Ondo politics: Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá pàṣẹ kí wọn dá àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo padà

Akeredolu ati Agboola Ajayi

Oríṣun àwòrán, others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Mohammed Adamu ti paṣẹ pe ki kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Bolaji Salami da ẹṣọ alabo igbakeji gomina ipinlẹ naa pada fun un.

Aṣẹ yii lo wa ninu iwe kan ti ọga agba ọlọpaa naa fi ranṣẹ lati olu ileeṣẹ ọlọpaa n'lu Abuja, eyi ti agbẹnusọ igbakeji gomina ọhun, Babatope Okeowo fi ṣọwọ si BBC Yoruba.

Ọsẹ to kọja ni kọmiṣọna ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo yọ awọn ẹṣọ alabo Agboola Ajayi, to jẹ igbakeji gomina ipinlẹ Ondo.

Iṣẹlẹ naa mu ki igbakeji gomina ọhun fẹsun kan kọmiṣọna ọlọpaa naa pe o n ṣiṣẹ lodi si oun nitori họwuhọwu to wa laarin rẹ ati gomina Rotimi Akeredolu.

Ṣaaju ni igbakeji gomina ọhun ti bu ẹnu atẹ lu kọmiṣọna naa lẹyin to dena rẹ nigbato fẹ jade kuro ninu ọgba ile ijọba to wa ni Alagbaka, ni ilu Akure.

Ede aiyede bẹ silẹ laarin gomina Rotimi Akeredolu ati igbakeji rẹ, Agboola Ajayi lẹyin ti Ajayi yapa kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC lọ si ẹgbẹ oṣelu PDP.

Iṣẹlẹ yii ti fa ọpọlọpọ gbọnmisi omi o to laarin awọn mejeji ati awọn alatilẹyin wọn.

Akeredolu ati Agboola Ajayi

Oríṣun àwòrán, others

Ìjọba Ondo ní òun kò sọ pé Agboola Ajayi kìí ṣe igbákejì gómìnà mọ́

Ijọba ipinlẹ Ondo ti sọ pe, ọdalẹ ni igbakeji gomina ipinlẹ naa, Agboola Ajayi, lẹyin to fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ lọ si ẹgbẹ oṣelu PDP.

Akọwe iroyin fun gomina ipinlẹ ọhun, Segun Ajiboye lo sọ bẹẹ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba.

O ni irọ ni awọn amugbalẹgbẹ igbakeji gomina naa n pa pe, ijọba ipinlẹ Ondo n dẹyẹ si wọn, ati pe amofin agba ni gomina Rotimi Akeredolu, ko si ni ṣe ohun kankan ti yoo lodi si ofin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ajiboye ṣalaye pe ijọba ipinlẹ Ondo ko sọ pe Agboola Ajayi kii ṣe igbakeji gomina mọ, ṣugbọn iwa ọdalẹ ni igbakeji gomina ọhun wu, bo ṣe fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ.

O ni "Nnkan ti arakunrin yii ṣe ni wọn pe ni iwa ọdalẹ ni ilẹ Yoruba. "Ni ti awọn alabaṣiṣẹ igbakeji gomina naa, ti ijọba ipinlẹ Ondo gbaṣẹ lọwọ wọn, Ajiboye sọ pe ẹni to ba fun ni ni iṣẹ le gba iṣẹ naa lọwọ, ẹni lọrọ naa ri.

Facebook/Rotimi Akeredolu Aketi

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu Aketi

Bẹẹ ba gbagbe, ede aiyede bẹ silẹ nile ijọba Akure lẹyin ti igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo yapa kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC, to si darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP.

Ọjọ kejilelogun oṣu kẹfa ọdun 2020 ni awọn eekan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, ṣe ayẹyẹ kaabọ ọmọ ọdọ rere fun igbakeji gomina ọhun.

Igbákejì gómìnà Ondo ti gbawọn òṣiṣẹ́ rẹ̀ mẹ́jọ tí Akeredolu dá dúró ṣíṣẹ́ padà

Igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo to fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ lọ si PDP, Agboola Ajayi ti gbawọn amugbalẹgbẹ rẹ mẹjọ ti Gomina Rotimi Akeredolu da duro lẹnu iṣẹ.

Ọkan lara awọn eeyan naa, Ọgbẹni Tope Okeowo lo fidi ọrọ yii mulẹ fun BBC Yoruba.

