Sheffield vs Chelsea: Ayé le! Sheffield faṣọ iyì ya mọ́ Chelsea lára lọ́nà ìrìnàjò sí Champions League

Awọn agbabọọlu Chelsea ati Sheffield

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aye ma le o, ẹgbẹ agbabọọlu Sheffield United fi oju Chelsea ri mọ bo lọjọ Satide ninu idije Premier League.

Afi bi awada bi ere ni ifẹsẹwọnsẹ naa bẹrẹ ti Sheffield ba gbayo akọkọ wọle Chelsea.

Kẹrẹkẹrẹ ti ere bọọlu naa n tẹsiwaju ni Sheffield ba tun fọba lee lẹyin ti wọn gbayo ẹlẹẹkeji sawọn.

Aṣe ẹgbẹ agbabọọlu Sheffield n ṣẹṣẹ mu ẹyẹ bọ lapo ni, ni wọn ba tun gbayo kẹta sinu awọn Chelsea.

Koda ohun ti a n wi yii kọ ni a o ba maa wi to ba jẹ pe ayo kẹrin ti Sheffield fẹ gba sawọn wọle Chelsea ni.

Sheffield ti wa ni ipo kẹfa lori tabili idije Premier League bayii, nigba ti Chelsea si wa ni ipo kẹta.