Gbas-gbos ní ìpínlẹ̀ Rivers àti àtunbọ̀tán òṣèlú bàbá ìsàlẹ̀ nínú òṣèlú Nàìjíríà

Wikw/Ladoja/Kwankwaso/Fubara

Oríṣun àwòrán, Wikw/Ladoja/Kwankwaso/Fubara

Ẹnu ọjọ mẹta yii ni ija to n waye laarin minisita fun ọrọ FCT, Nyesom Wike, ati gomina ipinlẹ Rivers, Siminalayi Fubara bẹrẹ si n nipọn si, eyii to fẹ ẹ da omi alaafia ipinlẹ naa ru.

Lati nnkan bii oṣu Kẹwaa, ọdun 2023 ni ija naa ti bẹrẹ amọ o tunbọ lagbara siwaju si lẹyin ti Aarẹ Bola Tinubu gbiyanu lati yanju rẹ.

Eyii ko ṣẹyin bi ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa ṣe kede pe aye awọn aṣofin to n tẹle Wike ti ṣofo lẹyin ti wọn darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Ṣaaju ni awọn aṣofin naa ti kọkọ ṣe afikun oloṣumẹfa si akoko to yẹ ki awọn alaga ibilẹ ipinlẹ ọhun lo lori oye amọ ijọba ipinlẹ ọhun lọ sile ẹjọ lati wọgile afikun naa.

Ọpọ eeyan ipinlẹ naa lo gbagbọ pe awọn aṣofin ipinlẹ ọhun ko si lẹyin gomina Fubara nitori bi wọn ṣe n ṣatilẹyin fun Wike.

Lẹyinorẹyin, ọrọ naa di iṣu ata yan an yan an, to si fẹ ẹ doju eto abo ipilẹ ọhun bole.

Amọ ṣa, kii ṣe igba akọkọ ree ti rogbodiyan yoo bẹ silẹ laarin ilu latari ija to n waye laarin gomina ati baba isalẹ wọn ninu oṣelu.

Wo awọn ipinlẹ ti ija ti waye laarin gomina ati baba isalẹ rẹ, eyii to da rogbodiyan silẹ laarin ilu.

Ladoja ati Adedibu – Ipinlẹ Oyo

Rashidi ladoja ni gomina ipinlẹ Oyo lati ọdun 2003 si ọdun 2007, gbogbo ilu lo si mọ oloye Lamidi Adedibu gẹgẹ bii baba isalẹ rẹ.

Amọ wahala bẹ silẹ laarin awọn mejeji lẹyin ti ariyanjiyan kan waye lori ọrọ owo.

Gẹgẹ bii ohun ti Adedibu funra rẹ sọ ninu irọfọwerọ kan, o ni kete ti Ladoja di gomina tan ni iwa rẹ yipada si oun.

Ṣaaju ni Adedibu ti kọ bere fun N15m gẹgẹ bii owo ajẹmọnu oun ninu N65m ti ijọba apapọ n fi ṣọwọ si Ladoja loṣoṣu gẹhgẹ bii owo eto abo ṣugbọn Ladoja kọ jalẹ.

Adedibu lo ipo rẹ lati jẹ ki awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin lọdun naa lọhun yọ Ladoja nipo bii jiga, ti ọrọ naa si da igboro ru.

Adekunle Ajasin ati Akin Omoboriowo – Ipinlẹ Ondo

Ni nnkan bii ogoji ọdun sẹyin ni oloye Adekunle Ajasin ati igbakeji rẹ Akin Omoboriowo dije du ipo gomina lọtọtọ ninu ẹgbẹ oṣelu UPN and NPN.

Ajasin ni gomina tẹlẹ, ti Omoboriowo si jẹ igbakeji rẹ, amọ awọn alatilẹyin Ajasin ri Omoboriowo bii ọdalẹ lẹyin ti oun naa gbe apoti ibo lati dije tako ọga rẹ ana.

Igbesẹ Omoboriowo naa lo waye latari ija kan to ṣẹlẹ laarin awọn mejeji lasiko ti wọn n ṣejọba ṣaaju.

Ẹwẹ, kii ṣe pe wọn yọ Omoboriowo nipo, bẹẹni ko kọwe fi ipo silẹ, niṣe lo kuro ninu ẹgbẹ oṣelu to gbe de ipo igabkeji gomina, UPN, to si lọ si NPN lati lọ dije tako ọga rẹ.

Amọ ṣa, ija wọn naa fa rogbodiyan ti ko ṣe fẹnusọ, ọpọ ẹmi sun, bẹẹ ni wọn dana sun ọpọ ile ati dukia.

Rabiu Kwankwaso ati Abdullahi Ganduje – Ipinlẹ Kano

Rabiu Kwankwaso ni gomina ipinlẹ Kano ṣaaju Abdullahi Ganduje amọ ija nla waye laarin wọn bo tilẹ jẹ pe wọn n ba ra wọn ṣe tẹlẹ gẹgẹ bii ọrẹ ati oloṣelu.

Ija naa tubọ buru si lẹyin ti Abba Yusuf di gomina lẹyin Ganduje, to bẹrẹ si bẹrẹ si n pa awọn nnkan ti Ganduje ti ṣe ṣaaju rẹ.

Lẹyinorẹyin, ija awọn oloṣelu mejeji naa fa iwọde nla niluu Kano.

Nyesom Wike ati Rotimi Amaechi – Rivers

Agbegbe Ikwere ni awọn oloṣẹlu memeji ti wa, wọn si ti jọ ṣiṣẹ pọ ki ija to waye laarin wọn.

Nigba ti Amaechi wa nipo gomina ipinlẹ Rivers, Wike ba ṣiṣẹ gẹgẹ bii olori awọn oṣiṣẹ rẹ ki wọn to fa Amechi kalẹ fun ipo minisita ninu ijọba Goodluck Jonathan.

Amọ ija bẹrẹ laarin awọn mejeji lẹyin ti Amaechi lọ sinu ẹgbẹ oṣelu APC lati ṣatilẹfin fun Muhammadu Buhari fun ipo Aarẹ lọdun 2015 ṣugbọn ti Wike, to n du ipo gomina lọdun naa lọhun ṣatilẹyin fun Goodluck Jonathan fun ipo Aarẹ kan naa.

Ninu idibo ọdun naa Wike ni jawe ti jawe olubori gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Rivers lẹyin to fidi aayo Amaechi, iyẹn Dakuku Pertersisde janlẹ.