Ọkeowo ṣalaye pe igbakeji Gomina Ondo tun ti yan oun gẹgẹ si ipo gẹgẹ bi akọwe iroyin.

Bakan naa ni ẹlomiiran, Allen Sowore fi si oju opo Facebook rẹ pe Ọgbẹni Ajayi ti yan oun gẹgẹ bi oludamọran paraki lori ọrọ iroyin.

Sowore sọ pe iyansipo naa ti bẹrẹ lati ọjọ Iṣẹgun tii ṣe ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹfa ọdun 2020.

Ẹwẹ, igbakeji Gomina ti rọ gbogbo alabiṣiṣẹpọ rẹ lati da ohun ini ijọba Ondo to ba wa lakata wọn pada lati wakati mẹrinlelogun.

Ọgbẹni Ajayi tun ṣeleri pe oun yoo bawọn eeyan ipinlẹ Ondo sọrọ lori ohun to n lọ laipẹ.

Lórí bóyá igbákejì gómìnà Ondo yóò fipò sílẹ̀ tàbí rárá, ohun tó lu sí wa lọ́wọ́ nìyí

Igbakeji gomina ipinlẹ Ondo, Agboola Ajayi ti sọ pe oun ṣi ni igbakeji gomina ipinlẹ naa nitori bi oun ṣe kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC lọ si PDP ko lodi si ofin.

Agboola lo kede bẹẹ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC lati ẹnu agbẹnusọ rẹ, Babatope Okeowo.

Lẹyin naa lo sọ pe ko pọn dandan ki igbakeji gomina ọhun yọju ojuko ipade awọn igbimọ aṣejọba to ma n waye laarin ọsẹ.

Agbla Ajayi

Oríṣun àwòrán, Premium times nigeria

Okeowo ṣalaye pe "Kii ṣe dandan ki igbakeji gomina yọju si ibi ipade awọn aṣejọba nitori wọn kii pe sibi ipade ọhun tẹlẹ gan lọpọ igba, nitori naa, to ba wu yoo lọ, to ba si wu, ko ni lọ.

O tẹsiwaju pe ijọba ipinlẹ Ondo ki n fun igbakeji gomina naa lawọn ẹtọ kan to tọ si gẹgẹ ipo rẹ.

Ni ti ohun gan to fa ede ayede laarin gomina Rotimi Akeredolu ati igbakeji rẹ.

Okeowo ni "Mi o le sọ ni pato ohun to fa họwuhọwu larin wọn, ṣugbọn ohun to ṣe pataki ni pe ko lodi si ofin ki eeyan fi ẹgbẹ oṣelu kan silẹ lọ omiran."

Okeowo pari ọrọ rẹ pe igbakeji gomina ọhun ko ji ẹru ijọba ipinlẹ Ondo ko bi awọn kan ṣe lero,

Ati pe iṣẹ ti awọn agbofinro ṣe lati dena rẹ nigba to fẹ jade ninu ile ijọba to wa ni ilu Akure ko ba ofin mu.

Àkọlé fídíò, Kid boxer: Ọmọọba 'The Buzz' Larbie rèé, ọmọ ọdún méje tó ń fi ẹ̀ṣẹ́ dá bírà

Kí ni awọn onwoye n ri sọ nipa rẹ?

Ẹwẹ, onimọ nipa bi eto oṣẹlu ṣe n lọ ni ipinlẹ Ondo, Sola Akinbinu sọ pe ko yẹ ko jẹ asiko ti eto idibo sun mọle yii lo yẹ ki igbakeji gomina fi ẹgbẹ oṣẹlu APC silẹ lọ si PDP.

Akinbinu ni o daju pe igbakeji gomina naa n lepa lati dije si ipo gomina ni ipinlẹ Ondo ni, bi bẹẹ kọ, o yẹ ko yẹ ko jẹ asiko yii ni Agboola Ajayi yoo fi ẹgbẹ to gbee wọle silẹ.

Nibi ipade ati gba Agbla si PDP

O ni "Ko ro wipe oun lee di gomina ninu ẹgbẹ APC lo jẹ ko lọ darapọ ẹgbẹ PDP."

Akinbinu tẹsiwaju pe "O ṣeṣe ki ọpọ ninu awọn to n ba gomina Akeredolu ṣiṣẹ tẹle igbakeji rẹ lọ sinu ẹgbẹ oṣelu PDP"

O ṣalaye pe Agboola Ajayi ko ba má jẹ nkan ni ipinlẹ Ondo ti kii ba ṣe ti gomina Rotimi Akeredolu.

