APC caretaker committee: Nkan márùn ún tí àwọn adarí ẹgbẹ́ gbọdọ́ ṣe kíákíá kí nkan ó má lọ yíwọ́

Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Bashir Ahmed

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 2020, ni igbimọ oludari ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, ṣe ipade lati fi opin si wahala to ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ wọn.

Aarẹ Muhammadu Buhari si tun tu igbimọ oludari ẹgbẹ naa ka, nibi ipade pajawiri naa to waye nile Aarẹ.

Igbimọ oludari naa lo da Adams Oshiomole duro gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ.

Buhari si fi igbimọ ẹlẹni mẹtala rọpo wọn, to si jẹ pe gomina ipinlẹ Yobe, Mai Mala Buni ni alaga wọn.

Awuyewuye ati arinyanjiyan oriṣiriṣi lo si ti n waye lori awọn ti ẹgbẹ oṣelu APC, ṣẹṣẹ yan sipo adari ẹgbẹ.

Awọn ọmọ igbimọ oluṣakoso ẹgbẹ tẹlẹ sọ pe nkan ti aarẹ ṣe ko ba ofin mu.

Awọn oludari ẹgbẹ APC

Oríṣun àwòrán, Bashir Ahmed

Awọn mejidinlogun naa, ti Hilliard Eta n dari, jẹ alatilẹyin Adams Oshiomole ti wọn yọ nipo alaga.

Wọn si fẹnuko pe ipade igbimọ alaṣẹ ti ẹgbẹ ṣe lọjọ ẹti ko ba ofin mu.

Wọn ni Alaga Apapọ ati awọn ọmọ igbimọ oludari nikan lo lẹtọ lati pe iru ipade bẹ ẹ.

Wọn si tun gbọdọ fi ikede sita lọjọ mẹrinla ṣaaju ọjọ ipade, tabi ọjọ meje, to ba jẹ pajawiri ni.

Pẹlu ikunsinu wọn yii, o ṣeeṣe ki wọn o lọ sile ẹjọ.

Eyi lo mu ki a ṣe akọsilẹ diẹ lara ipenija to ṣeeṣe ki igbimọ tuntun yii koju.

Aworan lati ibi ipade igbimọ oludari ẹgbẹ oṣelu APC to waye lọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kẹfa, ori ayelujara si ni awọn kan ti ko pa

Oríṣun àwòrán, Bashir Ahmed

Àkọlé àwòrán, Aworan lati ibi ipade igbimọ oludari ẹgbẹ oṣelu APC to waye lọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kẹfa, ori ayelujara si ni awọn kan ti ko pa

Ṣe ilaja laarin awọn ọmọ ẹgbẹ to n binu

Ọkan lara ipenija to wa nilẹ fun awọn olori ẹgẹ naa lasiko yii ni lati pari ija to wa laarin awọn ọmọ ẹgbẹ, ki ọrs to de ile ẹjọ.

Nitori o ṣeeṣe ki iru awọn aawọ bẹ ni ipa ti ko tọ lara ẹgbẹ naa ninu idibo gomina ipinlẹ Edo.

Iṣọkan ẹgbẹ

Ajeje ọwọ kan ko gbẹru d'ori, agbajọws la fi n sọya.

Ireti ati iwoye ọpọ eeyan ni pe ki awọn olori tuntun yii o wa ọna ti wọn yoo fi fa awọn ọmọ ẹgbẹ wọn bi miliọnu mẹrindinlogun mọra.

Awọn onimọ kan nipa oṣelu ti ẹ sọ pe awọn olori tuntun naa gbọds bẹrẹ ijiroro pẹlu awọn adari ẹgbẹ ni gbogbo ipinlẹ, lati wa ọna ti iṣọkan yoo gba pada sinu ẹgbẹ.

Wọn ni eyi yoo le dena ki APC o ma ni iriri ohun to ṣe PDP l'ọdun 2015.

Aṣeyọri ninu eto idibo Edo ati Ondo

Nkan pataki ti igbimọ alamojuto tuntun naa gbọdọ mojuto ni ipalẹmọ fun idibo gomina ipinlẹ Edo ati Ondo.

Wọn gbọdọ ṣe eto ati ilana to le mu ki ẹgbẹ wọn o bori.

Eyi gbọdọ waye, paapa ni ipinlẹ Edo, nibi ti wahala ti waye lori idibo abẹnu wọn.

Gomina Godwin Obaseki ti wọn ko fun ni tikẹẹti, ti darapọ mọ ẹgbẹ PDP, yoo si fẹ ẹ nira lati gba ipo naa lọwọ rẹ.

