Orúkọ ọkọ mi ló wà níbi gbogbo dúkìá tí a ní, àmọ́ mi ò ri rò-Kemi Fajana,ìyàwó tó bá ọkọ rẹ̀ da òwò pọ̀

Oríṣun àwòrán, Kemi Fajana/ Instagram
Kinni yii, temi ni, o yatọ si kinni yii, ti gbogbo wa ni. Eyi ni igbagbọ ọpọ eeyan, paapaa to ba di ọrọ dukia, ṣugbọn ko ri bẹẹ fun obinrin oniṣowo kan, Kemi Fajana, ti oun ati ọkọ rẹ jọ da owo pọ, ti ileeṣẹ wọn si ti gbooro gidi.
Ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu BBC ni Kemi Fajana ti ṣalaye, pe bi dukia ti oun ati ọkọ oun ti ni ṣe pọ to, ko si ọkan ṣoṣo ninu rẹ to ni orukọ oun ninu, bi ko ṣe orukọ ọkọ oun.
Koda, ẹni to jẹ oluṣiro owo agba oun paapaa, aburo ọkọ oun ni.
Obinrin naa sọ pe ṣugbọn oun ko fi ọjọ kan ro o ri pe boya ọkọ oun le fẹ iyawo miran, tabi ṣe ohunkohun to le fa ki oun kabamọ pe awọn jọ n ṣiṣẹ pọ.
Abilekọ Fajana fi kun un pe ọkọ oun jẹ akinkanju nigba ti oun fẹ ẹ, yara kan ṣoṣo lo n gbe, o si n ta simẹnti ti ko ju aadọta apo lọ. Awin lo n gba simẹnti naa paapaa.
Bi ọkọ ba ta simẹnti lọwọ aarọ bo ṣe wi, to ba di irọlẹ, yoo fi ọkada ṣiṣẹ kiri ki idile rẹ ṣaa le mọwọ lọ sẹnu, bẹẹ lo ni awọn ṣe rọju titi ti oun si bimọ ẹlẹẹkeji si inu yara kan ṣoṣo naa.
''Mo bẹrẹ si i foju si ọja ọkọ mi lati ran an lọwọ nipa owo ti ki i pé nigba miran, bó ṣe di ohun ti a jọ n ṣe niyẹn''

Ni itẹsiwaju alaye rẹ, Abilekọ Fajana sọ pe akinkanju ti ọkọ oun jẹ wu oun lori pupọ, o si jẹ idi kan toun fi fẹ ẹ.
O ni ṣugbọn nigba mi-in, o maa n sọ pe owo ọja ko pe, eyi to mu oun maa fi oju si i.
''Emi naa n kiri ọja, amọ mo bẹrẹ si i foju si ọja ọkọ mi lati dẹkun ai pe owo, iyẹn jẹ ko maa ri aaye lati tun ṣe ọkada lọ kiri pápá, o si n polowo fun awon eeyan pe oun n ta simẹnti ati irin.
Bi ọja yẹn ṣe bẹrẹ si i gbooro si i niyẹn.
"A lowo lati ra mọto, a ko ra a, a n fi owo ṣiṣẹ lọ."
Obinrin yii sọ pe nigba ti oun yoo fi bimọ kẹta, awọn ti tuwo jọ kọ ile.
Amọ bi gbogbo dukia naa ṣe pọ to, ko si eyi ti orukọ oun wa ninu rẹ.
Ìyá mi gbọ́rọ̀ sí baba mi lẹnu ni emi naa ṣe ni itẹlọrun pẹlu ọkọ mi
"Gbogbo ohun ti a ni pata, orukọ ọkọ mi ni , ẹ ko le ri ọkan ti Kemi Fajana wa nibẹ sugbọn mi o tiẹ ri i ro pe boya o le fẹ iyawo mi-in tabi ohun to jọ ọ.
"Ko sohun to fa eyi ju pe ipilẹ mi, awọn iya mi, wọn gbọrọ si ọkọ lẹnu wọn si fi ọkọ emi naa.''
Abilekọ Fajana ni gbogbo eeyan kọ ni ilana aṣepọ iṣẹ yii ṣiṣẹ fun ṣaa o, o ni oun ti gbiyanju lati mu lọkọ-laya bii mẹjọ pọ lati da òwò pọ, ṣugbọn ko si eyi to bọ si i ninu gbogbo ẹ.
O ni bi ẹnikan ba mọ owo i na, ti ẹnikeji jẹ ẹni ti ko ri bẹẹ, o le ma ṣee ṣe fun wọn.
Koko ohun to ni yoo jẹ ki ajọṣepọ bii eyi gunrege ni pe ki tọkọtaya jẹ akinkanju, ki iyawo naa ri ara rẹ bii ẹni to gbọdọ le da duro lai duro de ọkọ.
O fi kun un pe ki awọn obinrin fi ọwọ sowọpọ pẹlu ọkọ wọn ṣe pataki gan-an.