Akinbinu pari ọrọ rẹ pe ohun to ṣe pataki ni ki awọn eeyan mọ ohun ti wọn n fẹ ki ọjọ idibo to de ki wọn lee mọ ẹni ti wọn yoo dibo fun.

Ondo politics: Àwọn àgbàgbà PDP péjú sí Akure láti gba igbákejì gómìnà Ondo, Agboola Ajayi wọ PDP

Nibi ipade ati gba Agbla si PDP

Igbakeji gomina ipinlẹ Ondo, Agboọla Ajayi ti darapọ mọ gb oṣelu PDP ni san an bayii.

awn agbagba ẹgbẹ oṣelu naa ni wọn tẹw gbaa sinu ẹgbẹ nibi akanṣe ipade itagbangba kan ti wọn ṣe ni ilu Akurẹ.

Nibi ipade ati gba Agbla si PDP
Nibi ipade ati gba Agbla si PDP

Ondo politics: Fayose ní ìkọjá àyè ni kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá tó lọ de igbákejì gómìnà, Agboola Ajayi lọ́nà l'Ondo

Fayose ati Agboola

Oríṣun àwòrán, other

Gomina tẹlẹ fun ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayoṣe naa ti da si ọrọ to n lọ laarin igbakeji gomina ipinlẹ Ondo, Agbooọla Ajayii ati ọga rẹ, Gomina Rotimi Akeredolu eleyi to ti mu ki igbakeji naa o kọwe fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ.

Fayoṣe ṣalaye ninu atẹjade kan loju opo twitter rẹ pe ko si idi kan fun kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo lati de igbakeji gomina lọna nitori pe o n ko ẹru rẹ lọ sẹgbẹ oṣelu PDP.

Fayoṣe ni niwọn igba ti ko ti si ofin kan to laa kalẹ pe ọlọpaa ko lee fun igbkeji gomina laaye lati lo ọkọ ọfiisi rẹ mọ nitoripe o rekọja si ẹgbẹ oṣelu miran.

Bakan naa ni gomina tẹlẹ ọhun tun sọ ọ di mimọ pe awọn iṣẹlẹ to n ṣẹlẹ ni ipinlẹ Edo pẹlu n tọka si ipo gba f'Ọlọrun ti awọn eeyan ipinlẹ naa wa

Àkọlé fídíò, Láàrín ìdílé ẹlẹ́ni márùn ún yìí, ọmọ kan ṣoṣo ló léè sọ̀rọ̀

Ondo deputy governor: Igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo Agboola Ajayi ti fẹgbẹ́ APC sílẹ̀ lọ PDP

Agboola Ajayi

Oríṣun àwòrán, Facebook/Allen Sowore

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo sọ pe igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo, Agboola Ajayi ti fẹgbẹ oṣelu APC silẹ lọ PDP.

Akọwe iroyin fun Ọgbẹni Ajayi to ba BBC Yoruba sọrọ, Tope Okeowo lo fidi ọrọ naa mulẹ.

Skip Facebook post, 2

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post, 2

Okeowo fidi rẹ mulẹ fun BBC Yoruba wi pe lọjọ Aiku ni igbakeji Gomina Ondo kọwe fipo silẹ gẹgẹ ọmọ ẹgbẹ osẹlu APC.

Ti ijo ti ilu ni wọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP fi ki Ọgbẹni Ajayi kaabọ sinu ẹgbẹ wọn.

Ko da awọn eekan ninu ẹgbẹ PDP gbadura fun un bi wọn ti fi kaadi ọmọ ẹgbẹ le e lọwọ.

Ẹwẹ, akọwe iroyin rẹ sọ fun BBC Yoruba pe lọjọ Aje ni Ọgbẹni Ajayi yoo bawọn akọroyin sọrọ lori idi to fi kuro ninu ẹgbẹ APC lọ si PDP ati igbesẹ to kan fun un.

Ìròyìn òfegè ní! Mi ò sọ fáwọn ẹ̀ṣọ́ pé kí wọ́n ti géètì mọ́ igbákejì mi- Akeredolu

Gomina ipinlẹ Ondo Rotimi Akeredolu ti fesi si fidio kan to lu ori ayelujara pa ninu eyi ti awọn ẹṣọ kan ti dina mọ igbakeji gomina Ondo, Agboola Ajayi lati jade kuro nile ijọba.

