Kí ló fà á tí pásítọ̀ yìí fi pín kọ́mú fún àwọn obìnrin tó wá jọ́sìn láì wọ kọ́mú?

Oríṣun àwòrán, Reclaimers Ministry
Olusọ aguntan, Isaac Josiah, ti ile ijọsin Reclaimers Ministry niluu Benin nipinlẹ Edo ni ọpọ ẹnu ti n kun lori ayelujara lẹyin to fun awọn ọmọ ijọ rẹ ti wọn ko wọ kọmu wa si ile ijọsin ni kọmu lati wọ
Ninu fọnran to jade soju opo Facebook, lọjọ kẹrinla oṣu kẹsan an ọdun 2025 ṣafihan bi olusọ aguntan naa n pin irọ, kọmu ati awọn nnkan mii fun awọn ọmọ ijọ ti wọn jẹ obinrin.
O ṣapejuwe bi awọn obinrin kan ṣe n wọ aṣọ lai lo kọmu jẹ ohun to tabuku ilana Ọlọrun ati awujọ.
Ninu fọnran ọhun, Olusọ Aguntan Josiah sọ fun awọn aṣọna ile ijọsin naa pe ki wọn fun awọn obinrin kan to ni bi wọn ṣe wọ aṣọ ko da to lawọn iro ati kọmu naa.
O ni oun gbe igbesẹ yii lati ri pe ọkan awọn olujọsin papọ lasiko ijọsin.
"Ni igba ti olugbagbọ ba sọ fun yii pe ago mejila lo lu, ẹ ko n iyi pada, ti o ba ni ọkan to dara, o ko ni wọ aṣọ ti yoo fa awọn eeyan mọra ni ile ijọsin.
"Brọda Osase, Eric, ati Chimere, ẹ w ani ẹnu ilẹkun. Lati oni lọ, obinrin kankan ti a ba ri pe ko wọ kọmu wa si ile ijọsin, a o fun ni kọmu
"Ti a ko ba le yi ọ pada ni ile ijọsin yii, wa ile ijọsin miiran. Wo mi, ọdọmọkunrin ni mi, mo si fẹ lọ si ọrun.
"Ẹni kan pe mi ni ọsẹ to lọ pe ọkunrin kan wa si ile ijọsin wa, ti ọkan rẹ ko si papọ.
"Awọn eeyan wa lati ile wọn si ile ijọsin, wọn n wa iranlọwọ.
'Ti ẹ ba fun obinrin kan kan ni kọmu ti ko gba, ẹ pe, ki ẹ bere pe elo ni owo ọkọ rẹ lọ si ile?
"Fun idi eyi, Brọda Eric, Osase ati Chimere, ile ijọsin yii fun yii ni aṣẹ lati oni lọ."















