Bí eré bí àwàdà, Soludo fòpin sí 'Má jáde lọjọ Aje' ni Anambra

Oríṣun àwòrán, PATRICK MEINHARDT/AFP/GETTY IMAGES
Saaju ni Gomina Charles Soludo ti kede pe ko ni si gbé-ilẹ ẹ mọ nipinle Anambra ni eyi ti ọpọ sọ pe ko le waye bẹẹ nitori ẹru ati ipaya.
Gomina Soludo ni pe o to gẹ lori ọrọ 'Ma jade lọjọ Aje to ti n waye nipinle Anambra fun ọpọ ọdun sẹyin.
Awọn eeyna ko kọkọ bọ sita lati nkan bii aago mẹfa idaji, koda, ko si akẹkọọ kanakna ninu iwọnba ọkọ bọọsi akẹkọọ to jade sita to n rin ni titi.
Nigba ti o maa fi di bii aago mẹwaa arọ ni awọn perete n rin ni titi ninu ẹru ati ifoya, bẹẹ wọn ti awọn ṣọọbu kan pa sibẹ.
Kini o wa ṣẹlẹ lọsan ọjọ Aje ni ana?
Nigba ti aago mejila yoo fi lu ni awon ontaja kọọkan ti n fi igboya bọ sita nigba ti wọn ri awọn agbofinro ati eleto aabo to wa kaakiri ọja nla Onitsha Main Market.
Ko pẹ ko jina naa ni awọn miran n ṣilẹkun ṣọọbu wọn nigba ti wọn ri i pe ko si ẹni to n yọ awọn eeeyan lẹnu nibẹ mọ.
Gbogbo awọn to wa sibẹ wa ta ọja wọn lo tọwọ bọ iwe mo wa sita bi Gomina Soludo ṣe paṣẹ rẹ pẹlu aago ti onikaluku fi ọja silẹ lati fihan bi ẹri pe ko si nkankan to ṣe wọn nigab ti wọn wa na ọja.
Ogbeni Ikechukwu Obi, ọkan lara awọn ọlọja ti a ba sọrọ fi idunnu rẹ han, pẹlu ọpẹ si gomina Soludo pe ominira de si ipinle Anambra ati ilẹ Ibo lapapaọ pẹlu igbesẹ akin yii.
Gomina Soludo fi idunnu nla han si awon eniyan rẹ pe o dara bi ẹnikẹni ko ṣe le gba ọjọ Aje mọ ẹlomiran lọwọ mọ nipinlẹ Anambra.
Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan tó ti ọja Onitsha pa, Gomina Soludo pàṣẹ ṣíṣí rẹ̀ padà
Gomina ipinlẹ Anambra, Charles Soludo, ti paṣẹ ṣiṣi ọja nla ti a mọ si Onitsha Market pada lonii ọjọ Aje, ọjọ keji, oṣu Keji ọdun 2026, lẹyin ọsẹ kan to ti paṣẹ ki wọn ti i pa.
Ẹ o ranti pe ọjọ Aje to kọja ni Soludo paṣẹ pe ki wọn ti ọja Onitsha pa, pẹlu bi awọn ọlọja ibẹ ṣe fi aake kọri pe awọn yoo ṣaa maa fidi mọlẹ lọjọ Aje gbogbo ni, awọn ko ni I maa ṣi ṣọọbu.
Nnamdi Kanu, olori IPOB to n pe fun idasilẹ orilẹede Biafra ni eto jijoko sile lọjọ Aje yii tori rẹ bẹrẹ ni 2021, nigba ti awọn ọmọ ẹyin rẹ n pe fu ominira rẹ lẹyin ti ijọba mu un.
Awọn ipinlẹ ti ọrọ naa kan ju ni apa ilẹ Igbo ti wọn si maa n jokoo sile lọjọ Aje ni: Anambra, Imo, Enugu, Abia ati Ebonyi.
Bi wọn ba ṣi ṣọọbu, awọn ajinigbe ni wọn ni o maa n dọdẹ awọn, ti wọn maa n wọle ji awọn gbe, tabi ki wọn tilẹ pa awọn miran pẹlu.
Titi kan awọn ṣọọbu ati ile ẹkọ ni eto jijoko sile naa maa n kan, ati awọn oṣiṣẹ ijọba miran pẹlu.
Ohun ti Gomina Charles Soludo koro oju si ree to si ni kawọn ọlọja Onitsha dẹkun rẹ, ṣugbọn ti awọn eeyan naa taku pe awọn yoo ṣaa maa fi ọjọ Aje jokoo sile ni, nitori awọn ko le fi ẹmi awọn di isọro ai si aabo, ki wọn ma lọ gbe awọn pa.
Gomina Soludo paṣẹ titi ọjọ naa pa lọjọ Aje to kọja, o si ni ọsẹ kan gbako ni yoo fi wa bẹẹ.
