Wo àwọn àǹfààní ti atalẹ̀ ń ṣe fún ara

Àwòrán atalẹ̀ àti ife omi kan tí omi atalẹ̀ wà nínú rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Francesco Carta/Getty Images

    • Author, Abubakar Maccido
    • Role, Reporter
    • Reporting from, Kano
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Yálà kó jẹ́ láti fi se oúnjẹ, ṣe àgbo tàbí ṣe tíì gbígbóná nígbà tí ara èèyàn kò bá mú okun dáadáa, atalẹ̀ jẹ́ èso tí àwọn èèyàn mọ̀ dáadáa fún iṣẹ́ rẹ̀.

Láti ọjọ́ pípẹ́ ni àwọn èèyàn ti ń lo atalẹ̀ káàkiri àgbáyé.

Nígbà tó ń bá BBC News Pidgin sọ̀rọ̀, onímọ̀ nípa oúnjẹ kan ní ìpínlẹ̀ Kano, Sa'adutu Sulaiman sọ pé atalẹ̀ kìí ṣe èso tàbí egbògi kan tó dùn àmọ́ ó ní àwọn èròjà aṣaralóore tó pọ̀ tí àwọn olóyìnbó ń pè ní "bioactive compounds".

Ó ṣàlàyé pé èròjà kan tí wọ́n ń pè ní "gingerol" tó wà nínú atalẹ̀ tútù àti "shogal" tó wọ́pọ̀ nínú atalẹ̀ gbígbẹ jẹ́ àwọn ohun tó máa ń ṣe ara lóore gidi lára atalẹ̀.

Sulaiman tún fi kun pé ìwádìí tún fi hàn pé bí obìnrin bá ń mú ìlàjọ ṣíbí atalẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹta lójúmọ́ nígbà tí nǹkan oṣù rẹ̀ bá ku ọjọ́ kan, ó ní yóò jẹ́ kí nǹkan oṣù náà wá bó ṣe yẹ láì ní jẹ́ kí nǹkan oṣù pọ̀ púpọ̀ jù.

Àwọn àǹfààní atalẹ̀ fún ara

Gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ nípa oúnjẹ náà ṣe sọ, àwọn wọ̀nyí ni àǹfààní tí atalẹ̀ máa ń ṣe fún ara:

  • Kìí jẹ́ kí èèyàn ṣe àìsàn tó sì máa ń mú ara jí pípé: Atalẹ̀ máa ń mú kí ẹ̀yà ara èèyàn jí pípé dáadáa. Èyí túmọ̀ sí pé ẹni tó bá máa ń jẹ atalẹ̀ dáadáa, ara rẹ̀ yóò máa bá àwọn àìsàn wó ìyá ìjà pàápàá nígbà tí èèyàn bá fẹ́ ní ọ̀fìnkìn.
  • Ó máa ń dá èébì àti ọkàn rínrìn dúró: Nígbà tó bá ń ṣeni bí ọkàn rínrìn tàbí tí èébì fẹ́ máa gbé èèyàn, atalẹ̀ dára láti ṣe ìdádúró èyí. Fún àwọn aláboyún tó máa ń rẹ̀ ní òwúrọ̀, mímu ìlàjì ṣíbí atalẹ̀ le ṣe ìdádúró èébì tó máa ń gbé wọn, tó sì tún da fún àwọn tó bá ṣiṣẹ́ abẹ tàbí àwọn tó bá ń lo oògùn tó lágbára.
  • Ó máa ń dẹ́kun ìrora: Atalẹ̀ dára púpọ̀ láti dènà ara rírò, tó sì dára ju ọ̀pọ̀lọpọ̀ oògùn ara rírò lọ.
  • Láti dènà ẹ̀fọ́rí: Egbògi tó lágbára láti dènà ẹ̀fọ́rí ni atalẹ̀ jẹ́. Mímu ìlàjọ ṣíbí atalẹ̀ máa ń ṣiṣẹ́ láti lé ẹ̀fọ́rí lọ tí kò sí ní máa fa òyì ojú tàbí àyà títa.
  • Ó dára láti dènà ìnira nǹkan oṣù: Atalẹ̀ máa ń ṣiṣẹ́ bíi oògùn òyìnbó "ibuprofen" láti dènà ìrora nígbà tí èèyàn bá ń ṣe nǹkan oṣù. Èèyàn le mu ìlata sí ẹ̀kún ṣíbí kan ní ojoojúmọ́ lásìkò nǹkan oṣù.
  • Ó máa ń dín ẹ̀jẹ̀ nǹkan oṣù kù: Tí ẹ̀jẹ̀ bá máa ń pọ̀ lásìkò nǹkan oṣù, atalẹ̀ le ṣe ìrànwọ́ fún èyí. Ìwádìí fi hàn pé tí èèyàn bá máa ń mu ìlàjọ ṣíbí atalẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹta lójúmọ́, nígbà tó bá ku ọjọ́ kan tí nǹkan oṣù máa bẹ̀rẹ̀, ó le ṣe àdínkù ẹ̀jẹ̀ náà.
  • Ó dára fún ìtọ́jú oríkèéríkèé ara: Tí oríkèéríkèé bá máa ń dun èèyàn, atalẹ̀ le mú àdínkù bá ìrora bẹ́ẹ̀. Ó máa ń ṣiṣẹ́ "ibuprofen" tí kò sì ní da inú èèyàn rú kódà ó tún máa ń ṣiṣẹ́ ààbò fún inú ni. Ohun tí èèyàn nílò ni láti máa mú ìlàjì ṣíbí atalẹ̀ ní ojoojúmọ́.

Àwọn èròjà aṣaralóore tó wà nínú atalẹ̀

Atalẹ̀ tútù tó bá tó ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún gíráàmù (100g) ní àwọn èròjà yìí:

  • 80 Kcal (calories)
  • Carbohydrate: 17.77g
  • Fiber: 2.0g
  • Protein: 1.82g
  • Fat: 0.75g
  • Iron: 0.60mg
  • Folate: 11µg
  • Cholesterol: 0mg
  • Saturated Fat: 0.203g
  • Monounsaturated Fat: 0.154g
  • Polyunsaturated Fat: 0.206g