Wo àwọn ìwé méjì tí àwọn aláṣẹ̀ ilẹ̀ UK kìlọ̀ pé àwọn tó bá ńlo pásípọ́ọ̀tì rẹ̀ gbọ́dọ̀ ní lọ́wọ́ kí wọ́n tó rìnrìnàjò

Eeyan kan di iwe irinna ilẹ Gẹẹsi mu lori aṣia ilẹ Gẹẹsi.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọọ̀fisi ọrọ okeere lorilẹede Gẹẹsi tig be amọran tuntun kan sita fawọn arinrinajo pe ki wọn rii daju pe awọn iwe meji kan wa lọwọ wọn lasiko ti wọn ba fẹ́ rinrinajo lọ si orilẹede yowu lagbaye.

Yatọ si iwe irinajo soke okun, iyẹn pasipọọti wọn, ọfiisi ọrọ okeere ni orilẹede UK ni awọn eeyan bẹẹ tun gbọdọ ni iwe idanimọ miran miran dani.

Awọn alaṣẹ ọfiisi naa ṣalaye ninu atẹjade ikilọ tuntun ti wọn gbe jade pe ki awọn arinrinajo " tun ni awọn iwe idanimọ onifọto miran, yatọ si iwe irinna pasipọọti wọn."

Bakan naa ni wọn tun rọ awọn to n rinrinajo afẹ tabi okoowo lati rii daju pe wọn ṣeto aibaamọ silẹ lasiko ti wọn ba n rinrinajo naa.

Lara awọn nnkan ti wọn ni ki wọn rii daju pe o wa larọwọto wọn ni ibi ti wọn fẹ de si, iroyin nipa baluu ti wọn fẹ ba rinrinajo, nọmba iwe irinna wọn ati bẹẹlọ. wọn ni eyi ṣe pataki pupọ bi o ba ja si pe wọn padanu foonu wọn lasiko irinajo naa.

Wọn tun kọọ wi pe:"Ẹ ranti lati rii daju pe iwe irinna okeere yin w ani ibamu lati wọ orilẹede ti ẹ ba fẹ lọ.

Oju ewe pasipọọti ilẹ Gẹẹsi kan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn koko miran ti wọn tun sọrọ le lori niwọnyii:

  • Ẹ buwọlu iwe irinna yin ki ẹ si fi awọn nọmba ibanisọrọ ti awọn eeyan le pe bi o ba di pajawiri si oju ewe awọn eeyan to sunmọ yin to wa nibẹ.
  • Ẹ rii daju pe iwe irinna yin ba ilana orilẹede ti ẹ n lọ mu
  • Gba fisa to tọna fun orilẹede ti ẹ n rinrinajo lọ si.
  • Yatọ si iwe irinna pasipọọti rẹ, mu iwe idanimọ miran pẹlu fọto dani.
  • Bi o ba n lọ pẹlu awọn ọmọde, ṣe ayẹwo gbogbo to ba yẹ lati mọ boya o nilo awọn iwe miran.
  • Bi o ba jẹ pe o maa wa ọkọ ni ibi ti o nlọ, ṣe ayẹwo lati mọ boya o nilo lati gba iwe aṣẹ iwakọ.