Awọn oludari ẹgbẹ APC

Oríṣun àwòrán, Bashir Ahmed

Nipinlẹ Ondo, igun meji lo wa ninu ẹgbẹ APC.

Ija si ti n waye ni olu ile ẹgbẹ, to si ṣe eṣe ko ni ipa lori ẹni tio yoo ṣoju ẹgbẹ.

Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹsan, ati ọjọ kẹwa, oṣu Kẹwa, ọdun 2020, ni idibo mejeeji yoo waye.

Tun orukọ ẹgbẹ naa ṣe l'oju awọn ọmọ Naijiria

Lati bi ọdun melo kan, ni awọn ọmọ Naijiria lo da bi ẹni pe orukọ ẹgbẹ naa ati awọn olori ẹgbẹ APC, ti n dibajẹ lọkan awọn ọmọ Naijiria.

Eyi ko ṣẹyin bi ọpọ ṣe ni wọn ko mu ileri ti wọn ṣe lasiko ipolongo ibo ṣẹ.

Nitori naa, awọn olori tuntun naa gbọdọ tun orukọ naa ṣe.

Ki wọn o si ri pe awọn gomina, ati awọn miran ti wọn dibo yan ninu ẹgbẹ naa n ṣe daada fun araalu.

Ipagọ ẹgbẹ to ni akoyawọ

Nkan miran ti igbimọ oludari ẹgbẹ APC tun gbọdọ mojuto ni ṣiṣe ipagọ/ipade ẹgbẹ, ti ko ni mago-mago ninu.

Ọna ti wọn ba gbe e gba ni yoo sọ boya ẹgbẹ naa yoo duro, paapa iru awọn eeyan ti wọn ba fun ni tikẹẹti ẹgbẹ lati dije dupo.

Tinubu

Oríṣun àwòrán, TWITTER

Àkọlé àwòrán, Nibi ipade kan to waye ni ile Aarẹ ni Abuja ni Aare Muhammadu Buhari ti tu Igbimọ Amuṣẹya ẹgbẹ oselu APC ka.

Tinubu, oju ti ẹ, o ta ilẹ Yoruba fun ọta rẹ nitori adanikanjẹ- Femi Fani-Kayode

Oloselu Femi Fani Kayode ti kọ lẹta ranṣe si Asiwaju Bola Ahmed Tinubu lẹyin ti Aarẹ Muhammadu Buhari yan Alaga fidiẹ tuntun fun ẹgbẹ oṣelu APC.

Oloṣelu ni ẹgbẹ oṣelu PDP, Femi Fani-Kayode ti fi lẹta itagbangba ranṣẹ si Asiwaju Bola Ahmed Tinubu lori igbesẹ Aarẹ Buhari to yan gomina ipinlẹ Yobẹ gẹgẹ bi Alaga fidiẹ fun ẹgbẹ oṣelu APC.

Fani Kayode ninu lẹta naa ni bi oun ṣe fẹran tilẹ jẹ iwa rẹ lo mu ki oun sa fun un nitori imọtara ẹni nikan n ba ja.

O ni Aarẹ Buhari to fi ṣe ọrẹ ti sọ di ọta, ti gbogbo ero rẹ lori ẹgbẹ oṣelu APC si ti jasi pabo.

Femi Fani Kayode ni bi o tilẹ jẹ pe Asiwaju ti gbekele ara rẹ wi pe oun ko le e ṣi ṣe, ọrọ yii ti ba ẹyin yọ pẹlu bu Aarẹ Buhari ṣe pada lẹyin rẹ, ti wọn si ri pe ko ni ipo kankan mọ ninu ẹgbẹ oṣelu APC.

'Tinubu ta ẹmi rẹ, ta ọkan rẹ, to si ta gbogbo ilẹ Yoruba, to fi mọ Guusu ati Ariwa orilẹede Naijiria lati le ri wi pe oun mu gbogbo ero ọkan rẹ to kun fun ibi ṣẹ.

O fikun wi pe gbogbo ilakaka rẹ lati jẹ aarẹ orilẹede Naijiria ni ọdun 2015, 2019 ati 2023 lo ti ja si pabo bayii.

Bakan naa lo ni kaka ki Tinubu o ba aarẹ Buhari sọrọ lati wuwa rẹrẹ si awọn ọmọ Naijiria, ki iya ma ba jẹ wọn, niṣe ni Asiwaju n gbe lẹyin Buhari, ẹni to wa jakulẹ bayii.

