Gbogbo àwọn olùjọ́sìn táwọn agbébọn jí gbé ní Kaduna gba ìtúsílẹ̀

Gómìnà Uba Sani ń rẹrin si ọmọdé kan, àwọn ọkùnrin márùn-ún ń pàtẹ́wọ́

Oríṣun àwòrán, UbaSani/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Àwọn olùjọ́sìn táwọn ajínigbé jí gbé níbi ìkọlù tí wọ́n ṣe sí ìlú Kurmin Wali ní ìpínlẹ̀ Kaduna ti gba ìtúsílẹ̀.

Àwọn olùjọ́sìn náà gba ìtúsílẹ̀ kúrò ní akata àwọn ajínigbé náà lẹ́yìn tí wọ́n lo ọ̀sẹ̀ mejì ní àhámọ́ àwọn ajínigbé náà.

Olórí ìlú Kurmin Wali, Ishaku Dan'azumi sọ fún BBC pé àwọn ọlọ́pàá ti sọ fún òun lọ́jọ́bọ̀, ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kejì, ọdún 2026 pé àwọn èèyàn náà ti moríbọ́ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé náà.

Ó ní òun yóò ṣe àbẹ̀wò sí ilé ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna láti lọ gba àwọn èèyàn náà.

Èyí ló ń wáyé lẹ́yìn táwọn olùjọ́sìn ọgọ́rin tó sá mọ́ àwọn ajínigbé náà lọ́wọ́ padà sílé wọn.

Ní oṣù Kìíní ọdún 2026 làwọn agbébọn ṣe ìkọlù sáwọn ilé ìjọ́sìn mẹ́ta ní ìlú Kurmin Wali ní ìpínlẹ̀ Kaduna tí wọ́n sì jí èèyàn 177 gbé lọ ṣùgbọ́n táwọn ọgọ́rin sá mọ́wọ lọ́wọ́.

Ààrẹ ẹgbẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi ní Nàìjíríà lẹ́kùn àríwá Nàìjíríà, Ẹniọ̀wọ̀ John Hayab náà fìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún BBC pe àwọn èèyàn náà ti gba ìtúsílẹ̀.

Ó ní òwúrọ̀ ọjọ́bọ̀ ni àwọn gba ìròyìn pé àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ti gba ìtúsílẹ̀ àwọn èèyàn náà.

Ó fi kun pé ṣáájú ni àwọn èèyàn náà ti wà pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò níbi tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú lẹ́yìn gbogbo ohun tí wọ́n là kọjá lákàtà àwọn ajínigbé.

Ó sọ pé ìgbésẹ̀ ti ń lọ láti lè jẹ́ káwọn èèyàn náà darapọ̀ mọ́ àwọn ẹbí wọn.

Ẹniọ̀wọ̀ Hayab wá dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọba àtàwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò fún ìgbésẹ̀ tí wọ́n gbé láti gba ìtúsílẹ̀ àwọn èèyàn náà.

Àtẹ̀jáde tí gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna, Uba Sani fi sórí ìkànnì X rẹ̀ lọ́jọ́rú sọ pé inú òun dùn pé àwọn èèyàn náà ti gba ìtúsílẹ̀.

Bákan náà ló tẹmpẹlẹmọ pé ]oun tib á minísítà fétò ààbò sọ̀rọ̀ láti pèsè ibùdó àwọn ọmọ ogun sí ìlú Kurmin Wali.

Olùjọ́sìn 80 móríbọ́ nínú 177 táwọn jàndùkú agbébọn jí gbé ní ṣọ́ọ̀ṣì mẹ́ta ní Kaduna

Awọn agbebọn to daṣọ boju gbe ibọn lọwọ, ati aga ijokoo to ti daru ninu ṣọọṣi

Oríṣun àwòrán, AFP/BBC

Ọgọrin ninu awọn olujọsin mẹtadinlọgọsan tawọn janduku agbebọn ji gbe lọ ni ṣọọṣi mẹta nipinlẹ Kaduna ti moribọ lọwọ awọn ajinigbe.

Ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna ṣalaye pe awọn olujọsin naa ti wọn ji gbe lawọn ṣọọṣi to wa lagbegbe Kurmin Wali ni igberiko Kaduna ti kuro lakata awọn ajinigbe.

Ọlọpaa ni lati ọjọ ti wọn ti jawọn olujọsin naa gbe ni wọn ti moribo lasiko tawọn ajinigbe naa n gbe wọn kaakiri.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna, DSP Mansur Hassan, sọ fun BBC pe awọn olujọsin ọgọrin naa sa pamọ sawọn abule kan lati igba ti wọn ti moribọ lọwọ awọn janduku ajinigbe lati ọjọ yii ni.

DSP Hassan ṣalaye pe awọn olujọsin naa farapamọ titi di asiko ti ko ni sewu fun wọn lati pada si ibugbe wọn ni.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn olujọsin naa ti lọ fun ayẹwo ara wọn nile iwosan.

Bakan naa ni o sọ pe gbogbo awọn olujọsin ọhun lo ti lọ ba ẹbi wọn bayii.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn yoo ri pe awọn doola eeyan mẹrindinlaadọrun to ku lakata awọn ajinigbe.

'Ìjọba fẹ́ pa wá lẹ́numọ́, wọn ní ka má sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù àwọn agbébọn tó jí èèyàn 177 gbé lọ ní ìlú wa'

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣáájú làwọn aráàlú Kurmin Wali ní ìjọba ìbílẹ̀ Kajuru, ìpínlẹ̀ Kaduna, níbi tí àwọn agbébọn ti jí èèyàn 177 gbé lọ́jọ́ Àìkú tó kọjá yìí, ti fẹ̀sùn kàn pé àwọn aláṣẹ ń gbìyànjú láti pa àwọn lẹ́nu mọ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Àwọn èèyàn náà sọ fún BBC lọ́jọ́rú, ọjọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kìíní, ọdún 2026 pé àwọn aláṣẹ ń sọ fún àwọn aráàlú pé kí wọ́n yé bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, tí wọn sì ń dènà àwọn akọ̀ròyìn láti wọ inú ìlú náà.

Aráàlú kan tí kò fẹ́ kí a dárúkọ òun nítorí ààbò sọ pé àwọn aláṣẹ ṣèkìlọ̀ fáwọn aráàlú pé wọn kò gbọdọ̀ sọ ohunkóhun lórí ìkọlù náà fáwọn akọ̀ròyìn kankan.

BBC náà kò tètè ríbi wọ inú ìlú Kurmin Wali nítorí àwọn agbófinró àtàwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tó wà láti wọ inú ìlú náà ní kí a padà àmọ́ tí wọ́n padà jẹ́ kí a wọnú ìlú náà nígbà tí ikọ̀ ìròyìn wa kọ̀ láti padà.

Àwọn tí wọ́n jí àwọn èèyàn gbé àtàwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn sọ pé inú ìbànújẹ́ àti ìbẹ̀rù làwọn aráàlú wà láti ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé nítorí àìsí ààbò tó péya fún wọn.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna, Uba Sani padà ṣe àbẹ̀wò sí ìlú Kurmin Wali lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta tí ìkọlù náà wáyé tó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ láti pèsè ibùdó àwọn ọmọ ogun sí agbègbè náà.

Bákan náà ló tún kéde láti pèsè àwọn ohun ìdẹ̀kùn fáwọn tí wọ́n lùgbàdì ìkọlù àwọn agbébọn náà tó fi mọ́ pípèsè ètò ìlera fún wọn.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá àtàwọn aláṣẹ ìjọba ìbílẹ̀ Kajuru ti kọ́kọ́ jiyàn pé ìkọlù kò wáyé ní ìlú Kurmin Wali, kí wọ́n tó yí ohun padà.