Mi ò lérò pé mo lè kọ́lé mọ́ láyé lẹ́yìn tí mo ti pé ọdún 70, kí n tó jẹ ilé tó rẹwà níbi àjọ̀dún iléeṣẹ́ redio Ayefele - Màmá Aminat
Yoruba bọ wọn ori ti yoo la ni lo n gbe alawore ko ni, bayii ni ọrọ ṣe ri pẹlu mama Aminat Dairo, iya eleedu niluu Ibadan to jẹ ile to rẹwa nibi ajọdun ọdun mẹwaa ileeṣẹ redio Yinka Ayefele, Fresh FM n'Ibadan.
Mama sọ fun BBC Yoruba wi pe ni ṣe lo dabi ''bi ala, abi irọ ni? Ṣe ile leleyii ṣa? Ṣe emi ni maa a ni i?
Ṣe wọn a fun mi ni abi wọn fi ṣe arumọjẹ ipolowo ọja ni?''
Oriṣiiriṣii ipenija ni mama Dairo ti koju lori ọrọ nini ile ati lẹnu owo eedu ti mama n ṣe, ki iya naa to jẹ ẹbun ile.
Mama ni ''emi kii ta tẹtẹ o, koda, mo ṣiṣẹ akọwe puulu ri nigba ti mo wa lọmọge, ṣugbọn eleyii, igba ti mo dẹ ti ra aṣọ ni mo fi ja tikẹẹti ẹyọkan ni ẹgbẹrun meji naira.
Kii ṣe pe ẹnikan lo ṣo pe ki n lọ ta a o, ẹmi Ọlọrun lo sọ pe ki n lọ ra aṣọ Ayefele o.
Mama Aminat ni o ya awọn lẹnu nigba tawọn wọ ile naa tawọn si wo inu rẹ kaakiri ti Ayefele funra rẹ si mu kọkọrọ ile naa fun mama.
''Mi o le sun fun odidi ọjọ mẹta, mo ṣa n wo o pe ṣe wọn fun mi nibi ile ọhun ni abi bawo ni mo ṣe fẹ ṣe e?
Amọ, Ọlọrun lo ye e o, mo ti jiya lori ọrọ ile, mo ti ra ilẹ mo si ti ṣe gbogbo rẹ, wọn gba a lọwọ mi.
Wọn ni ki n lọ wa ẹgbẹrun lọna ọgọrun un naira wa lati fi gba ilẹ mi pada, ṣugbọn mi o rowo naa.''
Mama ni eyi lo jẹ ''ki n gbe ọkan sọdọ Ọlọrun pe lẹyin ki n maa jẹun nikan loku bayii ti mo ti pe ẹni aadọrin ọdun.
Amọ, Ọlọrun wa pẹlu mi o n gbọ gbogbo rẹ tori o dabi ẹni pe eeyan n sọrọ fun eeyan ti ẹni naa si ṣe nnkan ti eeyan n beere lo ṣe ri.''
Ninu ọrọ tiẹ, oludasilẹ ileeṣẹ redio Fresh FM, Yinka Ayefele, sọ pe ''ko too di ọjọ ajọdun ti a ṣe ni mama ti fẹ wa ta Ayefele lọrẹ.
Wọn fẹ gbe eedu wa fun mi pe ki n fi ṣe asun.
Kii ṣe pe bo ya a dọgbọn si i rara, mi o mọ ọjọ ti wọn ja tikẹẹti.
Amọ, a dupẹ fun ibi to bọ si, inu emi gan an dun fun ibi to bọ si.''
Ayefele ni gbogbo awọn to ra tikẹẹti ni inu wọn dun fun ibi to bọ si tori pe o jẹ toootọ, wọn dẹ ri i pe aniyan ni Ọlọrun fi fun mama naa ni oore ọtun.'
















