Àwọn alákatakítí ẹ̀sìn pa èèyàn 22 níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìrìbọmi

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Awọn agbebọn ti yinbọn pa eeyan mejilelogun lati ori alupupou lagbegbe iwọ oorun orilẹede Niger.
A gbọ pe pupọ ninu awọn eeyan ti wọn pa lo n kopa nibi eto iribọmi kan ki iṣẹlẹ ọhun to waye.
Ẹnikan to n gbe agbegbe naa sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe eeyan marundinlogun lo ku nibi iribọmi naa to waye lagbegbe Tillabéri to wa laarin orilẹede Mali ati Burkina Faso ki wọn to lọ gbẹmi eeyan meje mii nibomii.
Ajafẹtọọ ọmọniyan kan nibẹ, Maikoul Zodi, sọ loju opo ayelujra rẹ pe "Akoko ti awọn eeyan ọhun n ṣajọyọ iribọmi wọn lọwọ lawọn agbebọn naa ṣina ibọn bolẹ."
Fun ọpọ ọdun ni ijọba Niger ti n gbiyanjiu lati pa ina awọn alakatakiti ẹsin Islam to n ṣiṣẹ pọ pẹlu ẹgbẹ agbesunmọmi al-Qaeda ati Islamic State.
Gẹgẹ bii AFP ṣe jabọ, ileeṣẹ iroyin abẹle Elmaestro TV jabọ pe "ipakupa" ni wọn pa awọn eeyan naa.
Ijọba Niger ti fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni ikọlu waye nibẹ amọ ko mẹnuba iye eeyan ba iṣẹlẹ naa lọ ni pato.
Lọsẹ to kọja ni ajọ ajafẹtọ, Human Rights Watch sọ pe awọn alakatakiti ẹsin ti bẹrẹ akọlu lakọtun si agbegbe naa, koda wọn ti pa eeyan bii 127, to fi mọ awọn Musulumi pẹlu.
Bẹẹ naa lawọn alakakiti naa sun ọpọ ile ti wọn tun ja ọpọ ṣọọbu lati ji ẹru ko lọ ni ẹ.
Lẹyin naa ni wọn di ẹbi awọn ikọlu naa ru ijọba to kuna lati ṣe ohun to yẹ lati dena awọn ikọlu ọhun ko to waye ati lati tẹti si ike awọn araalu to n bere aabo lọwọ rẹ.
Lọjọru to kọja, awọn alakatakiti naa ṣekupa ọmọ ogun Naijiria mẹrinla lagbegbe Tillabéri.
Ileeṣẹ ọmọ ogun sọ pe awọn gbọ pe awọn kan ji maalu gbe amọ nigba ti wọn yoo fi de agbegbe naa, niṣe ni awọn alakatakiti ọhun dena de wọn ti wọn si gbẹmi wọn nibẹ.
Ẹwẹ, o ṣoro lati mọ iye eeyan to n ku ni patọ latari bo ṣe ṣoro lati rekọja sibẹ ati ibẹru pe awọn alakakiti ọhun le maa pada wa fun ikọlu lakọtun.