Gomina Akeredolu sọ loju opo Twitter rẹ ko si ohun kan to le mu oun sọ fawọn ẹṣọ alaabo lati dena mọ igbakeki oun.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Lori ẹsun wi pe Agboola fẹ fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ lọ PDP, Akeredolu ni igbakeji oun le lọ si ibi kibi to ba wun u.

Gomina ipinlẹ Ondo ni awọn kan lo kọ iroyin lati fi oun han gẹgẹ bi eeyan buruku.

Facebook/Rotimi Akeredolu Aketi

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu Aketi

Ohun ti a gbọ ni pe aarin Akeredolu ati igbakeji ko dan mọran lati igba ti igbakeji ko ti da si awọn eto ijọba ipinlẹ Ondo kan to fi mọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Ondo deputy governor: Akeredolu ti géètì mọ́ igbákejì rẹ̀, ó fẹ̀sùn olè kàn án, kò tún jẹ́ kó lo ọkọ̀ ìjọba'

Ọrọ di ero ya waa wo, idan orita ni ile ijọba ipinlẹ Ondo to wa ni agbegbe Alagbaka, Akure ni alẹ ọjọ Abamẹta lasiko ti awọn oṣiṣẹ alaabo kọ lati jẹ ki igbakeji gomina ipinlẹ naa, Agboola Ajayi o jade kuro nile ijọba.

Iroyin sọ pe Kọmiṣana Ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Salami Bolaji ko awọn ọlọpaa rẹ sẹnu ọna ọfiisi ijọba ki igbakeji gomina, Agboola Ajayi ma lee jade sita tabi gbe ọkọ ijọba to n lo jade.

Agboola Ajayi/Akerdolu

Oríṣun àwòrán, Others

Ohun taa gbọ ni pe aṣẹ Gomina Rotimi Akeredolu ni awọn ọlọpa n tẹle.

Ṣugbọn nigba ti BBC Yoruba kan si igbakeji gomina lati gbọ iha tirẹ, agbẹnusọ igbakeji gomina, Tope Okeowo sọ pe irọ gbaa ni ohun to n tan kalẹ pe igbakeji gomina n gbiyanju lati ji ẹru ijọba ko jade.

Eyi lohun to wa ninu atẹjade ti Gomina Akeredolu fi sita lati ọwọ akọwe rẹ nipa iroyin, Segun Ajiboye, pe awọn gbọ iroyin pe, iṣẹlẹ jiji ẹru ijọba ko fẹ waye kan ni ọfiisi igbakeji gomina, ṣugbọn ti awọn ẹṣọ ọfiisi naa ṣiṣẹ gidi lati ma jẹ ki wọn ri nkankan ji lọ.

Àkọlé fídíò, Amugbalẹgbẹ fun Gomina Akeredolu, Ọmọwe Doyin Ọdẹbọwale koro oju si

Bakan naa, agbẹnusọ igbakeji gomina ni irọ patapata ni gbogbo rẹ. O ṣalaye pe wọn kan fẹ fi ohun ti wọn kọ jade bo otitọ mọlẹ ni.

"Igbakeji gomina to wa lori ipo lọwọlọwọ fẹ lọ tọwọ bọwe lọdọ ẹgbẹ oṣelu APC ki o le lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP to si fẹ gbe ọkọ to n lo lọfiisi rẹ jade lawọn ọlọpa o jẹ ko jade nile ijọba".

Ọgbẹni Tope ni titi ago mejila oru ọjọ Satide lawọn wa lori ọrọ yii pẹlu awọn ọlọpaa. Koda, o fi ẹsun kan pe kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Ondo wa nibi iṣẹlẹ naa.

O sọ pe ọkọ aladani ọga oun lo pada gbe jade kuro ni ile ijọba, to si fi ọkọ ijọba to da wahala silẹ sibi ti ọrọ ti waye.

Ninu atẹjade ijọba, akọwe iroyin fun Gomina Akeredolu sọ pe "kii dena mọ ẹtọ ẹnikẹni lẹnu iṣẹ ṣugbọn ijọba yoo koro oju si igbimọpọ lati gbẹsẹ le nkan ijọba nipa lilo ominira tabi anfaani ti wọn ni si iru dukia bẹ ẹ".