Ogun Majek: Ọmọ, ẹbí àti àwọn òṣèré tíátà ló péjú sìnkú olóògbé

Gbajumọ osere tiata to doloogbe ni idaji ọjọru, Gbolagade Majekodunmi ti wọ kaa ilẹ sun ni ọsan oni.
Abule oloogbe naa, ti ọpọ eeyan mọ si Ogun Majek, to wa ni agbegbe Elesude, lọna Ọmi ni ilu Ibadan ni wọn yoo sin wọn si.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìròyìn Yàjóyàjó - Ogun Majek jáde láyé
- Eji Gbadero, ọmọ Ibadan àti jayé-jayé ọmọ ónílẹ̀ ti wọn yẹgi fun l'Eko
- Èyí ni àwọn arẹwà ‘ẹ̀lẹ̀ Daddy’, àfẹ́fẹ́ tí Aláàfin fi ń mí
- Mùjẹ̀-mùjẹ̀ ní Akinyele tún ti mu ẹ̀jẹ̀ obìnrin míràn lónìí
- Oyè adelé alága APC bọ́ lọ́wọ́ Ajimobi, Buhari fòǹtẹ̀ lu Giadom
- Ọkùnrin kan bá ọmọ oṣù mẹ́ta lòpọ̀, ìfun ọmọ tú jáde!
Ẹbi, ara awọn ọmọ ati ojulumọ to fi mọ awọn osere tiata lo peju sibi isinku Ogun Majek.

Ilana ẹsin musulumi ni wọn fi sin oku agba osere ọhun, ti awọn ọmọ rẹ si n sọkun pe o digbo se.
Àlàyé rèé lórí ikú tó pa Ogun Majek
Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo ti salaye pe, ilumọọka osere tiata Gbolagade Akinpelu, ti ọpọ eeyan mọ si Ogun Majek ti jade laye.
Ọrẹ timọtimọ Ogun Majek ti wọn tun jọ jẹ oṣere tiata, Musiliu Dasofunjo, ti ọpọ eeyan mọ si Esu laalu, lo fi idi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba.
Dasofunjo ni ibanujẹ ọkan lo jẹ fun oun nigba ti oun gbọ nipa iku ọrẹ oun yii, nitori ko dagba debi to yẹ ko ku lasiko yii.
Ki lo pa Ogun Majek to jade laye?
Dasofunjo ni wọn gbe Majek digbadigba lọ si ileewosan UCH ni Ibadan, nigba ti aisan rẹ fẹ bọwọ sori amọ ẹpa ko boro mọ.
O fikun wi pe, kii se pe agba lo de si ọrẹ oun nitori ọjọ ori rẹ ko tii to nnkan, amọ asiko ti to, ni Majek fi di ero ọrun.

Oríṣun àwòrán, Foluke Daramola Instagram
Aisan kidinrin ati aisan itọ suga ni Majek ti n ba finra fun ọpọlọpọ ọdun ko to jade laye.
Dasọfunjo fikun pe, aago meji ọsan oni ni wọn yoo sin Majek gẹgẹ bi ilana ẹsin musulumi.
Ọrẹ timọtimọ Ogun Majek, Musiliu Dasofunjo ni ilu wọn ni agbegbe Elesude, lọna Ọmi ni ilu Ibadan ni wọn yoo sin wọn si.
Musiliu Dasofunjo ni awọn ẹgbẹ oṣere Yoruba ni yoo ṣeto isinku rẹ.
Iru eniyan wo ni Ogun Majek to jade laye?
Musiliu Dasofunjo wa sapejuwe Ogun Majek gẹgẹ bi ẹni to ni suuru, ti kii si fa wahala.
"Majek jẹ ẹni ti ko si nkan ti ko ba lara mu, to si tutu ni iwa."

Oríṣun àwòrán, Others
Dasofunjo tun ni "laarin ọpọ eniyan, Majek jẹ ẹni to lawọ, ti ko ba ni, o maa n jẹ ibanujẹ ọkan fun un."
Dasofunjo ni ohun to dun oun ju ni pe, oun ko ni ri mọ, ti wọn ko si ni lee sọrọ lori ẹrọ ilewọ mọ.












