D'banj's rape accusation: Ẹ wo ìṣẹ̀lẹ̀ nípa ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ tí wan fi kan D'banj ní sísẹ̀n tẹ̀lé

Dbanj ati Seyitan

Oríṣun àwòrán, Dbanj ati Seyitan

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lati bi ọsẹ melo kan ni gbajugbaja akọrin takasufe l'orilẹ-ede Naijiria, D'Banj,ti wa ninu iroyin.

Bo tilẹ jẹ pe, kii ṣe fun nkan to dara.

Ọmọbinrin kan, Seyitan Babatayo lo fi ẹsun ifipabanilopọ kan Oladapo Daniel Oyebanjo 'D'Banj'.

Ẹkunrẹrẹ alaye re e lori bi ọrọ naa ṣe lọ:

Ibẹrẹ oṣu Kẹfa, ọdun 2020 ni wahala naa bẹrẹ, lasiko ti olootu arinrinoge kan, Benjamin Ese, sọ pe D'Banj fi ipa ba ọrọ oun kan lopọ nile itura kan ni Eko l'ọdun 2018.

Ẹsun naa jade lẹyin ti D'banj darapọ mọ awọn gbajumọ bi ti ẹ lati polongo tako ifipabanilopọ.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

Ọrọ ti D'banj kọ sori ayelujara yii lo bi Ese ninu. To si fi fun gbajugbaja naa l'esi pe, ọwọ ti ẹ naa ko mọ́.

Ese ṣalaye ninu ọrọ kan to kọ sori Instagram nigba naa pe D'banj fi ẹgbẹrun lna igba Naira lọ ọrẹ oun lati ba lopọ, ṣugbọn ó kọ̀.

Ninu ọrọ naa to ti parẹ bayii, Ese sọ pe onkọrin naa gba ẹ̀dà kọkọrọ to ṣi ilẹkun yaara ti ọmọbinrin naa sun si nile itura.

Lẹyin naa lo wọ yaara rẹ balopọ ni tipatipa.

Seyitan

Oríṣun àwòrán, Seyitan/instagram

Àkọlé àwòrán, Seyitan Babatayo to fi ẹsun kan D'banj

Ọmọbinrin naa f'oju han si gbangba

Lẹyin ti Ese fi alaye ọrọ naa sita ni ọmọbinrin kan, Seyitan Babatayo jade sita pe oun ni ẹni naa.

Ninu ọrọ kan to kọ sori Twitter, o sọ pe oun lọ si ayẹyẹ asẹmọju kan ti amugbalẹgbẹ D'banj, Franklin pe oun si ni Eko Atlantic.

O ni lẹyin ti ayẹyẹ naa pari, oun lọ si yaara ti oun gba ni ile itura Glee, to wa ni Victoria Island.

Igba to de yaara rẹ, o ni ọmọbinrin kan ti oun pade nibi ayẹyẹ naa pe e pe D'banj ri nibi ayẹyẹ, o si nifẹ lati wa pẹlu rẹ lalẹ ọjọ naa.

Ṣugbọn, Seyitan sọ pe oun kọ jalẹ.

"Ni nkan bi aago maarun si mẹfa owurọ ni oorun gbe mi lọ. Jiji ti mo si ji ni mo ri D'banj ninu yaara mi.

Mo beere lọwọ rẹ pe ki lo wa ṣe ninu yaara mi, esi to fun mi ni pe ṣe ọmọde ni mi ni.

Lo ba bẹrẹ si ni ki ika ọwọ rẹ bọ oju ara mi (ihoho ni mo ma n sun).

"Mo kilọ fun pe maa pariwo, lo ba dahun pe ihoho ni maa kuro ni ile itura naa, ti mo ba fi pariwo.

Igba to jade pada ni mo ṣakiyesi pe ẹdà kọkọrọ lo fi wọ yaara naa.

Ṣugbọn ile itura Glee ti sọ pe irọ ni pe akọrin naa fi ipa ba ẹnikan lopọ ni ọdọ wọn.

Wọn si fi ikede sita pe kii ṣe ootọ pe awọn fun D'banj ni kọkọrọ si yaara naa.

Àkọlé fídíò, Say no to rape: Àwọn òṣèré tíátà Yorùbá pariwo síta lórí wàhálà ìfipábánilòpọ̀

D'banj fi iwe owo itanran da Seyitan l'ohun

Ọsẹ kan lẹyin ti ẹsun naa jade ni D'banj to o f'esi lẹyin ayẹyẹ ọjọ ibi ogoji ọdun to ṣe lọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2020.

O ni "irọ lati ọrun apaadi ni ẹsun naa".

Bakan naa lo kede lati ẹnu agbẹjọro rẹ, Mike Ozekhome(SAN) pe ki Seyitan o san ọgọrun miliọnu Naira fun oun lati tu oun ninu.

O si tun ni ko kọ iwe ẹbẹ. Gbogbo eyi lo gbọdọ ṣe laarin wakati mejidinlaadọta, ti ko ba fẹ lọ sile ẹjọ.

Nibo gan-an ni Seyitan wa?

Ori ayelujara gbona janjan lori iṣẹlẹ yii, paapa nigba ti iroyin jade pe awọn ọlọpaa ti mu Seyitan.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Skip X post, 2

End of X post, 2

Iroyin naa sọ pe ọpọlọpọ wakati lo fi wa ni agọ ọlọpaa, ti wọn si tun ni ko pa gbogbo nkan to kọ nipa ẹsun rẹ lori ayelujara.

Bakan naa lo kọ pe irọ ni pe awọn ọlọpaa mu oun lasiko to fi wa lọdọ wọn.

Koda, o tun polongo fidio orin D'banj loju opo ayelujara rẹ.

Oṣerebinrin, Dorcas Shola Fapson sọ pe oun ti ba Seyitan sọrọ.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Ootọ si ni awọn ọlọpaa mu, ti wọn si tun gba dukia rẹ.

Nibo ni nkan de duro?

Ko pẹ to kuro ni agọ ọlọpaa ni Seyitan fi ikede kan sita pe lootọ ni ọlọpaa mẹrin gbe oun lọ si agọ wọn ni Shodipo, Ikeja.

Wọn si fi si ihamọ fun bi i wakati mejidinlaadọta lai fi ẹsun kankan kan-an.

O tun sọ ninu ikede naa pe D'banj fi ipa ba oun lopọ.

Ati pe oun ti fi ẹjọ sun ni agọ ọlọpaa.

Sibẹsibẹ, D'banj ko ti i sọ nkankan lori rẹ, yatọ si fidio kan to fi n jo si orin rẹ kan 'Ọlọrun ma jẹ'.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

O si kọ ọrọ si abẹ fidio naa pe 'funfun ni ọwọ oun mọ, titi ti wọn ba fi da oun l'ẹbi'.

Lootọ ni ọrọ ko ti i de ile ẹjọ, ṣugbọn Ọga Agba ọlọpaa ni Naijiria, Mohammed Adamu, ti paṣẹ pe ki iwadii o bẹrẹ lori rẹ.