Ìdí rèé táwọn ọmogun 16 fi gbìmọ̀ pọ̀ láti dìtẹ̀ gbàjọba Ààrẹ Bola Tinubu - Ọ̀gágun Musa

Oríṣun àwòrán, Defence Headquarters/X
Minisita fun eto aabo ni Naijiria, Ọgagun fẹyinti Christopher Musa, ti ṣalaye idi tawọn ọmogun mẹrindinlogun fi gbimọ pọ lati ditẹ gbajọba Aarẹ Bola Tinubu.
Ọgagun Musa fidi ọrọ yii mulẹ lori eto Politics Tonight ileeṣẹ tẹlifan Channels lalẹ ọjọ Aiku tii ṣe ọjọ kinni oṣu Keji ọdun 2026 yii.
''Awọn ọmogun to gbimọ pọ lati gbajọba yii ko ni arojinlẹ rara ti a ba wo ipo ti gbogbo awọn to lọwọ ninu iditẹgbajọba to fori ṣanpọn naa wa.
Mi o mọ nnkan ti wọn n fori wọn ro to le mu wọn ro wi pe awọn lagbara lati ṣẹgun ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria.
Awọn ọmọ Naijiria gan an ti to lati kọju ija si wọn, lai tiẹ ti sọ nipa ileeṣẹ ọmogun rara.
Nnkan kan gbọdọ ṣẹlẹ ninu ọpọlọ wọn ki wọn to ji lọjọ kan lati ro pe awọn le doju ijọba awarawa bolẹ bayẹn,'' minisita eto aabo lo sọ bẹẹ.
Ọgagun Musa ṣalaye pe ọga agba ologun kan to ti de ipo ''Colonel'' lo bẹrẹ ọrọ naa.
O ni nitori wi pe ko ni igbega lẹnu iṣẹ lọ si ipo to kan lo jẹ ki o ronu iditẹgbajọba.
Minisita ni nnkan ti ọga agba ologun yii ṣe ni pe o wa awọn ọmogun mii tawọn naa ko ri igbega lẹnu iṣẹ gba tabi awọn ti ibi ti wọn gbe wọn lọ ko tẹ wọn lọrun.
O ni nnkan to dun oun ni pe ọga agba ologun naa ti ṣakoba fawọn ọmogun ọjẹwẹwẹ ti wọn ko mọ kulẹkulẹ ohun to ṣẹlẹ gan an.
Ọgagun Musa ni gbogbo wọn ni yoo foju wina ofin papọ bayii.
Minisita tun fikun ọrọ pe oun naa wa lara awọn tawọn ọmogun naa gbimọ pọ lati mu tabi lati ṣekupa ti iditẹgbajọba naa ba kẹsẹjari.
Wo ohun tuntun tí iléeṣẹ́ ológun ń sọ nípa àwọn ọmọogun tó gbìyànjú gbígba ìjọba lọ́wọ́ ọ Tinubu, ohun tójú wọn yóò rí
Laipẹ yii ni ileeṣẹ ologun Naijiria sọ wi pe àwọn ọmọogun to gbimọ pọ lati gbajọba naa yoo foju ba ile ẹjọ ologun lẹyin ti iwadii pari lori ẹsun iditẹgbajọba ti wọn fi kan wọn lọdun to kọja.
Eyi wa ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ologun Naijiria fi soju opo ayelujara rẹ pe ọmọ ogun mẹrindinlogun ni ọwọ tẹ ninu oṣu kẹwaa ọdun 2025, ti wọn si ti fi ẹsun iwa ibajẹ ati titapa sofin kan wọn.
Lọdun 2025, ileeṣẹ ologun kọkọ wogile iroyin nipa iditẹgbajọba ṣugbọn ọpọ iwadii, awọn alaṣẹ fidi iṣẹlẹ naa, ti wọn si jẹ ko di mimọ ọmọ ologun mẹrindinlogun yoo farahan ni ile ẹjọ.
Orilẹede Naijiria ni ọpọ itan to da lori ijọba ologun ati ijọba awarawa, ti ọpọ iditẹgbajọba si waye laarin ọdun 1966 si 1993, eyi lo fa ti ibẹrubojo ti wọpọ lọdun to kọja.
Ko ti han tabi daju iye awọn ọmọ ologun ti yoo foju ba ile ẹjọ ṣugbọn awọn alaṣẹ ileeṣẹ ni igbesẹ yii foju waye ni ilana ti ofin la kalẹ, lia si mọdaru.
Atẹjade naa fikun pe gbigbero lati gba ijọba lọwọ aarẹ ti ilu dibo yan tako ofin ati ilana ileeṣẹ ologun Naijiria.
Lọwọ yii lorilẹede Naijiria, iṣoro eto aabo ati ibinu araalu wọpọ, to si jẹ pe ohun lo n fa ti ọpọ iroyin ofege fi n lọ kiri pe awọn ọmọ ologun kan n gbero lati gba ijọba lọwọ Aarẹ to wa lode lasiko yii.
Ọdun 1999 ni o jẹ opin ijọba ologun lorilẹede Naijira, to si jẹ pe lati gba naa ni awọn ologun ti ni awọn yoo tẹriba fun ijọba awarawa.



























