Ìjọba Kwara ṣí àwọn ilé ẹ̀kọ́ ní ìjọba ìbílẹ̀ tí ètò ààbò ṣokùnfà títì wọ́n pa

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń ṣe ìdánwò

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara ti kéde ṣíṣí àwọn ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n tìpa ní ìjọba ìbílẹ̀ márùn-ún, tí wọ́n sì ní káwọn ilé ẹ̀kọ́ náà bẹ̀rẹ̀ ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ padà.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ẹ̀kọ́ ní ìpínlẹ̀ Kwara, Peter Amogbonjaye, fi léde lórúkọ Kọmíṣánnà fún ètò ẹ̀kọ́, Lawal Olohungbede ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kejì, oṣù Kejì, ọdún 2026 ni kí gbogbo àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó wà ní títipà jẹ́ ṣíṣí padà.

Ẹ ó rántí pé láti ìgbà sáà ètò ẹ̀kọ́ tó kọjá ni ìjọba Kwara ti gbé àwọn ilé ẹ̀kọ́ tìpa ní àwọn ìjọba ìbílẹ̀ Oke-Ero, Ifelodun, Irepodun, Isin àti Ekiti nítorí ìbẹ̀rù ìkọlù àwọn ajínigbé àtàwọn agbébọn.

Ìgbésẹ̀ náà ló wáyé lẹ́yìn táwọn agbébọn ṣèkọlù sí ilé ìjọsìn CAC Eruku ìjọba ìbílẹ̀ Ekiti, tí wọ́n sì jí ọ̀pọ̀ àwọn olùjọ́sìn gbé lọ.

Ẹ̀wẹ̀, ìjọba Kwara ní ààbò ti wà dé ààyè kan láwọn agbègbè náà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn yóò túnbọ̀ máa mójútó ààbò àwọn agbègbè yìí.

Olohungbede níú àtẹ̀jáde náà sọ pé gbogbo àwọn ilé ẹ̀kọ́ tí ọ̀rọ̀ náà kàn ni wọ́n ti fi ọ̀rọ̀ náà tó létí.

"Àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ṣì ń bá iṣẹ́ wọn lọ láti ri dájú pé gbogbo akitiyan àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò náà kò jásí pàbó."

Ní oṣù Kọkànlá ọdún 2025 ni ìjọba kéde kí wọ́n ti gbogbo àwọn ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama tó wà láwọn ìjọba ìbílẹ̀ náà títí tí wọ́n fi máa wá ojútùú sí ìpèníjà ètò ààbò tó ń bá àwọn agbègbè náà fínra.

Ìjọba ní ìgbésẹ̀ náà wáyé látàrí àti dá ààbò bo àwọn akẹ́kọ̀ọ́, olùkọ́ àtàwọn òṣìṣẹ́ míì nítorí ìbẹ̀rù ìkọlù àwọn agbébọn èyí tó ń wáyé lemọ́lemọ́ sí àwọn ìlú tí igbó yíká púpọ̀.

Lẹ́yìn náà ni ìjọba da àwọn ọmọ ogun àtàwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò míì láti kojú oro sáwọn agbébọn tó ń fi àwọn àyíká náà ṣe ibùgbé.

Ṣíṣí àwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tí ìjọba Kwara gbé ilé olùkọ́ni tó wà ní ìlú Oro, ìjọba ìbílẹ̀ Irepodun tìpa nítorí ìbẹ̀rù ìkọlù àwọn agbébọn, táwọn akẹ́kọ̀ọ́ sì ti kúrò nínú ọgbà náà báyìí.

Ìgbésẹ̀ yìí náà ló ti ń da ìbẹ̀rù bojo sọ́kàn àwọn òbí lórí ààbò àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ìpínlẹ̀ Kwara.

Ìjọba wá rọ àwọn òbí àti olùkọ́ láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọba, tí wọ́n sì sọ àrídájú rẹ̀ pé gbogbo ètò láti dá ààbò bo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ ni àwọn ti ṣe.

Ìjọba Kwara bẹ̀rẹ̀ ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ lórí rédíò fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ nítorí ìkọlù àwọn ajínigbé

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Láti oṣù Kọkànlá ọdún 2025 ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láwọn ìjọba ìbílẹ̀ márùn-ún náà wà nílé títí tí sáà ìkẹ́kọ̀ọ́ àkọ́kọ́ fi parí nínú oṣù Kejìlá.

Nígbà tí sáà ètò ẹ̀kọ́ kejì bẹ̀rẹ̀ ní oṣù Kìíní, ọdún 2026, ìjọba ní àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà kò ní bá àwọn akẹ́gbẹ́ wọn wọlé nítorí ètò ààbò kò ì tíì kẹ́sẹ járí lágbègbè wọn.

Ìjọba kéde nínú oṣù Kìíní pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà yóò máa kẹ́kọ̀ọ́ lórí rédíò fún ìgbà kan ná.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ náà, Peter Amogbonjaye, nínú àtẹ̀jáde tó fi léde lórúkọ Kọmíṣánnà ètò ẹ̀kọ́, Lawal Olohungbebe sọ pé ìjọba fẹnukò lórí ìdarí yìí lẹ́yìn tí wọ́n ṣe àgbéyẹ̀wó ètò ààbò àtàwọn iṣẹ́ tó ń lọ lọ́wọ́ káàkiri ìpínlẹ̀ náà.

Olohungbebe ní dídá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ dúró sílé láwọn agbègbè tí ètò ààbò ti nílò àmójútó níbẹ̀ gidi jẹ́ ọ̀nà láti fi dá ààbò bo àwọn olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ ní agbègbè náà.

"Bí ìwọlé padà sẹ́nu ẹ̀kọ́ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe ń wáyé ní ipele ipele yìí jẹ́ ojúná láti ri pé a kò fi àwọn ọmọ wa sínú ewu pẹ̀lú àkànṣe iṣẹ́ ààbò tó ń lọ lọ́wọ́ láwọn agbègbè náà.

"Ètò ẹ̀kọ́ máa tó padà sípò láwọn agbègbè náà láìpẹ́," Olohungbede sọ.

Ó fi kun pé láti lè ri dájú pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí kò lọ sílé ẹ̀kọ́ kò máa ṣe àfẹ́kù ohun tó yẹ kí wọ́n kọ́ púpọ̀, ó ní ìjọba ti gbé àwọn ètò kan kalẹ̀ lórí rédíò láti máa fi ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà.

Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kìíní ni Kọmiṣánnà náà sọ pé ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí rédíò náà máa bẹ̀rẹ̀ èyí tí àjọ UNICEF àti Nigeria Learning Passport fọwọ́ sí.

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde náà ṣe sọ, orí ìkànnì Midland FM 99.1 ni ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ náà yóò ti máa wáyé ní aago mọ́kànlá òwúrọ̀ ní gbogbo ọjọ́ Ajé, aago kan ọ̀sán ní gbogbo ọjọ́rú àti aago méjì àbọ̀ ọ̀sán ní gbogbo ọjọ́ Ẹtì títí tí ètò ẹ̀kọ́ fi máa padà sípò láwọn ìjọba ìbílẹ̀ náà.