Ìwọ̀nyí ni àwọn ìpínlẹ̀ márùn ún tí ètò ààbò ti burú jùlọ ní Naijiria lọ́dún 2025

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oniruru iṣoro lo dojukọ Naijiria amọ eto aabo to mẹhẹ jẹ olori wọn.
Lara awọn eto abo to mẹhẹ naa ni ikọlu lemọlemọ awọn agbesunmọmi, ijinigbe , ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Lakọkọ, iha ariwa Naijiria lawọn iṣẹlẹ naa ti gbọngbọn julọ, amọ lonii, o fẹ ẹ dabi pe ko si agbegbe ti eto abo ti ṣẹnu ire ni Naijiria.
Ileeṣẹ Beacon Security and Intelligence Limited ti wọn jẹ onimọ nipa eto aabo sọ pe eto aabo Naijiria dara lọdun 2025 ju ọdun 2024 lọ.
Iwọyin ni awọn akọjọpọ ipinlẹ marun un ti eto aabo rẹ mẹhẹ julọ ati ipinlẹ ti wọn ti gbẹmi eeyan julọ ni Naijiria lọdun 2025.
Zamfara
O ti pẹ ti to aabo ti mẹhe nipinlẹ Zamfara, ipinlẹ naa lo tun leke tente ninu awọn ipinlẹ ti eto aabo rẹ buru julọ lọdun 2025.
Atẹjade lati Beacon Security fi han eeyan 2499 ni wọn ji gbe ti wọn si gbẹmi eeyan 1534 nipinlẹ naa lọdun to kọja.
Ipinlẹ Zamfara ni Bello Turji to jẹ ogbontatigi agbesunmọmi ti ijọba apapọ n wa lati ọjọ pipẹ fi ṣe ibuba.
Katsina
Iwadii ileeṣẹ eto aabo naa fi han pe ipinlẹ Katsina, to fẹgbẹkẹgbẹ Zamfara ni ipinlẹ to rọrun fun agbesunmọmi lati wọ julọ ni 2025.
Iwadii wọnfi han pe eeyan 911 ni wọn pa nibẹ ti wọn si ji 1,468 lọ lọdun 2025.
Ti a ba n sọ nipa ipinlẹ ti wọn ti n ji eeyan gbe fun owo itusilẹ, ipinlẹ Katsina jẹ ọkan gboogi ni Naijiria.
Lọdun to kọja, awọn ijọba ibilẹ kan nibẹ tilẹ dunadura pẹlu awọn ajinigbe ti wọn si n san owo ori fun wọn nibẹ lati dena ikọlu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Niger
Ipinlẹ kẹta ti eto abo rẹ buru julọ ni Niger gẹgẹ bii Beacon Security ṣe fi lede.
1,400 eeyan ni wọn pa nibẹ lọdun 2025 nigba ti wọn ji 833 gbe lọ gẹgẹ bii Beacon Security ṣe sọ.
Ipinlẹ Niger ni wọn ti ji eeyan to pọ ju gbe lọ lẹẹkan ṣosọ ni Naijiria lọdun to kọja lẹyin ti agbesunmọmi ji akẹkọọ to le ni 300 lọ nile ẹkọ St. Mary's to wa ni Papiri.
Borno

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aapapọ eeyan 669 ni wọn ji gbe lọ ti wọn si pa eeyan 1601 ni Borno ni 2025.
Ipinlẹ naa ni wọn ti gbẹmi eeyan julọ ni Naijiria lọdun 2025.
Ipinlẹ ọhun lo jẹ olu ibuba fun ẹgbẹ agbesunmi Boko Haram ati ISWAP ni Naijiria.
Lara awọn ẹmi eeyan to ṣe pataki to sọnu nibẹ ni ti ọgagun MA Uba ti awọn agbesunmọmi pa ti wọn tun gbe fidio iku rẹ sita lẹyin ti ileeṣẹ ọmọ ogun sọ pe ọkunrin naa ko si lakata ajinigbe.
Sokoto
Ipinlẹ Sokoto to fẹgbẹ kẹgbẹ Katsina ati Zamfara naa ko gbẹyin ninu awọn ipinlẹ ti eto abo rẹ mẹhẹ julọ ni 2025.
Eeyan 433 ni wọn gbẹmi wọn nigba ti agbebọn ji eeyan 707 gbe nibẹ lọdun 2025 nikan ṣoṣo.
Ipinlẹ Sokoto ni ẹgbẹ agbesunmọmi Lakurawa ti jade ti wọn si n ṣe awọn eeyan ipinlẹ ọhun bii ọṣẹ ṣe n ṣe oju.
Yatọ si Lakurawa, Bello Turji to jẹ ogbontarigi agbesunmọmi naa tun maa n de wọn lalejo nibẹ fun ikọlu lemọlemọ.
Ẹwẹ, lara awọn ipinlẹ mii ti eto wọn tun mẹhẹ ni Kano, Kebbi, Kogi ati Kwara wa.















