Wo ọ̀rọ̀ tí gbajúmọ̀ 'alágbe' àti akọrin ẹ̀fẹ̀, Mukaila Ṣẹnwẹlẹ bá BBC sọ kó tó jáde láyé
Ti ẹda ba mọ iṣẹ aṣela ṣebi ko ni maa daamu, eyii lo difa fun ọgbẹni Mukaila Omotoso Ayinla ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si ‘Ṣẹnwẹlẹ Ayinla Ọmọ Ayeronfẹ.’
Eredi apẹle orukọ naa ko ṣẹyin bo ṣe n kọ orin Ṣẹnwẹlẹ.
Ninu alaye rẹ fun BBC Yoruba, o ni oun bẹrẹ iṣẹ Ṣẹnwẹlẹ gẹgẹ bii ẹfẹ lati ibi ipolowo ọja, titi toun fi mu iṣẹ naa lọkunkundun.
Orin Ṣẹnwẹlẹ jẹ orin kan to gbajumọ nipinlẹ Kwara, ti ọpọ awọn eeyan si maa n gbọ.
Bo tilẹ jẹ pe iṣẹ obinrin ni iṣẹ Ṣẹnwẹlẹ, ọgbẹni Mukaila sọ pe oun loun yan laayo ati pe o rọrun fun oun pupọ lati maa kọ.
Ni ti awọn ipenija to wa nidi iṣẹ naa, o ni ọpọ igba lawọn maa n lọ kọ orin lawọn adugbo ti awọn eeyan adugbo naa yoo si maa fi tipatipa gba owo ilẹ lọwọ awọn.
Nigba mii, o ni iye owo ti awọn eeyan naa maa n bere fun le ju iye owo ti awọn pa lọ, eyii to maa n yọri si rogbodiyan laarin awọn mejeji.
Lẹyin naa lo gba awọn obi lamọran lati gba awọn ọmọ wọn laaye lati ṣe iṣẹ ti ọkan wọn fẹ, ki wọn si maa gbadura fun wọn ni gbogbo igba.
Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ ohun ti Mukaila sọ.