Ọrọ ipari rẹ ninu lẹta naa ni wi pe o ti tan fun Tinubu ninu oṣelu orilẹede Naijiria, oun ti o ku ni ki o lọ rọkun nile, ki o si ma a sinmi.

O gba ni adura pe lasiko ifẹyinti Tinubu, ohun gbogbo to ti bajẹ lorilẹede Naijiria yoo gba atunṣe.

Oyè adelé alága APC kúrò ní gúúṣù Nàíjíríà, ó bọ́ sẹ́kùn àríwá

Gomina ipinlẹ Yobe, Mai Mala Buni ti di Alaga ẹgbẹ oṣelu APC tuntun ni Naijiria.

Eyi ko ṣẹyin bi Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe tu igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ oselu APC ka, ti o si fi igbimọ fidiẹ sibẹ.

Ami idamọ ẹgbẹ oselu APC

Oríṣun àwòrán, APcNG

Oluranlọwọ fun Aarẹ Buhari lori ọrọ iroyin, Bashir Ahmad lo fi ọrọ yii lede loju opo ikansiraẹni Twitter rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni wọn fikun pe, laipẹ ni wọn yoo fi kede ọjọ ti wọn too ṣe ipade apapọ ẹgbẹ.

Bẹẹ ba gbagbe, Adams Oshiomole lati ẹkun guusu Naijiria ni alaga tẹlẹ fun ẹgbẹ oselu APC, ko to di pe ileẹjọ yẹ aga mọ nidii.

Ireti ọpọ ọmọ ẹgb oselu naa si ni pe ẹkun guusu Naijiria ni wọn yoo pada ti yan alaga afunsọ fun ẹgbẹ oselu naa.

Buhari

Oríṣun àwòrán, Others

Koda, ẹgbẹ APC ti kọkọ yan gomina ana nipinlẹ Oyo, Abiola Ajimobi gẹ́gẹ bii adele Alaga ẹgbẹ, amọ Ọjọru ni wọn tun yan Geidom rọpo rẹ.

Ibeere ti ọpọ eeyan wa n beere ni pe ki ni yoo jẹ ireti awọn ọmọ ẹgbẹ APC lẹkun guusu Naijiria ni bayii ti alaga afunsọ ẹgbẹ APC tun ti lọ si ẹkun ariwa Naijiria?

Bẹẹ ba si gbagbe, ẹkun ariwa Naijiria yii naa ni aarẹ Muhammadu Buhari ti wa.

Ta ni Victor Giadom?

Ọmọ ipinlẹ Rivers ni ẹkun Gusu-Gusu Naijiria ni Victor Giadom, ti wọn ṣẹṣẹ kede ni Adele Alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC.

Giadom ti jẹ kọmiṣọnna fun akanṣe iṣẹ ni ipinlẹ Rivers, lasiko ti Minisita fun eto irinna ni Naijiria, Rotimi Amaechi fi jẹ gomina ipinlẹ naa.

Ajimobi ati Giadom

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Awọn alaṣẹ ẹgbẹ APC ni ipinlẹ Rivers ti kọkọ da Giadom duro, "fun pe o tako ilana ati agbakalẹ ẹgbẹ".

O ti fi igba kan jẹ ọmọ igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ APC, ko to fi ipo naa silẹ lati dije fun ipo igbakeji gomina ipinlẹ Rivers l'ọdun 2019.

Sugbọn ipo naa ko jamọ oun ati Tonye Cole to fẹ ẹ di gomina lọwọ.

Lẹyin naa lo tun pada si ipo to fi silẹ gẹgẹ bi Igbakeji Akọwe Apapọ ẹgbẹ.

Ṣaaju ki wọn o to kede rẹ gẹgẹ bi adele alaga ẹgbẹ APC, Giadom ni igbakeji Akọwe Apapọ ẹgbẹ naa.

Ṣugbọn, ẹgbẹ ti da a duro l'ẹnu iṣẹ rẹ tẹlẹ.

Awọn alaṣẹ ẹgbẹ naa ni ipinlẹ Rivers lo da a duro, "fun pe o tako ilana ati agbakalẹ ẹgbẹ".

Koda, ile ẹjọ giga kan nipinlẹ Rivers fi ofin de Giadom pe ko gbọdọ pe ara rẹ ni ọmọ ẹgbẹ tabi oloye ninu ẹgbẹ APC mọ.

Ni kete ti ile ẹjọ kotẹmilọrun fi idi idaduro alaga ẹgbẹ APC tẹlẹ mulẹ ni Giadom ti kede ara re,

Adams Oshiomole ni ile ẹjọ yọ l'ọsẹ to kọja ti Giadom si ni oun ni Adele Alaga ẹgbẹ ni kete ti.

