Ohun méje tó ṣeéṣe kó wáyé tí Amẹrika bá ju àdó olóró sí Iran

Aarẹ Donald Trump ati adari Iran, Ayatollah Ali Khamenei

Oríṣun àwòrán, EPA

    • Author, Frank Gardner
    • Role, Security correspondent
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Pẹlu bi nnkan ṣe ri bayii, o dabii pe ijọba ilẹ Amẹrika ti n gbaradi lati ju ado oloro si orilẹede Iran laipẹ.

Bo tilẹ jẹ pe o rọrun lati sọ awọn ibi ti Amẹrika yoo ju awọn ado oloro naa si, o ṣoro lati sọ ohun ti yoo ti ẹyin rẹ yọ.

Ti ijọba orilẹede mejeji ko ba le fẹnuko lori ọna abayọ si ija to n rugbo bọ naa, ki ni ohun to le ṣẹlẹ ti Amẹrika ba fi ado oloro ranṣẹ si Iran?

1. Amẹrika yoo kọlu awọn ibi to ṣe pataki, araalu diẹ yoo ku, ijọba yoo pada sọwọ oloṣelu

Amẹrika yoo sọ ado oloro si ibuba awọn ọmọ ogun Islamic Revolutionary Guards Corps (IRGC) ati ẹka Basij.

Ijọba to wa lode yoo dojude ti agbara yoo si bọ si ọwọ oloṣelu.

Amọ ṣa, kii ṣe gbogbo ibi ti ologun Amẹrika lọ ni ijọba ti n pada sọwọ oloṣelu, bii Iraq ati Lybia ti iṣoro wọn tunbọ buru si ju ti atẹyinwa lọ.

Syria ti awọn funra gbe igbesẹ lati paarọ awọn adari wọn san ju awọn ilẹ ti Amẹrika kogun ja lọ.

2. Ijọba Iran yoo dojude amọ yoo ṣe atunṣe si awọn ohun to n ṣe

Eleyii le farajọ ohun to ṣẹlẹ ni Venezuela.

Fun Iran, Islamic Republic ko ni dawo, eyii ti ko ni dun mọ awọn eeyan ilẹ naa ninu amọ yoo jawọ atilẹyin rẹ fun awọn agbebọn kaakiri Middle East.

Amọ eyii yoo ṣoro diẹ nitori ijọba Islamic Republic ti wa lori oye lati ọdun bii mẹtadinlaadọta sẹyin.

3. Ijọba yoo dojude amọ ologun ni yoo gori alefa

Ọpọ lo gbagbọ pe ohun ti yoo ṣẹlẹ kẹyin ree.

Pupọ eeyan to n gbe nibẹ ni ko fẹran ijọba to wa lode amọ ti Amẹrika ba le ju ado oloro si Iran o ṣeeṣe ko jẹ pe ologun ni yoo pada maa tukọ orilẹede naa ni igbẹyin.

Ọlọpaa Iran

Oríṣun àwòrán, Getty Images

4. Iran yoo gbẹsan nipa jiju ado oloro si Amẹrika atawọn to fẹgbẹkẹgbẹ rẹ

Iran ti ṣelẹri tẹlẹ pe oun yoo da pada fun Amẹrika to ba ju ado oloro si oun.

Agbara ologun Iran ko to ti Amẹrika amọ oun naa ṣi le ta putu pẹlu awọn ohun ija oloro to ko pamọ si awọn aginju.

Ọpọ awọn orilẹede Arab to wa lẹyin Amẹrika ni ẹru ti n ba bayii pe awọn ni yoo jẹ eyii to ju ninu iya naa ti ogun ba bẹ silẹ laarin orilẹede mejeji.

Awọn olufẹhonuhan ni Iran

Oríṣun àwòrán, UGC

5. Iran yoo gbeṣan nipa riri ado oloro sabẹ omi okun lagbegbe Gulf

Ti eyii ba waye, yoo ṣoro fun awọn orilẹede mii lagbaye lati ko epo rọbi atawọn nnkan mii kọja lọ silẹ wọn.

Amọ ṣa, kii ṣe igba akọkọ ree ti ibẹru irufẹ ikọlu bayii ti n waye, o ti wa bẹẹ lati igba ogun Iran ati Iraq laarin ọdun 1980 si ọdun 1988.

Iran ti ṣe awọn igbaradi kan tẹlẹ ninu eyii to ti to awọn ado oloro sinu omi okun lagbegbe Gulf.

Maapu agbegbe Gulf

6. Iran yoo gbẹsan nipa riri ọkọ ologun ori omi Amẹrika sinu omi okun

Ọgagun ori omi ilẹ Amẹrika kan sọ lasiko kan pe ohun ti oun bẹru julọ ni akọlu Iran si ọkọ ori ologun Amẹrika lati ọwọ ijọba Iran.

Ti Iran ba ri ọkọ ori omi Amẹrika si isalẹmokun to si ko awọn ologun inu rẹ ni igbekun, eyii jẹ itiju nla fun ijọba ilẹ naa.

Bo tilẹ jẹ pe ọpọ lo gbagbọ pe eyii yoo ṣoro lati ṣe, amọ ẹgbẹ agbesunmọmi Al-qaeda ti kọlu irufẹ ọkọ bẹẹ, USS Cole ri lọdun 2000, to si pa gbogbo ọmọ ogun ori omi to wa ninu rẹ.

Obinrijn ẹlẹha to n rin lẹgbẹ aworan to lodi si ijọba Amẹrika

Oríṣun àwòrán, Anadolu via Getty Images

7. Ijọba Iran yoo dojude, gbogbo nnkan a dojuru

Nnkan yoo buru jọjọ ti ọrọ naa ba ri bayii ni ikẹyin, eyii si wa lara ohun to n ba orilẹede Qatar ati Saudi Arabia to fẹgbẹkẹgbẹ Iran lẹru.

Igbabọ wa pe ogun abẹle tun le waye gẹgẹ bo ṣe ri ni Syria.

Wayi o, ọwọ Aarẹ Trump ni gbogbo rẹ wa bayii; boya ko fopin si erongba rẹ ko si fi itiju karun tabi ko bẹrẹ ogun ti ko ni mọ ohun ti yoo gbẹyin rẹ.