Hajj 2020: ìjọba Saudi ní kò sí ààyè fáwọn alálàájì láti fi ọwọ́ kàn Ka'aba

Aworan awọn to jina si Ka'abah lasiko ti wọn n kirun ni Mọṣalaṣi Haram lọdun 2017

Oríṣun àwòrán, AFP

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn eleto Hajj lorileede Saudi Arabia ti kede pe, ko ni saye fawọn alalaji lati fọwọ kan Ka'abah lasiko Hajj ọdun yi.

Eyi wa lara awọn ilana ti wọn fi lelẹ lati daabo bo awọn ti yoo kopa ninu ijọsin ọlọdọọdun nitori ajakalẹ Covid-19.

Yatọ si Ka'abah, awọn alalaji ko tun ni fọwọ kan okuta dudu ti a mọ si Hajar Aswad, ti wọn si tun gbọdọ fi aye ijina sira ẹni iwọn mita kan ati aabọ si ara wọn silẹ, lasiko ti wọn ba n ṣe ijọsin .

Ọpọ musulumi ni ko ni lanfani lati kopa ninu Hajj tọdun yii, nitori bi Saudi ti kede pe, eeyan diẹ ni yoo kopa ninu ijọsin yii, to jẹ opo kan pataki ninu ẹsin Islam.

Loṣu to kọja ni ileeṣẹ to n risi ọrọ Hajji ati Umrah gbe awọn ilana mẹjọ kan jade ti yoo de sise Hajj ọdun 2020 kalẹ.

Awọn wo ni yoo kopa ni Hajj ọdun yii?

Eeyan ẹgbẹrun mẹwa pere ni yoo kopa ninu Hajj ọdun 2020, tosi jẹ pe pupọ ninu wọn ni yoo jẹ awọn ọmọ ilẹ Saudi ati awọn ajoji to n gbe nibẹ.

Sheikh Abdul Rehman Al Sudais duro pẹlu awọn ẹsọ mọṣalaṣi lasiko abẹwo si Haram

Oríṣun àwòrán, Facebook/Haramain Sharifain

Àkọlé àwòrán, Aarẹ mọṣalaṣi mejeeji Haram ati Masjid Nabawiy, Sheikh Abdul Rehman Al Sudais lasiko abẹwo si Haram

Saaju asiko yii, ọdun marun marun lawọn to n gbe Saudi ma n kopa ninu Hajj ṣugbọn nitori ajakalẹ Covid-19 yii, wọn yoo gba wọn laye lati kopa ninu Hajj tọdun 2020.

Awọn ilana ti ijọba Saudi gbe kalẹ lori ṣise Hajj 2020 ree:

  • Ayẹwo yoo waye fawọn ti yoo ṣe Hajj lati mọ boya wọn ni arun Covid-19 lara, bi wọn ba si pari Hajj naa, wọn yoo ṣe ayẹwo wọn
  • Awọn to n gbe Saudi ati ọmọ ilu ti ọjọ ori wọn ko to ọdun marundinlaadọrin ni yoo kopa.
  • Awọn ọmọde to ni arun to lagbara bi itọ ṣuga ati aisan ọkan ko ni le kopa ninu Hajj
  • Wọn yoo maa tọpinpin ilera alalaji to ba kopa ninu Hajj naa loore koore
  • Diẹ ninu awọn eto Hajj ni wọn yoo ṣe lati mojuto ilana ijina sira ẹni
  • Awọn alalaji ti yoo kopa ko ni ju ẹgbẹrun mẹwaa lọ
  • Ko ni si eeyan kankan ti yoo ti a ti ilẹ miran wa si Saudi lati wa ṣe Hajj
  • Wọn yoo si ile iwosan pataki nitori titọju awọn to ba ni ipenija ilera pajawiri

Lọdun 2019 eeyan miliọnu meji ati abọ kaakiri awọn orileede agbaye lo kopa ninu Hajj.

Ibudo Hajj

Oríṣun àwòrán, Getty Images

'Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni inú wọn kò dùn sí bí Hajj kò ṣe ní wáyé lọ́dún yii'

Àkọlé fídíò, Saudi Arabia Hajj 2020: Alaga Hajj ni Naijiria ni inú wọn kò dùn sí bí Hajj kò ṣe ní wáyé.

