Tinubu, Obasanjo, Sanwo-Olu àtàwọn mí-ìn ń ṣèdárò Ọba Akran tó wàjà ní Badagry

Oba Babatunde Akran, Wheno Aholu Menu-Toyi I.

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Oba Babatunde Akran, Wheno Aholu Menu-Toyi I.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Latigba ti iroyin ipapoda Ọba Babatunde Akran, Wheno Aholu Menu-Toyi I, ti ilu Badagry nipinlẹ Eko ti gbode ni awọn eeyan ti n ranṣẹ ibanikẹdun si aafin ọba naa.

Lara awọn eeyan nla to ti ba wọn kẹdun ipapoda naa ni Aarẹ Bola Tinubu, Oloye Olusegun Obasanjo, Gomina Babajide Sanwo-Olu ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ana ode yii ti i ṣe ọjọ Aje ni iroyin ipapoda àgbà ọba fun gbogbo Badagry naa gbode. Ẹni ọdun mọkandinlaadọrun-un (89) ni Kabiyesi naa ki ọlọjọ too de.

Ibaṣepọ to wuyi lo wa laaarin Ọba Akran ati awọn oloṣelu lati ọdun pipẹ, oun si ni Igbakeji alaga igbimọ awọn lọbalọba ipinlẹ Eko titi di igba ti ọlọjọ de yii.

Diẹ lara awọn oloṣelu ati awọn eeyan nla to ti ranṣẹ ibanikẹdun si mọlẹbi ọba ati ilu Badagry pẹlu gbogbo Eko lapapọ ni.

Aarẹ Bola Tinubu:

Ninu iṣẹ ibanikẹdun ti Aarẹ Tinubu fi sita latọwọ Bayo Onanuga ti i ṣe Oludamọran pataki nipa iroyin fun un lo ti ni Ọba Wheno Aholu Menu-Toyi I fi han pe aṣiwaju to ṣee tẹle ni oun jẹ, ni gbogbo asiko to fi wa lori itẹ, eyi to din diẹ ni aadọta ọdun.

Aarẹ sọ pe ọba to fi ọgbọn dari ni, ti ko si jẹ ki abawọn de ba aṣa, bi ọlaju ṣe ti pọ to.

O ni oun mọ riri iṣakoso ọba to ti figba kan ṣe iṣẹ olukọ, to tun ṣiṣẹ akọroyin naa, to si pada depo ọba.

Oloye Olusegun Obasanjo

Ninu iṣẹ ibanikẹdun ti aarẹ tẹlẹ, Oloye Olusegun Obasanjo fi ranṣẹ lori ipapoda Ọba Akran Babatunde lo ti ṣapejuwe ọba naa bii "Aposteli to ṣe deede laaarin ẹlẹyamẹya, to si tun mu igbọra ẹni ye waye."

Obasanjo sọ pe iku ọba naa ya oun lẹnu pupọ.

O ni ọkan lara awọn ọba ti awọn eeyan bọwọ fun daadaa nipinlẹ Eko ni .

Ninu atẹjade ti Oloye Obasanjo fi sita lati ọwọ Akọwe iroyin ẹ, Kehinde Akinyemi, lo ti ni awọn eeyan yoo maa ranti Ọba Akran bii ẹnikan to tọju nnkan iṣẹmbaye awọn baba nla wa.

Obasanjọ sọ pe Ọba Akran duro fun alaafia, iṣọkan ati igbọra ẹni ye laarin awon eeyan Badagry nilẹ yii ati loke okun.

Gomina Sanwo-Olu

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Atẹjade ti Gomina Babajide Sanwo-Olu fi kẹdun iku Ọba Akran, ṣapejuwe ipapoda yii bii òfò nla fun ipinlẹ Eko ati Naijiria lapapọ.

Sanwo- Olu sọ pe ọba to wa nipo fun bii ọdun mọkandinlaadọta naa kun fun ọgbọn.

O ni o da aabo to peye bo aṣa ati iṣẹdalẹ, o si fẹran idagbasoke ilu Badagry gan-an.

"Lorukọ iyawo mi, ijọba ati awọn eeyan Eko, mo ba awọn eeyan Badagry, ẹbi ati awọn alajọṣe Ọba Babatunde Akran, Wheno Aholu Menu-Toyi I, kẹdun.

"Adanu nla ni iku Oba Akran fun ilu Iṣẹmbaye ti I ṣe Badagry, a si maa ṣe afẹri rẹ gan-an."

Sanwo-Olu lo sọ bẹẹ.

Gomina Sanwo-Olu sọ pe awọn eeyan Badadgry ni wọn yoo mọ bi iku ọba pataki naa ṣe ri lara gan-an, o ni ṣugbọn oun fẹ ki wọn mọ pe gbogbo eeyan Naijiria naa lo kan, bo ṣe kan oun gan-an alara.

Ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kẹfa ọdun 1936 ni wọn bi Ọba Babatunde Akran ni Badagry, ẹni ọdun mọkandinlaadọrun-un ni lasiko ti ọlọjọ de.

Ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹrin ọdun 1977 lo gun ori itẹ baba rẹ, to si ṣiṣẹ ilu pẹlu ilana ti awọn eeyan fi fẹran rẹ.