Barcelona vs Osasuna: Real Madrid gbadé ògo La Liga, Messi ní Barcelona ò lè ta pútú mọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nibi ti ẹlẹkun ti n sunkun lalayọ ti n yọ. Bayii lọrọ ri pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid ati Barcelona.
Bi idunnu ti ṣubu layọ fun Madrid lẹyin ti wọn fagba han Villareal eyi to mu wọn gba ife ẹyẹ La Liga fun igba kẹrinlelọgbọn, nnkan ko ṣẹnu ire fun Barca ni ti wọn.
Ẹgbẹ agbabọọlu Osasuna to bawọn lalejo lo dẹru iya le wọn lori eleyi lo mu Lionel Messi koro oju ti o si fi ibinu sọrọ.
Messi ti juwe ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona gẹgẹ bi ikọ ti ko lagbara lẹyin ti ikọ Osasuna gbo ewuro si wọn loju pẹlu ami ayo meji si ọkan ni Nou Camp.
Ibanujẹ dori agba Messi kodo lẹyin ti ijakulẹ Barcelona pẹlu Osasuna gba ife ẹyẹ La Liga mọ Barcelona lọwọ lalẹ Ọjọbọ.
Ajẹkun iya ti Barcelona jẹ lọwọ Osasuna yii n tumọ si pe ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid ni yoo gba ife ẹyẹ naa lai wo ohun ti ifẹsẹwọnsẹ rẹ pẹlu Villarreal yoo ba jade.
Nigba to n ba ileeṣẹ iroyin Spanish TV sọrọ lẹyin ifẹṣwọnsẹ ọhun, Messi sọ pe "Esi ti a ri kọ la lero pe a o ri, ẹgbẹ agbabọọlu wa ko lagbara to."
O tẹsiwaju pe "Awa gangan ni wọn n pe ni Barcelona, o si yẹ ki a maa bori ninu gbogbo ifẹsẹwọnsẹ wa ni, ṣugbọn bẹẹ kọ lọrọ ri bayii."

Oríṣun àwòrán, Getty Images
José Arnaiz Diaz lo kọkọ sọ bọọlu sinu awọn Barcelona lẹyin iṣeju marundinlogun ti ifẹsẹwọnsẹ naa bẹrẹ, ṣugbọn Messi da pada ni abala keji ifẹsẹwọnsẹ ọhun.
Laarin iṣẹju diẹ ti ifẹsẹwọnsẹ naa yoo pari ni Roberto Torres tun ri ẹyin awọn Barcelona nigba kan sii, eyi to mu ki goolu Osasuna di meji.
Oṣu Kẹfa ọdun 2020 ni idije La Liga gberasọ pada lẹyin ti wọn ti kọkọ da a duro nitori ajakalẹ arun Covid-19.













