Àwọn alákatakítí ẹ̀sìn dínà ibi tí epo bẹntiró ń gbà wọ ìlú, ọ̀wọ́ngógó gbòde

Oríṣun àwòrán, AFP/Getty
- Author, Chris Ewokor
- Role, BBC Africa's West Africa correspondent
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Ni Bamako to jẹ olu ilu orilẹede Mali, ọpọ ero lo ti bẹrẹ si n fi ẹsẹ wọn rin bayii dipo awọn ọkọ ati alupupu.
Eyii ko ṣẹyin bi awọn alakatakiti ẹsin ṣe di oju ọna to yẹ ki epo bẹntiro maa gba wọ orilẹede naa lati nnkan bii oṣu meji sẹyin.
Ẹgbẹ alakakiti ẹsin Islam, Jama'at Nusrat al-Islam wal-Muslimin (JNIM), to ni ibaṣepọ pẹlu ẹgbẹ al-Qaeda lo ti bẹrẹ si n kọlu awọn agbepo to n wọ orilẹede Mali, eyii to sọ ogun awọn agbesunmọmi di ogun ọrọ aje bayii.
Awọn ọmọ ogun JNIM ti ji ọpọ awakọ epo gbe ti wọn si ti dana sun nnkan bii ọgọrun ọkọ agbepo bẹntiro to n lọ silu Bamako.
Fun ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu eeyan, wọn ko le gbe igbeaye wọn bo ṣe wu wọn mọ ni bayii ti awọn ile ẹkọ ti di titi pa ti ounjẹ si ti gbe ọpọ owo gọbọi lori, bẹẹ ni ko si ina lawọn ile iwosan.
Ọrọ naa le to bẹẹ ti ijọba ilẹ Amẹrika fi kilọ fun awọn eeyan rẹ pe ki wọn maṣe tẹ Mali nigba ti France sọ fun awọn eeyan rẹ to wa ni Mali ki wọn fi orilẹede naa silẹ ni kia-kia.
Ọpọ eeyan lo n to siwaju awọn ile epo bayii amọ ti wọn kii ri epo ra.
We're here waiting for fuel, and we've been here for more than four days now"
Awakọ takisi kan niluu Bamako, Sidi Djiré, sọ fun BBC pe "Epo la n duro de nibi, a si ti wa nibi fun ọjọ mẹrin o le bayii."
Ọgbẹni Sidi Djiré ni oun n ni ireti pe ijọba ologun to wa lode yoo le yanju iṣoro naa laipẹ nitori gbogbo araalu lo ti n kan bayii.
Pupọ awọn ile epo nibẹ ni wọn n kọ akọle "Ko si epo lonii" siwaju rẹ ti pupọ ninu awọn awakọ ero si n sun ile epo mọju, yatọ si ọgọrọ ero to n fi ẹsẹ rin lọ ibiṣẹ wọn.
Nile itaja igbalode Baco Djicoroni, oṣiṣẹ kan nibẹ sọ pe ounjẹ ti gbowo lori ni ilọpo mẹta.
O ni "gbogbo nnkan lo ti le koko bayii amọ ki ni a fẹ ṣe? Oju ogun ni a wa. A gbadura ki Ọlọrun da alaafia pada fun wa."
Awọn oniṣowo sọ fun BBC pe awọn ti ṣe afikun awọn ọja wọn nitori owo ọkọ to gbowo lori.
Amadou Traoré to jẹ oniṣowo sọ pe awọn ko ni ọna abayọ mii ju ki wọn fikun owo awọn ọja awọn lọ nitori ko rọrun lati lọ maa ko awon nnkan ti wọn n ta.

Lọdun marun un sẹyin ti awọn ologun gbajọba, ọpọ araalu lo kin wọn lẹyin latari bi wọn ṣe ni awọn yoo yanju iṣoro eto abo to n ba orilẹede naa finra.
Amọ awọn alakakiti ẹsin naa tunbọ n lagbara si to si da bii pe ijọba ologun naa ko le bori wọn.
JNIM, to jẹ ẹgbẹ agbesunmọmi to milẹ titi julọ nibẹ n ṣọṣẹ lemọlemọ ti wọn si bẹgi dina oju ọna ti epo bẹntiro n gba wọ orilẹede naa lagbegbe ariwa ati ila oorun ilẹ ọhun.
Ko si omi kankan to yi Mali ka, eyii to n tumọ si pe wọn gbọdọ maa gbe epo wọ ibẹ lati awọn agbegbe to yi ka bii Senegal ati Ivory Coast.
Ni bayii to ti di gbogbo ọna ti epo le maa gba wọle, JNIM ti fi ijọba si ipo ti ko dara.
Igi ti wọn bẹ dina yii tun n tumọ si pe JNIM ti n gba ọpọ ilẹ.
Epo ti ko si naa ni ipa ribiribi lara awọn ile iwosan nitori ina mọnamọna ko ṣe dede nibẹ.
Nile iwosan Kalaban Coro Health Centre, ọpọ oṣiṣẹ ni ko yọju sẹnu iṣẹ nitori awọn ọkọ akero ti ko ri epo lati gbe awọn eeyan.
Yatọ si eyii, ọpọ akẹkọọ ni ko le lọ ile ẹkọ, koda, wọn ti gbe ile ẹkọ ati fasiti ti pa fun odidi ọsẹ meji.
Ni bayii, ọpọ araalu lo ti n sọ ireti nu ninu ijọba ologun to wa lode.
Lọna ati maye dẹrun, awọn ologun ti n ṣọ awọn ọkọ agbepo bayii ti wọn si n tẹle wọn lọ ibikiti ti won ba ti fẹ lọ ja epo ṣugbọn ewu wa nitori ikọlu awọn agbesunmọmi na si awọn ọkọ agbepo ọhun lai ro ti ologun to wa pẹlu wọn.
Bo tilẹ jẹ pe ara n ni awọn araalu, ijọba ologun Mali sọ pe ko sewu ki awọn eeyan lọ fi ọkan balẹ.

Oríṣun àwòrán, AFP/Getty Images
Epo ti ko si yii ti n tu aṣiri ikuna ijọba ologun Mali ti ọgagun Assimi Goïta n dari pe ko le daabo bo araalu gẹgẹ bii ileri rẹ fun wọn ṣaaju.
Iṣẹlẹ naa tunbọ jẹ ki ijọba orilẹede ọhun maa gbẹkẹle orilẹede Russia.
Awọn ajagunta lati Russia lo ti kọkọ ṣatilẹyin fun ijọba Goita lẹyin ti awọn ọmọ ogun UN fi orilẹede naa silẹ.
Eyii n tumọ si pe Mali le maa gbẹkẹle Russia fun iranlọwọ bayii dipo ilẹ Amẹrika ati ilẹ Gẹẹsi.
Lọwọ yii, epo ti ta si ala Mali ati ajọ EU to fi mọ ilẹ Amẹrika, ti wọn si tun ti pin gari pẹlu France.
Ṣugbọn fun araalu, ko si nnkan to kan wọn pẹlu oṣelu agbaye bi ko ṣe ki aye dẹrun fun wọn.
Ọkunrin kan, Amidou Diallo to jẹ jorinmọrin sọ fun wa pe ohun to n lọ lọwọ ni Mali le ṣokunfa alekun iwa ọdaran lorilẹ naa.