Igbesẹ rẹ lati rọpo Oshiomole ti bẹrẹ lati igba ti Oshiomole ti n koju wahala idaduro ninu ẹgbẹ nibẹrẹ ọdun 2020.

Lẹyin eyi lo kọwe si ajọ eleto idibo, INEC, pe oun ti fagile eto idibo abẹle lati yan oludije fun ipo gomina ipinlẹ Edo.

O ni ko ba ofin mu, nitori pe oun ko fi aṣẹ sii.

Ọjọru si ni gbogbo awuyewuye to n waye lori ẹni ti yoo jẹ alaga fun ẹgbẹ oselu APC da bi pe o ti dopin.

Idi ni pe Aarẹ Muhammadu Buhari ti kede pe ẹni to yẹ nipo igbakeji alaga fun ẹgbẹ oselu APC ni igbakeji alaga ẹgbẹ tẹlẹ, Victor Giadom.

Wakati diẹ lẹyin ti Aarẹ Buhari fi atilẹyin rẹ fun Giadom han, ni Giadom kede pe ipade igbimọ amuṣẹya ati igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ yoo waye lọjọbọ.

Oun fun'ra rẹ lo fi ọwọ si atẹjade ikede ipade naa ti yoo waye lori ayelujara.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bi ẹ ko ba gbagbe, ileẹjọ lo yọ alaga tẹlẹ fun ẹgbẹ oselu APC, Adams Oshiomọlẹ, ti igbimọ amusẹya ẹgbẹ si kede pe Senatọ Abiola Ajimobi ni ipo naa tọ si.

Lati igba naa si ni ara ko rọ okun, ti ko si rọ adiẹ ninu ẹgbẹ oselu APC.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ fun Aarẹ Muhammadu Buhari, Garba Shehu fi sita loju opo Twitter rẹ lorukọ aarẹ orilẹ-ede yii lo sisọ loju ọrọ naa.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Shehu ni aarẹ ti gba imọran to daju nipa ohun ti ofin ilẹ wa sọ lori awọn isẹlẹ to n waye ninu ẹgbẹ oselu APC, to si fara mọ pe ẹyin Victor Giadom ni ofin gbe si.

"Bakan naa, nitori pe aarẹ Buhari maa n wa lẹyin ofin, aarẹ yoo ba adele alaga tuntun naa se ipade lati ori ẹrọ ayelujara ni ọsan ọla."

Ileesẹ aarẹ wa rọ awọn akọroyin lati dẹkun dida awuyewuye silẹ, ki wọn ma si faaye gba sise itumọ ofin lọna odi lori ọrọ naa.

Abiola Ajimobi

Oríṣun àwòrán, Instagram/Abiola Ajimobi

Àkọlé àwòrán, Ọ̀pọ̀lọpọ̀ awuyewuye ló tí súyọ lẹ́yìn tí ẹgbẹ́ òṣèlú APC kéde Abiola Ajimobi gẹ́gẹ́bí igbákejì alága APC.

Mí ò bẹ̀bẹ̀ fún oyè igbákejì alága APC kí wọ́n tó ó fún mi - Abiola Ajimobi

Gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ, Abiola Ajimobi ti sọ pe awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC gbagbọ ninu oun ni wọn ṣe fi oun jẹ igbakẹji alaga ẹgbẹ naa.

Ajimobi ni kii ṣe pe oun bẹbẹ fun ipo ọhun, ṣugbọn awọn alakoso APC ri oun gẹgẹ bi ẹni to ṣe e fọkan tan ni wọn ṣe fi oun si ipo naa ni iha guusu Naijiria.

Nigba to n fesi si ọrọ ti awọn alatako rẹ lori ipo tuntun naa, Ajimobi sọ pe ẹgbẹ APC mọ iru atunṣe rere ti oun lee mu ba ẹgbẹ naa ni guusu Naijiria ati ni orilẹ-ede yii lapapọ.

Ajimobi, ninu ọrọ naa to fi sita latẹnu agbẹnusọ rẹ, Bolaji Tunji, sọ pe awọn eniyan ipinlẹ Oyo ko le gbagbe ipa ribiribi ti oun ko lasiko iṣejọba bii Gomina ipinlẹ Oyo.

O sọ pe nitori naa, ti awọn alaṣẹ ẹgbẹ APC ba lero pe oun ni ipo naa yẹ, ko si alatako to le e yi pada.