada gba itusilẹ lọwọ ologun Tobruk.

Gaddafi, nigba aye rẹ ni oun fi gba kankan fẹ jogun agbara baba rẹ, to si ma n sọ pe agbara ki n ṣe oko, ti eeyan n jogun.

Ẹwẹ ni ọdun 2021, o kede pe oun yoo jade dupo aarẹ ninu eto idibo, eyi ti wọn pada sun siwaju.