America so fífún Naijiria àti orílẹ̀èdè 74 míràn ní físà rọ̀ láì ní gbèdéke

Aworan awọn arinrinajo ati patako to n ki wọn kaabọ si America

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ẹka to n ri si fifun awọn arinrinajo ni fisa lọ silẹ America ti kede pe ko ni i si gbigba fisa lọ si orilẹede naa fun Naijiria ati awọn orilẹede mẹrinlelaadọrin miran, bẹrẹ lati ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 yii.

Ikede naa ṣalaye pe igbesẹ yii n waye pẹlu aṣẹ ti ẹka naa lati America, pa fun awọn oṣiṣẹ ẹka ọfiisi awọn orilẹede ti ofin yii kan.

Wọn fi kun un pe ai ni i ṣiṣẹ lori fisa wọn yii ko ti i ni i gbedeke igba ti yoo wa sopin, yoo maa wa bẹẹ titi ti wọn yoo fi pari awọn ayẹwo to yẹ ni.

Igbesẹ tuntun yii lo n waye lẹyin ọsẹ kan pere ti ijọba Aarẹ Trump kede owo asansilẹ (visa bond), to to $15,000 fun orilẹede mejidinlogoji to ba fẹ lọ si America, eyi ti Naijiria naa wa ninu wọn.

Kí ló fà á tí America fi bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ yìí?

Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ to n ri si fisa gbigba lọ s'America fi si oju opo X wọn l'Ọjọru, eyi ti wọn fi kede iroyin naa ni wọn ti ṣalaye pe:

"Ẹka ileeṣẹ wa yoo sinmi ṣiṣẹ fisa fun orilẹede 75 ti awọn arinrinajo lati ibẹ maa n di bukata si orilẹede wa lọrun ti wọn ba de, ni ọna ti a ko faramọ.

Idawọduro fisa yii yoo wa bẹẹ titi ti America yoo fi ri idaniloju pe awọn arinrinajo tuntun to n wọle ko ṣe akoba fun ọrọ aje awọn eeyan America.

"A n ṣiṣẹ lati ri i pe wọn ko tẹ ẹtọ awọn eeyan America loju. Ijọba Trump yoo maa ri i daju pe America lo ṣaaju."

Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa ṣalaye.

Ofin tuntun yii bi wọn ṣe wi, wa lati dena awọn to n wọ America lati maa jẹ ọrọ̀ ilu naa, to si le pa awọn ọmọ oniluu lara.

Bakan naa lo wa fun awọn orilẹede ti awọn eeyan wọn maa n pẹ ju bo ṣe yẹ lọ l'America, ati awọn ti gbigbe l'America wọn lewu lẹka aabo.

Bi ẹka US State Department ṣe kede, igbesẹ tuntun yii kan awọn oriṣi fisa bii awọn to n lọ fun irinajo afẹ, awọn to fẹẹ lọ kawe ati awọn to fẹẹ lọ ṣiṣẹ l'America.

Awọn orilẹede ti ọrọ yii kan ni:

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Orilẹede Africa mẹtadinlọgbọn (27) ni ofin yii kan, eyi ti Naijiria jẹ ọkan lara wọn.

Awọn orilẹede apa Asia to kan jẹ mejilelogun (22), apa Europe jẹ mẹjọ, mẹtala lati ẹkun North America ati awọn orilẹede Carribean, orilẹede mẹta lapa South America ati orilẹede kan lati Oceania.

Awọn orilẹede naa ni:

Naijiria, Algeria, Cameroon, Cape Verde, Cote d'Ivoire, Democratic Republic of the Congo, Egypt, Eritrea, Ethiopia, Gambia, Ghana, Guinea, Liberia, Libya, Morocco, Republic of Congo, Rwanda, Senegal, Sierra Leone, Somalia, South Sudan, Sudan, Tanzania, Togo, Tunisia, Uganda ati Yemen.

Awọn mi-in ni Afghanistan, Armenia, Azerbaijan, Bangladesh, Bhutan, Burma, Cambodia, Georgia, Iran, Iraq, Jordan, Kazakhstan, Kuwait, Kyrgyzstan, Laos, Lebanon, Mongolia, Nepal, Pakistan, Syria, Thailand and Uzbekistan.

Bakan naa lo kan Albania, Belarus, Bosnia, Kosovo, Macedonia, Moldova, Montenegro, Russia, Antigua and Barbuda, Bahamas, Barbados, Belize, Cuba, Dominica, Grenada, Guatemala, Haiti, Jamaica, Nicaragua, Saint Kitts and Nevis, Saint Lucia, Saint Vincent, Grenadines, Brazil, Colombia, Uruguay ati Fiji.