Lẹ́yìn ìtúsílẹ̀ rẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, orúkọ Baba Ijesa wọ iwé àwọn ọ̀daràn tó ṣẹ̀ sófin tó de ìbálòpọ̀ l'Eko

Oríṣun àwòrán, Baba Ijesha Official/Instagram
Ẹka to n ri si ẹsun ifipabanilopọ nipinlẹ Eko, ti fidi rẹ mulẹ pe awọn ti fi orukọ gbajumọ oṣere, Olanrewaju James, ẹni ti ọpọ mọ si Baba Ijesha, sinu awọn orukọ awọn eeyan to ti sẹ si ofin ibalopọ nipinlẹ Eko lẹyin to pari asiko rẹ lọgba ẹwọn fun ẹsun ifipabanilopọ ọmọde.
Ile ẹjọ ran Baba Ijesha lọ si ẹwọn fun ẹsun aṣemaṣe pẹlu ọmọde lọdun 2021.
Ikede yii wa lati ọwọ ijọba ipinlẹ Eko lẹyin ti iroyin ofege kan jade pe ile ẹjọ giga ti da a lare.
Agbẹjọro agba ati kọmisana fun eto idajọ ipinlẹ Eko, Lawal Pedro, SAN ṣapejuwe iroyin ọhun gẹgẹ bii iroyin ẹlẹjẹ.
Bakan naa lo tun fi ikilọ ransẹ si gbajumọ oṣere to jẹ akẹgbẹ Baba Ijesha, Yomi Fabiyi ati awọn eeyan mii pe ki wọn dẹkun gbigbe iroyin ẹlẹjẹ kiri fun araalu.
Ninu atẹjade ti wọn gbe soju opo ayelujara, ẹka to lodi si ifipabanilopọ nipinlẹ Eko, fidi rẹ mulẹ pe lotitọ ni pe awọn ti fi orukọ Baba Ijesha kun orukọ awọn eeyan to ti sẹ si ofin ifipabanilopọ, ni ilana pẹlu ofin ọdun 2021.
Ẹka naa ni igbesẹ ọhun da lori dida aabo bo awọn ọmọde ati ọdọmọbinrin lọwọ awọn iwa bayii ati lati le jẹ ki awọn araalu ni anfaani si iroyin to yẹ.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko sọ òkodoro nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lórí ìtúsílẹ̀ Baba Ijesa lọ́gbà ẹ̀wọ̀n yàtọ̀ sí àhesọ ọ̀rọ̀ tó gbalẹ̀

Oríṣun àwòrán, Baba Ijesha/Instagram
Ijọba ipinlẹ Eko ti ṣalaye okodoro ọrọ lori iroyin tawọn eeyan kan n gbe kiri wi pe ile ẹjọ kotẹmilọrun fidi rẹ mulẹ pe gbajugbaja oṣere tiata, Olarenrawaju James Omiyinka, ti ọpọ mọ si Baba Ijesa ko jẹbi ẹsun ifipabanilopọ to ṣẹwọn le lori.
Kọmiṣọna fun eto idajọ ati agbẹjọro agba ni ipinlẹ Eko, Amofin Lawal Pedro (SAN) ti sọ fawọn akọroyin wi pe irọ to jina si oootọ ni iroyin naa.
Agbẹjọro agba Pedro (SAN) sọ pe iru iroyin bayii le ṣi awọn araalu lọna.
Ọgbẹni Pedro sọrọ yii lẹyin ti Yomi Fabiyi to jẹ akẹgbẹ Baba Ijesa ṣalaye lọjọ Ẹti ọsẹ to kọja pe Baba Ijesa ti gba itusilẹ lọgba ẹwọn, ile ẹjọ kotẹmilọrun si ti sọ pe ko jẹbi ẹsun ifipabọmọdelopọ ti wọn fi kan an.
Amọ, amofin agba Pedro sọ pe ''ko si nnkan to jọ bẹẹ ninu gbogbo igbẹjọ Baba Ijesa, ọna lati yi idajọ ile ẹjọ pada lawọn eeyan kan n wa.''
Agbẹjọro agba ipinlẹ Eko ṣalaye wi pe ile ẹjọ giga ipinlẹ Eko fidi rẹ mulẹ lọjọ kẹrinla oṣu Keje ọdun 2022 pe Baba Ijesa jẹbi ẹsun ifipabanilopọ ati ihuwa ti ko tọọ si ọmọde lori iṣẹlẹ to waye lọdun 2021.
O ni lẹyin naa ni ile ẹjọ da ẹjọ ẹwọn ọdun marun un fun Ọgbẹni Omiyinka.
Agbẹjoro agba ipinlẹ Eko tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ wi pe loootọ ni ile ẹjọ kotẹmilọrun gbe awọn ẹsun kan ti wọn fi kan Baba Ijesa eyi to ṣẹlẹ lọdun 2013 si 2014 sẹgbẹ kan, loṣu Kẹfa ọsun 2024, amọ, Ọgbẹni Pedro fidi rẹ mulẹ pe ile ẹjọ kotẹmilọrun fọntẹ lu idajọ ile ẹjọ giga to dajọ ẹwọn ọdun marun un fun un lori ẹsun ifipabanilopọ eyi to ṣẹlẹ lọdun 2021.
''Baba Ijesa lo ọdun marun un ti ile ẹjọ ni ko lo lọgba ẹwọn pere pere''
Amofin agba Pedro fikun ọrọ rẹ pe gbogbo ọna lawọn agbẹjọro Baba Ijesa wa labẹ ofin lati yi idajọ ti ile ẹjọ fun un danu.
Ṣugbọn Ọgbẹni Pedro fidi rẹ mulẹ pe ile ẹjọ yi ẹjọ kotẹmilọrun ti Baba Ijesa fẹ pe ni ile ẹjọ to ga julọ danu loṣu Karun un ọdun 2025.
O ni eyi lo fontẹ lu idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun to buwọlu idajọ ile ẹjọ giga eyi to ni ki Ọgbẹni Omiyinka lo faṣọ penpe roko ọba fun ọdun marun un.
Pedro ni itusilẹ Baba Ijesa lọgba ẹwọn ko tumọ si pe ko jẹbi ẹsun to gba idajọ le lori.
Kọmiṣọna fun eto idajọ ipinlẹ Eko ṣalaye pe itumọ eleyii ni pe Baba Ijesa lo ọdun marun un ti ile ẹjọ ni ko lo lọgba ẹwọn pere pere, gẹgẹ bi ile ẹjọ kotẹmilọrun ṣe fontẹ lu idajọ ile ẹjọ giga ipinlẹ Eko.
Agbẹjọro agba ipinlẹ Eko wa rọ awọn eeyan lati kọ eti ikun si iroyin tawọn kan n gbe kiri pe ile ẹjọ kotẹmilọrun sọ pe Baba Ijesa ko jẹbi ẹsun to lọ sẹwọn le lori.