''Ki i ṣe pe ko wuwa ka lọ si ọja lọjọ Aje, ẹru ijinigbe ati iku ojiji lo n ba wa''
Fun gbogbo ọsẹ to kọja ti ọja Onitsha fi wa ni titipa, ọpọ ọlọja lo mọ ọn lara ti wọn si padanu owo pẹlu aiṣilẹkun fun ọsẹ kan gbako.
Ọkan ninu wọn, Chimezie, sọ fun BBC pe ko din ni miliọnu kan naira ti oun n padanu lojumọ latari ai lọ si ọja.
O ni okoowo to yẹ koun ṣe pẹlu awọn onibaara tawọn jọ ni adehun ko ṣee ṣe rara.
Chimezie sọ pe to ba jẹ bi wọn ṣe ko awọn ọlọpaa wa si ọja Onitsha lasiko yii ni wọn n ṣe tẹlẹ ni, ko si ọlọja ti yoo bẹru, awọn ko ba maa ṣilẹkun lọjọ Aje gbogbo ni.
Ṣugbọn pẹlu adanu naa, wọn duro lori ipinnu wọn pe awọn ko ni i ṣilẹkun ni gbogbo ọjọ Aje, nitori ibẹru iku ojiji.
Latigba naa ni ọrọ yii ti di ohun ti araalu kaakiri n da si lori ayelujara, bawọn kan ṣe n sọ pe ọgbọn ni ọrọ awọn ọlọja naa gba, ki I ṣe titi ọja pa, bẹẹ ni awọn miran n sọ pe Soludo ko le ri ofin naa yipada pẹlu ilana titi ọja pa.
Ṣugbọn Gomina Soludo fi n da wọn loju pe aabo to peye wa fun wọn bi wọn ba bẹrẹ si I ṣilẹkun lọjọ Aje.
"A maa si ọja Onitsha lọjọ Aje, eto aabo to nipọn yoo si wa''

Oríṣun àwòrán, Anambra Police Command
Ninu atẹjade ti Kọmiṣanna eto iroyin l'Anambra, Law Mefor, fi sita lọjọ Aiku ana lo ti kede pe titi ọja pa fun ọsẹ kan naa ti wa sopin.
Atẹjade naa rọ awọn ọlọja lati pada sibi ọja wọn l'Onitsha, ki wọn si ma ṣe bẹru, wọn ni aabo to peye wa fun wọn.
Bi ẹnikẹni ba kẹẹfin ohun ibẹru kankan lọja, wọn ni ki wọn pe nọmba pajawiri ti I ṣe 5111 lati fi sùn.
"Eyi ni lati fi to gbogbo ilu leti, pe aṣẹ titi ọja Onitsha ti Gomina Soludo pa ti dopin lopin ọsẹ yii.
"Gbogbo ọlọja ni a paṣẹ fun lati bẹrẹ ọja pada lọjọ Aje, ọjọ keji, oṣu Keji ọdun 2026, nitori ko si ofin jokoo sile lọjọ Aje mọ nipinlẹ Anambra.
"A fi n da ẹyin eeyan Anambra loju pe aabo to peye wa fun yin, a si rọ yin ki ẹ fi ohun ti ẹ ba kẹẹfin nipa eto aabo to wa leti nipa lilo nọmba pajawiri 5111."
Yatọ si Gomina Soludo, bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Anambra paapaa fi n da awọn eeyan ilu naa loju pe aabo to peye wa fun wọn bi wọn ba bẹrẹ si I ṣiṣẹ wọn pada lọjọ Aje gbogbo.
Bakan naa lo ran awọn oṣiṣẹ ijọba ati awọn olukọ leti, pe ẹni ti ko ba ṣiṣẹ lọjọ Monde, ko ni I gbowo asiko ti ko fi ṣiṣẹ naa.
Ijọba tun rọ awọn obi lati jẹ kawọn ọmọ wọn pada sile ẹkọ lọjọ Aje, ki wọn ma baa rojọ labẹ ofin.
Ṣugbọn awọn ikọ to wa lẹyin eto jokoo sile lọjọ Aje yii naa ko yee leri pe bẹẹ ni yoo maa ri lọ. Koda, wọn ni ki ẹnikẹni ma ṣe jade lọjọ Aje oni ti ijọba ni oun yoo ṣi ọja Onitsha pada.
Agbẹnusọ ẹgbẹ IPOB, Emma Powerful, sọ ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Ẹti, pe bẹẹ ni awọn yoo maa fi ẹhonu han lọ.
BBC yoo maa fi to yin leti bo ba ṣe n lọ lọja Onitsha, ipinlẹ Anambra.


























