Obìnrin tí àwọn dókítà gbàgbé sísọ́ọ̀sì sínú rẹ̀ lásìkò iṣẹ́ abẹ jáde láyé

Obinrin naa ati aworan sisọọsi ninu rẹ

Oríṣun àwòrán, Abubakar Muhammad

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Obinrin kan, Aishatu Umar, ti jade laye lẹyin ti awọn dokita gbagbe sisọọsi sinu rẹ lasiko iṣẹ abẹ kan nile iwosan Abubakar Imam, to wa nipinlẹ Kano.

Ohun ti a gbọ ni pe ọjọ Aiku ni iya ọlọmọ marun un naa ku lasiko iṣẹ mii lati yọ abẹ ti wọn gbagbe sinu rẹ ṣaaju.

Abubakar Mohammed, to jẹ ọkọ rẹ ṣalaye fun BBC pe fun ọpọ oṣu ni iyawo oun fi jẹ irora lẹyin iṣẹ abẹ ti wọn kọkọ ṣe fun ni Imam Urology Centre hospital, ni Kano.

Mohammed ni irora naa tẹsiwaju fun nnkan bii oṣu mẹrin ki wọn to lọ ṣe ayẹwo ni ile iwosan Aminu Kano Teaching Hospital ṣaaju iku rẹ.

O ni ayẹwo naa fi han pe abẹ ti wọn fi ṣiṣẹ abẹ fun ninu oṣu Kẹsan an, ọdun 2025 ṣi wa ninu rẹ sibẹ.

Ọkọ obinrin ọhun sọ pe "Lọjọ meji sẹyin, nigba ti irora naa ko ṣe e farada mọ ni a lọ sile iwosan Aminu Kano Teaching Hospital, nigba ti wọn ṣe ayẹwo, ibẹ lawọn dokita ti ri siọọṣi naa ninu rẹ."

"O n farada irora naa titi di opin ọsẹ to kọja ti ọrọ naa fi yiwọ ti ko si le maa farada irora ọhun mọ.

"Eredi ree ti a fi gbe digbadigba lọ si ẹka iṣẹlẹ pajawiri.

"Wọn gbe digbadigba lọ si ẹka iṣẹ abẹ lati yọ sisọọsi naa amọ a padanu rẹ.

"Wọn ko tilẹ tii bẹrẹ iṣẹ abẹ naa to fi dakẹ, bi wọn n gbe wọ inu yara iṣẹ abẹ ọhun lo fi aye silẹ."

"Irufẹ eeyan ti iyawo mi jẹ"

Oloogbe naa ati ọkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, ABUBAKAR MUHAMMAD

Ọkunrin naa juwe iyawo rẹ gẹgẹ bii obinrin rere lọọdẹ ọkọ ti ẹni to ba fẹ iru rẹ ko ni kabamọ.

O ni "eeyan daadaa ni, ẹnikẹni to ba si ni nnkankan ṣe pẹlu rẹ yoo jẹri pe ootọ ni mo sọ.

"Ohun ti mo saaro julọ nipa iyawo ni pe o jẹ eeyan to ni ifẹ lọkan, o fẹran gbogbo eeyan, awọn eeyan si fẹran rẹ."

Mohammed ni iku iyawo oun jẹ irufẹ eyii ti ko yẹ ko tilẹ waye rara to ba jẹ pe awọn to kọkọ ṣiṣẹ abẹ mọ ohun ti wọn n ṣe.

Ni bayii, ijọba ipinlẹ Kano ti paṣẹ ki awọn mẹta to ṣiṣẹ abẹ naa lọ rọọkun nile na.

Ajọ to n ri si ọrọ ile iwosan, State Hospitals Management Board, sọ ninu atẹjade kan pe oun yoo fi iya to tọ jẹ gbogbo awọn ti ọro iku obinrin naa kan.