Ìjọba America fẹ́ wọ́gilẹ́ tẹ́tẹ́ oríire físà H-1B, àmọ́ kí ni wọ́n fẹ́ fi rọ́pò rẹ̀?

Oríṣun àwòrán, Chip Somodevilla/Getty Images
Iṣejọba Donald Trump fẹ wọgile fisa H-1B.
Ti wọn si fẹ fi nnkan to jọ iye owo ti n eeyan n gba ti yoo ṣe anfani pupọ fun awọn eeyan ti yoo san owo to tobi.
Labẹ igbesẹ yii, awọn oṣiṣẹ ti wọn n gba owo oṣu to tobi yoo ni anfani lati fi orukọ silẹ ni ọpọ igba, ti awọn eeyan ti wọn ko ni ọpọ owo yoo ni anfaani lẹẹkan soso.
Eyi n waye lẹyin ti ijọba fowokun owo fisa si $100,000 ni ẹnikọọkan.
Awọn alatako kilọ pe igbesẹ Trump ko ni fi aye silẹ fun awọn mẹkunu lati rọwọ mu ṣugbọn awọn olowo nikan.
Ki ni erongba fisa tuntun
Ijọba Amẹrika ni awọn gbe igbesẹ lati da abo bo awọn ọmọ ilu lọwọ aigba owo to yẹ pẹlu awọn oṣiṣẹ oke okun.
Aarẹ Donald Trump ṣe ifilọlẹ ofin irinajo yii lẹyin ti wọn bura wọle fun un ninu oṣu kini.
Ofin irinajo ti ijọba Trump gbe kalẹ lo tun pe fun dida awọn eeyan pada ni ọpọ, ti wọn si fopin si fun fun awọn ọmọ ti wọn ba ni ilu ni iwe igbelu lorilẹede Amẹrika.
Laipẹ yii ni iṣejọba naa tun fi ẹgbẹ oju kan wo fisa H-1B, eyi to jẹ ilumọka pẹlu awọn ileeṣẹ ti wọn n gba awọn oṣiṣẹ lati oke okun.
Ni ọsẹ to kọja ni iṣejọba Trump ni ki awọn ileeṣẹ naa ma san owo toto $100,000 lọdun, to si gbe ilana fisa H-1B fisa.
Awọn ileeṣe yii ti kilọ fun awọn eeyan to ni fisa yii lọwọ pe ki wọn duro si US tabi pe ki wọn da pada ni kiakia.
Igbesẹ lati sọ eyi di aṣẹ ni o ṣeeṣe ko lo ọpọ oṣu tabi ọdun ko to le fi ẹsẹ mulẹ. Igbesẹ daba pe ofin tuntun yoo wa ninu fisa gbigba ti ọdun 2026, o tumọ si pe o le waye ṣaaju oṣu kẹta ọdun to n bọ to pe jẹ asiko iforukọ silẹ.
Trump to wa lati ẹgbẹ oṣelu Republican ti n gbiyanju lati ṣe atunṣe si fisa H-1B lati igba ṣaa rẹ akọkọ 2017 si 2021 ṣugbọn akoko ko to fun nitori igbẹjọ ati igba ti ṣaa rẹ pari si.
Ile ẹjọ dena de igbesẹ yii ni oṣu kẹsan an lasiko iṣejọba Aarẹ Joe Biden.
Ṣaaju asiko yii, gbogbo awọn owo ti awọn eeyan n san lori fisa H-1B ko ju $1,500 lọ.
Agbẹjọro Tahmina Watson, to jẹ oludasilẹ ileeṣẹ Watson Immigration Law sọ fun BBC pe ofin tuntun yii yoo ṣe akoba nla fun ileeṣẹ atawọn oṣiṣẹ oun.
Alaye lati ajọ US Citizenship and Immigration Services (USCIS) fi han pe, nnkan bii 359,000 eeyan lo ti n gbaradi lati gba fisa naa lọdun to n bọ.
Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, lara ileeṣẹ to janfaani awọn fisa naa sẹyin julọ ni Amazon, atawọn ileeṣẹ imọ ẹrọ igbalode bii Tata, Microsoft, Meta, Apple ati Google.
Jorge Lopez, to jẹ alaṣẹ ajọ Littler Mendelson PC sọ pe, igbesẹ naa yoo fa ọwọ aago awọn ileeṣẹ imọ ẹrọ igbalode ati ọwọ ọpọlọpọ ileeṣẹ mii sẹyin nilẹ Amẹrika.











