Ooni Ile Ife ṣàbẹ̀wò sí Olubadan tuntun, sọ̀rọ̀ nípa oyè Oluọmọ tó ń dá àríyànjiyàn sílẹ̀

Olubadan ati Ooni lasiko ipade wọn nile Olubadan niluu Ibadan

Oríṣun àwòrán, naijanewshub

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ooni Ile Ife, Ọba Adeyeye Babatunde Ogunwusi Ojaja Keji ti juwe iyansipo Olubadan tuntun, Ọba Rasidi Adewolu Ladoja gẹgẹ bii ipele tuntun ninu itan ilẹ Yoruba.

Ọba Aeyeye lo sọ ọrọ yii lasiko to ṣabẹwo si Olubadan nile rẹ to wa lagbegbe Bodija, niluu Ibadan.

Ooni juwe Olubadan gẹgẹ bii ẹni to ni iriri to dantọ lẹyin to ti wa ni ipo Sẹnetọ ati gomina nigba kan ri ko to tun gori itẹ ọba bayii.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, akoko Ladoja bii Olubadan yoo san awọn ọmọ ilu naa nile ati lokeere.

O ni "Ọba Ladoja kii kan n ṣe olori nikan, o jẹ apẹrẹ baba to ni oniruru iriri, a si nilo ọgbọn ati suuru rẹ lasiko yii ju ti tẹlẹ lọ.

"Bẹẹ naa ni ilu Ibadan kii ṣe ilu ti a le fi ọwọ rọ sẹyin nilẹ Yoruba, o jẹ ilu kan ti awọn alagabara wa. Awọn Ooni kan ti gbe niluu naa ri, eyii to fi ilu ọhun sipo ti a ko le fi ọwọ rọ sẹyin ninu aṣa ati ohun ẹmi."

Lẹyin naa lo ke si awọn ọba ilẹ Yoruba pe ki wọn yago fun ẹtanu ati ija emi ni mo ju ọ lọ laarin ara wọn.

O ni "Ti a ba kọ lati wa ni irẹpọ, a maa ja awọn aṣaaju atawọn eeyan wa kulẹ."

Ooni tun fi akoko naa rọ Olubadan lati maṣe naani awọn ẹlẹgan, ko si gbajumọ iṣẹ rẹ nipo ti wọn yan an si.

Ki ni abẹwo Ooni si Olubadan n tumọ si?

Ọpọ araalu lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori ipade Ooni ati Olubadan yii, paapaa bi Ooni ṣe gbera lọ ilu Ibadan lati ki Olubadan.

Gẹgẹ bii ohun ti awọn onimọ nipa ọrọ to n lọ n sọ, eyii n tumọ si pe irẹpọ to ti wa laarin awọn lọbalọba nilẹ Yoruba tipẹtipẹ ko tii di ohun igbagbe.

Ipade ọhun tun n tumọ si pe ko si ikunsinu kankan laarin awọn Ọba mejeji ati pe bi ilẹ Yoruba yoo ṣe tẹsiwaju lo jẹ awọn mejeji logun.

Ti ẹ ko ba gbagbe, lẹnu ọjọ mẹta yii ni ija ta ni olori n jẹyọ laarin Ooni Ile Ife ati Aaalfin ilu Oyo, ti irufẹ nnkan bẹẹ tun n waye laarin Oluwo ti ilu Iwo ati Ayaoja ilu Osogbo.

Bo tilẹ jẹ pe Ooni ko mẹnuba ọrọ Alaafin lasiko ipade naa, Olubadan ti sọ ṣaaju pe ko si ija kankan laarin Ooni ati Alaafin, amọ awọn alatilẹyin awọn mejeji lo fẹ da ija agba silẹ laarin wọn.

Ooni kede Okanlomo Oodua

Ẹwẹ, Ooni ti kede pe inu oṣu Kejila, ọdun yii ni wọn yoo ja ewe oye le Oloye Jubril Dotun Sanusi lori gẹgẹ bii Okanlomo Oodua nilẹ Yoruba.

Ikede yii lo fopin si awuyewuye to wa nilẹ ṣaaju lori bi wọn ṣe kede Sanusi gẹgẹ bii ọmọ oye naa.

Ṣaaju ni Alaafin ilu Oyo, Ọba Akeem Abimbola Owoade, ti kọkọ bu ẹnu atẹ lu Ooni fun igbesẹ rẹ lati kede ọmọ oye naa.

O ni ko tọ si Ooni lati fi eeyan jẹ oye gbogbo ilẹ Yoruba.