Kwara: Ológun Naijiria yabo ibùba àwọn agbésùnmọ̀mí, gba àwọn tó wà nígbèkùn kalẹ̀

Awọn ologun nibuba awọn ajinigbe, ni Kwara. Ina n jo lapa kan ibẹ, bẹẹ ni ọpọ nnkan lo fọn silẹ kiri

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army

Àkọlé àwòrán, Awọn ologun nibuba awọn ajinigbe, ni Kwara
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria ti kede pe oun mu awọn ajinigbe kan balẹ nipinlẹ Kwara, bẹẹ ni awọn eeyan to wa nigbekun nibẹ gba ominira.

Ana ode yii ti i ṣe ọjọ Ẹti, ọgbọnjọ oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 ni ileeṣẹ ologun Naijiria fi eyi lede loju opo X wọn.

Adele Adari ikede nileeṣẹ ologun, (2 Division Nigerian Army) Ọgagun Maureen Ogbuka, lo buwọlu ikede naa.

Gẹgẹ bi atẹjade ọhun ṣe wi, awọn ikọ ologun '22 Armoured Brigade', pẹlu ajọṣepọ ọfiisi Oludamọran agba lori aabo ni Naijiria, ni wọn jọ ṣiṣẹ ọhun laarin ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kin-in-ni si ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kin-in-ni ọdun 2026.

Bawo ni wọn ṣe ri ajinigbe pa, gba awọn to wa nigbekun silẹ?

Awon ologun ninu igbo pẹlu awon obinrin meji

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army

Gẹgẹ bi alaye ileeṣẹ ologun ilẹ wa, yiyabo ibuba awọn ajinigbe naa ni wọn ṣe labẹ eto kan ti wọn pe ni Operation Igbo Danu.

Wọn fi kun un pe igbesẹ naa waye labẹ idari awọn ọga ologun Chinedu Nnebife ati Nicholas Rume.

"Ninu ikọlu naa, awọn ikọ wa doju kọ awọn agbebọn naa nipa yiyabo iho ti wọn fi ṣe ibuba, wọn si ri pupọ ninu wọn pa.

"Bakan naa ni awọn kan raye sa wọgbo lọ pẹlu ọta ibọn to ba wọn."

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bẹẹ ni apa kan atẹjade ileeṣẹ ologun Naijiria wi.

Wọn fi kun un pe ọpọlọpọ ibi ti awọn oniṣẹ ibi naa fi ṣe ibuba ni awọn ṣọja bajẹ pata.

Nipa agbegbe ti wọn ti koju awọn agbesunmọmi yii, atẹjade naa sọ pe Garin Dandi, nijọba ibilẹ Ifelodun ni. Wọn ni ibẹ ni ọpọ eeyan mọ si aaye kan ti awọn agbesunmọmi fi ṣe ibuba.

"Ikọ ologun tu Garin Dandi yẹbẹyẹbẹ, iyẹn aaye ti awọn agbebọn fi ṣe ibugbe nijọba ibilẹ ifelodun, eyi to fa iku ọpọ awọn agbesunmọmi naa, ti a si da oju eto wọn ru."

Ogbuka lo ṣalaye bẹẹ ninu atejade naa.

Yatọ si agbegbe naa, ileeṣẹ ologun tun ni ikọ naa tun de awọn jingun igbo ti awọn ẹṣọ alaabo ki I le de tẹlẹ.

Wọn ba gbogbo ibugbe awọn agbesunmọmi to wa nibẹ ti wọn ti kọti jẹ, wọn si di gbogbo ọna ti wọn n gba gbe nnkan ija wọle.

Bi igbo ọhun ṣe ṣoro lati wọ to, awọn ologun fọ gbogbo ibẹ bi atẹjade wọn ṣe wi, koda, wọn ni awọn ri awon kan mu ninu awọn agbesunmọmi to fẹẹ sa lọ.

"Ikọ ologun da awọn to fẹ salọ lọna bi wọn ṣe di ọna mọ wọn, eyi to jẹ ki wọn ri awọn agbebọn to fẹ sa lọ mu, nigba ti wọn gba ọpọ awọn to wa nigbekun kaakiri ibẹ silẹ."

Atẹjade ologun lo tẹsiwaju bẹẹ.

"Ileeṣẹ ologun ri ọwọ awọn agbẹyinbẹbọjẹ araalu to n ran agbesunmọmi lọwọ''

Alupupu kan to fẹgbẹ lelẹ ree lati ibudo naa

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army

Afikun kan ti ileeṣẹ ologun fi kun alaye rẹ ni pe o foju han pe awọn ara agbegbe naa kan n ya agbẹyinbẹbọjẹ, wọn ni wọn n pese iranwọ fun awọn agbesunmọmi.

"Iwoye wa lasiko iwọde yii fi han pe awọn agbesunmọmi n ri atilẹyin gba latọdọ awọn to n sọ bi awọn ẹṣọ alaabo yoo ṣe rin fun wọn.

"Eyi to n mu kawọn agbesunmọmi naa tete maa sa kuro kawọn ẹṣọ too debi ti wọn ti fọkan si pe awọn yoo ba wọn."

Atẹjade naa lo kede bẹẹ.

Wọn rọ araalu lati fọwọ sowọpọ pẹlu ileeṣẹ ologun, dipo awọn agbesunmọmi, lati le ran yiyabo ibuba agbesunmọmi to n lọ lọwọ.