'Àwọn tó fẹ́ gbe Imam níjà lásìkò ti Najeem fẹ́ la gbohùngbohùn mọ́-ọn lórí ló lù ú pa'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni ọjọ Ẹti, ọgbọnjọ oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 ni iroyin kan gbode lori ọkunrin kan ti wọn fẹsun kan pe awọn olujọsin kan ni ipinlẹ lu ni alubami titi ẹmi fi bọ lọrun rẹ.
Gẹgẹ bi iroyin to gbode, ni mọṣalaṣi Ummu Haani Adigun, to wa ni agbegbe Ayedun Estate, agbegbe Ogo Oluwa, niluu Osogbo nipinlẹ Osun ni iṣẹlẹ naa ti waye.
Ọkunrin to di oloogbe naa ni wọn pe orukọ rẹ ni Najeem Hammed ti oun naa jẹ ọkan lara awọn janmọ to maa n kirun ni mọṣalaṣi naa.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, awọn olujọsin ẹgbẹ rẹ ni iroyin sọ pe wọn dawọ jọ lu ọkunrin naa pa lasiko irun idaji ta a mọ si Fajr, lori ẹsun pe Oloogbe naa da iwaasu Imam ru.
BBC News Yoruba kan si adugbo ti iṣẹlẹ ti naa ti waye ti ẹni ti iṣẹlẹ naa si ṣoju rẹ sọ fun wa pe Najeem Hammed lo kọkọ doju ija kọ Imaamu mọṣalaaṣi yii lasiko adura idaji, eyi si lo mu ki awọn to wa ni agbegbe naa pinnu lati gbe Imaamu nija.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nigba ti a de adugbo naa, niṣe ni gbogbo ibẹ pa lọlọ, ko fi bẹẹ si lilọ bibọ awọn eeyan, bakan naa ni awọn ọlọpaa wa ni gbogbo agbegbe naa lati ri daju pe ẹnikẹni ko da omi alaafia agbegbe naa ru.
Gẹgẹ bi ẹni ti ṣẹlẹ naa ṣoju rẹ, Arabinrin Lolade Adesina, ṣe ṣalaye, o ni ohun to da wahala silẹ ni pe inu Hammed ko dun si iwaasu Imaamu laaarọ ọjọ naa, o si gbagbọ pe oun ni baba naa n dọgbọn fi iwaasu rẹ bu, idi niyẹn to ṣe fẹ la irin gbohungbohun mọ ọn.
O sọ pe Najeem Hammed gbe irin ẹrọ gbohungbohun, to si fẹẹ jan an mọ Imaamu lori, ko to di pe baba Imaamu sare jade.
O ni lojiji ni awọn to wa ninu mọṣalaaṣi gbe Hammed bọ sita, ti wọn si bẹrẹ si ni lu u lalubami.
O fi kun pe bi iṣẹlẹ naa ṣe n lọ lawọn kan lọ fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti ni agọ ọlọpaa Ataọja Police Division.
Arabinrin naa tẹsiwaju pe awọn ọlọpaa lo gbe oloogbe naa lọ si agọ wọn nigba ti wọn de ṣugbọn nigba ti wọn ri wi pe, ẹmi ti fẹ bọ lẹnu rẹ, latari ọpọlọpọ iya ti wọn ti fi jẹ, wọn sare gbe e lọ si ile iwosan.
"Bi wọn ṣe gbe e de ile iwosan ni awọn dokita sọ fun wọn pe o ti dakẹ.
"Idi ti awọn mọlẹbi ati ọrẹ rẹ fi ya wọ inu mọṣaalaṣi lasiko irun Jimoh, ti ọrọ naa si di wahala nla."
Nigba to n fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oṣun, Abiọdun Ojelabi ni awọn ti nawọ gan awọn afurasi kan lori iṣẹlẹ naa, ti wọn si ti wa ni ahamọ.
Ojelabi ni iwadii ti bẹrẹ lati mọ bi ọrọ naa ṣe jẹ ati pe awọn ọlọpaa ti wa lagbegbe naa lati ri daju pe alaafia pada si agbegbe naa.
O fi kun pe gbe oku Hammed si ile igbokusi ti ile iwosan Fasiti ipinlẹ Osun. titi iwadii fi maa pari.
Niṣe ni mọṣalaṣi naa wa ni titipa lasiko ti a ṣe abẹwo sibẹ ti ko si si aaye fun irun kiki tabi eto adura kankan nibẹ.


