Alaga Ajọ Hajj ni Naijiria, Alhaji Zikrullah Hassan ti ni ọpọlọpọ awọn to yẹ ki wọn lọ fun Hajj lọdun yii ni inu wọn kodun lẹyin ti ijọba ilẹ Saudi gbegile Hajj ọdun 2020.

Alhaji Hassan lasiko Ifọrọwanilẹnuwo parọwa si awọn eniyan lati gba bẹẹ lọdun yii nitori ati dẹkun ajakalẹ arun Coronavirus ni.

Bakan naa lo wa kesi awọn eniyan ti wọn fẹ gba owo wọn pada lati yọju si wọn.

Saudi Arabia kéde ìlànà tuntun fún Hajj nítorí coronavirus

Ajọ to n ṣeto irinna Hajj l'orilẹ-ede Naijiria sọ pe oun yoo ṣe ipade lọjọ Iṣẹgun, lati le mọ igbesẹ to ku ti wọn yoo gbe lori bi ijọba Saudi Arabia ṣe f'ofin de Hajj f'awọn ọmọ ilẹ okeere.

Ajọ naa sọ pe lootọ ni Saudi sọ fun awọn l'oṣu Kẹta pe ki wọn o dawọ ipalẹmọ fun Hajj duro fun awọn arinrinajo lati Naijiria.

"Oṣu mẹta sẹyin lati ri pe o ṣeeṣe ki ọrọ ko ri bayii, ṣugbọn a ko da ipalẹmọ duro, nitori a tun ro o pe Hajj ṣi le waye, ki ọrọ o ma wa a ba wa ni ojiji.

Awọn to wa ni mọsalaasi ni Saudi Arabia

Oríṣun àwòrán, AFP

Kọmisana fun iṣẹ ṣiṣe ninu ajọ naa, Alhaji Abdullahi Magaji Harwawa, sọ pe igbesẹ ti Saudi gbe ko ya wọn l'ẹnu, botilẹjẹ pe wọn ti n palẹmọ lati bi oṣu mẹta.

O ṣalaye pe bi wọn ṣe f'ofin de irinajo Hajj ọdun 2020 kii ṣe ẹbi orilẹ-ede kankan, ṣugbọn wọn gbọdọ gba a bi akọsilẹ Ọlọrun .

Bakan naa lo sọ pe awọn ti fi akọsilẹ igbaradi wọn ranṣẹ si ijsba ṣaaju ki Saudi to fi ikede sita.

Eyi ni yoo si mu ki ipade miran ko waye lati mọ ọna abayọ.

Ọjọ Aje ni ijọba orilẹ-ede Saudi Arabia kede pe irinajo mimọ Hajj ko ni waye fun ọpọ eero lọdun 2020.

Wọn ni eyi ko ṣẹyin itankalẹ aarun coronavirus to n ran kiri agbaye, to si ti de orilẹ-ede to le ni aadọwa.

Ibudo Hajj

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita loju opo Twitter wọn, ijọba Saudi sọ pe awọn eeyan to n gbe l'orilẹ-ede naa nikan ni yoo ni anfaani lati kopa, lai fi ti ẹya tabi orilẹ-ede ti wọn ti wa ṣe.

Ṣaaju asiko yii, gbogbo orilẹ-ede kaakiri agbaye ni awọn ẹlẹsin Islam ti maa n lọ si Mecca ati Medina lati ṣe Hajj lọdọọdun. O si maa n to miliọnu meji eeyan to maa n kopa ninu eto ẹ̀sìn naa.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Awọn alaṣẹ sọ pe igbesẹ naa jẹ ọna lati pa ofin tita kete siraẹni mọ.

"A gbe igbesẹ yii lati le mu ki Hajj o waye ni ayika to ba ilana eto ilera mu, ati lati daabo bo awọn eeyan lọwọ ewu to rọ mọ aarun naa, to si jẹ ọkan lara awọn ilana ẹsin Islam pe lati da ẹmi eniyan si i."

Eniyan 161,005 lo ti ni coronavirus ni Saudi Arabia, 1,307 si ti ku. Koda, opin ọsẹ to lọ ni ijba gbe ẹsẹ kuro lori ofin isede.