"Ẹnikẹ́ni tọ́wọ́ bá tẹ̀ pé ó ń lo fọ́tò ìhòhò ọmọdé lórí ayélujará l'Eko, ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rìnlá ni ìjìyà rẹ̀"

Oríṣun àwòrán, Lagos state Government.
Bi oriṣiiriṣii eto ṣe gba ori ayelujara kan latọwọ awọn sọrọsọrọ loju opo ọlọkan-o-jọkan, ti awọn miran ninu wọn ko si mọ ofin to de iṣẹ ti wọn n ṣe ti wọn fi n pawo sapo ara wọn, debi ti wọn yoo tiẹ tẹle ilana tootọ, ijọba ipinlẹ Eko ti kilọ fun awọn ti tiwọn ni i ṣe pẹlu lilo ọmọde.
Ana ode yii ti i ṣe ọjọ Aje, ọjọ keji, oṣu Keji ọdun 2026 ni ijọba Eko jawe ikilọ fun awọn eeyan to n lo ọmọde lọna aitọ fi ṣeto lati dẹkun rẹ.
Ijọba ran wọn leti pe ẹwọn ọdun mẹrinla ni ofin la kalẹ fun ẹni to ba tẹ ẹtọ ọmọ ti ọjọ ori rẹ ko to nnkan mọlẹ nitori ati pawo sapo.
Ninu atẹjade to kede ikilọ yii, eyi ti Kọmiṣanna fun ọrọ ọdọ ati idagbasoke;Mobolaji Ogunlende ati Akọwe ajọ to n ri si ifiyajẹni labẹle, ibalopọ lọna aitọ, Titilola Vivour-Adeniyi, buwọ lu ni wọn ti kede ikilọ naa.
Wọn ṣalaye pe labẹ ofin Naijiria, lara awọn ti ofin gbọdọ da aabo bo ni awọn ọmọde wa.
Atẹjade naa sọ pe ẹnikẹni ko gbọdọ lo wọn fun ohun to tako aabo, alaafia ara ati ọkan wọn.
"Lilo awọn ọmọde fun ohun to ṣafihan ilokulo, ibalopọ tabi dida oju wọn kọ ohun to le pa wọn lara, lodi si ilana rere, bẹẹ naa lo si lodi si ofin to n de aabo ọmọde."
''Labẹ ofin Naijiria, ẹnikẹni to ba ṣe eto to jọ mọ ibalopọ fun ọmọde, to pin in sita tabi to ta a lodidi lati jere nibẹ, ti huwa ọdaran."
Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa ka.
Abala ofin to gbe ọrọ yii lẹsẹ pẹlu ijiya to wa fun un
Lati yanna-na ofin to de iwa ti ijọba Eko n kilọ rẹ yii, atẹjade naa ka awọn ofin to gbe e lẹsẹ nikọọkan.
Ijọba ipinlẹ Eko ni abala 25(1) ati 26 ofin ipinlẹ yii to wa fun ẹtọ awọn ọmọde, lodi si lilo ọmọ nilokulo.
Omiran ni abala 135–139 ati 141 ofin iwa ọdaran ipinlẹ Eko ti ọdun 2015, eyi to ṣalaye ni kikun nipa hihu iwa ọdaran nipasẹ ibalopọ fun ọmọ kekere.
Bakan naa ni abala 23 ofin to de iwa ọdaran lori ayelujara ti wọn ṣe ni 2015, ka lilo aworan ọmọde nihoho kun iwa ọdaran lori ayelujara, ati abala 24 rẹ naa to lodi si ki eeyan maa dọdẹ ẹlomiran lori ayelujara ati ki eeyan maa fi abuku kan wọn.
Abala 32 ofin to n da aabo bo ẹtọ ọmọde lo la ẹwọn ọdun mẹrinla kalẹ fun ẹnikẹni to ba ṣe ọmọde baṣubaṣu nipasẹ ibalopọ tabi ifẹkufẹẹ ara, tabi ki eeyan fi ẹtan mu ọmọde ṣe ohun ti ko fẹ.
"A maa tẹsiwaju lati maa ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ti ọrọ yii kan, bẹẹ ni a o maa gbe igbesẹ lati koju awọn to ba lufin yii nigbakigba to ba ṣẹlẹ."
Bẹẹ ni ijọba Eko wi ninu atẹjade ikilọ naa.
Wọn ko ṣai rọ awọn ti wọn n gbe eto ori ayelujara jade lati lọ mọ gbogbo ofin to de iṣẹ wọn dunju-dunju.
Wọn ni ki wọn ri i daju pe wọn n pa ofin to de aabo ati ẹtọ ọmọde mọ bi wọn ba n gbe ero ọkan wọn safẹfẹ, ki wọn ma baa tori atijẹ dero ẹyin gbaga.


























