Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara gbé àwọn ilé ẹ̀kọ́ tì pa níjọba ìbílẹ̀ márùn-ún torí ètò ààbò tó mẹ́hẹ

Gomina Abdulrasaq Abdulrahman ipinlẹ Kwara wọ aṣọ funfun pẹlu fila lori, ile ijọsin CAC niluu Eruku atawọn ọlọpaa
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba ipinlẹ Kwara ti gbe gbogbo awọn ile ẹkọ alakọbẹrẹ ati girama to wa ni ijọba ibilẹ marun-un ti pa lẹkun gusu ipinlẹ naa tori bi ọrọ eto abo se ri bayii nibẹ.

Awọn ijọba ibilẹ tọrọ naa kan ni, ìjọba ibilẹ Ekiti, Isin, Oke ẹrọ, Ifẹlodun ati Irẹpọdun ti gbogbo wọn wa ni lẹkun Gusu ipinlẹ Kwara.

Titi pa awọn ile ẹkọ naa ko sẹyin bọrọ eto abo ṣe n buru si i lẹkun naa.

Alaga ẹgbẹ awọn olukọ ipinlẹ Kwara (NUT), Kọmureedi Yusuf Agboọla, sọ ninu atẹjade kan to fi sita pe ijọba ti awọn ile ẹkọ naa pa latari ipenija ọrọ eto abo.

O salaye pe ki awọn olukọ kiyesi atẹjade yii, ati pe bi nnkan ba se ri awọn yóò pada fi to wọn leti.

Ninu ọrọ rẹ, alakoso awọn olukọ nijọba ibilẹ Isin, Oloye Lere Balogun, naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.

Kọmisọna feto ẹkọ ni ipinlẹ Kwara, Dr Lawal Ọlọrungbẹbẹ naa sọ pe ijoba ipinlẹ gbe igbesẹ yii lati daabobo awọn akẹkọọ ni.

O fi kun un pe ijọba fẹ ki aabo to peye wa fun awọn akẹẹkọ to fi mọ awọn akẹẹkọ to n gbe lọgba ile ẹkọ.

Gbogbo ile ẹkọ ijọba ati aladani lọrọ naa kan bayii lawọn ijọba ibilẹ marun-un ọhun.

Ni irọlẹ ana ni ibẹrubojo gbalẹ pe, awọn ajinigbe fẹ kọlu ile ẹkọ Anglican Girls College Iludun Oro, ṣugbọn ti ijọba tete ko awọn ẹṣọ alabo sọwọ si ile ẹkọ naa.

Titi awọn ile ẹkọ pa yii waye lẹyin wakati merinlelogun tawọn agbebọn kọlu ile ìjọsìn CAC niluu Eruku nijọba ibilẹ Ekiti nibi ti wọn pawọn olujọsin, ti wọn si ji awọn ọmọ ijọ marundinlogoji gbe lọ.

Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazak naa sabẹwo si ilu Eruku l'Ọjọru lati bawọn kẹdun, to si bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ ikọlu naa.