Gómìnà Seyi Makinde buwọ́lu ìyànsípò Olakunleyin gẹ́gẹ́ bíi Olubadan

Oríṣun àwòrán, Oyo Govt
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti buwọlu iyansipo Oba Akinloye Owolabi Olakunleyin gẹgẹ Olubadan ti ilẹ Ibadan.
Olakunleyin ni yoo jẹ Olubadan ẹkẹtalelogoji ninu ita ilẹ Ibadan
Gomina kede igbesẹ yii ninu ọrọ kan to fi lede eyi to ti buwọlu lati ọjọ kẹrinla oṣu kẹfa ọdun 2024, ni oun paṣẹ pẹlu ilana ti iwe ofin ipinlẹ Oyo ti ọdun 2000 gbe kalẹ.
Ninu atẹjade ti Kọmisọna fun ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ nipinlẹ Oyo, Olusegun Olayiwola fi lede fun awọn akọroyin, o ni igbesẹ yii waye ni ilana ti ofin ti seto nipa oye jijẹ nipinlẹ Oyo.
Ninu ayẹjade naa, Gomina Seyi Makinde ki Olubadan tuntun naa ku orire, to si gba ladura pe igba rẹ yoo san gbogbo araalu Ibadan.
Bẹẹ ba gbagbe, Oba Owolabi Olakunleyin ti sọ pe tabi ṣugbọn kan ko si, oun ni ipo Olubadan kan.
Lasiko ti ikọ alabẹwo lati ọdọ Gomina Ṣeyi Makinde lọ ki baba naa nile rẹ lagbegbe Alalubọsa, n’Ibadan lo sọ bẹe.
Alagba Ọlakulẹyin ni oun ti ṣetan lati gun ori itẹ, ati pe ọpẹ lo kan lọrọ oun.
Alagba Ọlakulẹyin to sọrọ pẹlu ohun to ja geere, si iyalẹnu ọpọ eeyan to wa nibẹ, sọ pe, “ Inu mi dun lati ri awọn ikọ alabẹwo lati ọdọ gomina.
‘’Nigba ti wọn sọ fun mi pe ẹ n bọ, ẹsẹkẹsẹ ni mo sọ fawọn oloye mi pe ki wọn maa bọ, ki wọn jẹ ka jọ gba yin lalejo.
‘’Inu mi dun pe awọn eeyan mi wa nibi pẹlu mi.
‘’Mo ti ṣetan patapata. Mo mọ pe Ọlọrun wa lẹyin mi. O ti sọ pe emi ni ipo Olubadan kan, emi naa si mọ lododo pe emi lo kan, asiko mi ree.’’
Ohun to yẹ ko mọ nipa Olubadan tuntun
Oba Owolabi Olakunleyin wa lati apa ariwa ila oorun ilu Ibadan, to si wa lati agboole Okugbaja ni agbegbe Ita Baale niluu Ibadan.
Ọpọlọpọ ọdun ni Olakunlẹyin fi ba Ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria siṣẹ ko to di pe o fẹyinti lẹnu iṣẹ.
Oba Olakunleyin yoo darapọ mọ awọn ori ade ti ọjọ n bẹ lori wọn, ẹni ọdun mẹrinlọgọrun ni Oba Olakunleyin bayii.
Lọdun 1992, Olakunleyin gbe apoti ibo fun igbimọ aṣofin kekere labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party, to si wọle lati soju ekun idibo rẹ.
Ará ìlú nìkan ló leè fi Olubadan sórí ìtẹ́, ojúṣe Gomina Makinde kọ́ - Rasheed Ladoja ṣàlàyé

Oríṣun àwòrán, Rasheed Ladoja
Ọtun Olubadan ti ilẹ Ibadan, Sẹnetọ Rasheed Ladoja ti salaye pe, Gomina kọ lo laṣẹ lati fi Olubadan tuntun sori itẹ.
Gbolohun yi jẹyọ lẹyin ti Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde sọ pe, oun ko ni ṣeto ifọbajẹ fun Ọba Owolabi Olakulehin ti wọn fa kalẹ lati jẹ Olubandan ti ilu Ibadan ayafi ti ipo ilera rẹ ba wa ni pipe.
Agba oye ilẹ Ibadan, Rasheed Ladọja sọrọ nibi pọpọṣinṣin ọdun Ileya to waye nilu Ibadan, pe ko si ootọ ninu iroyin to gbode pe oun lo wa nidi bi Gomina Makinde ko ṣe fẹ gbe igbesẹ fifi Olubadan tuntun jẹ.
Ladoja salaye wi pe, ọwọ awọn ara ilu ni ati fi Olubadan tuntun sori apere wa, igbesẹ naa ko si lọwọ Gomina Seyi Makinde rara.
"Ojuṣe Gomina ni lati gbe ọpa aṣẹ pẹlu awọn ohun elo miran ti Ọba naa yoo maa lo lori itẹ fun, toripe dukia ijọba ni awọn eroja naa jẹ."
Ladoja salaye wi pe, Oluwo tilu Ibadan nikan lo lagbara lati gbe ade le Olubadan tuntun lori, ti Gomina yoo si fun un ni ọpa aṣẹ ati awọn eroja yooku.
O tun tenumọ pe ibaṣepọ to gun rege lo wa laarin ohun ati Gomina Makinde ati wi pe Gomina ti ki oun ku ọdun Ileya pẹlu ẹbun to jọju.

Oríṣun àwòrán, Channels tv
Gomina ana ni ipinlẹ Ọyọ ọhun mẹnuba a wi pe latọdun 1983 ni Ọba Olakulehin ti n fi oju sọna fun ipo Olubadan, o ni ara Olubadan tuntun ọhun ya gaga ṣugbọn o ti dagba.
Rasheed Ladoja sọ pe, “nigba ti wọn beere lọwọ mi nipa ipo Olubadan lọdun 2023, mo fesi wi pe ade Olubadan ni mo fẹ, ṣugbọn nibi ọdun Ileya to kọja ni wọn ti beere kini ipo ilera Ọba Ọlakulehin, mo dahun pe dokita nikan lo lee ṣalaye”.
“Emi ni olori awọn afọbajẹ ilu ibadan lọwọ lọwọ, bẹẹ ni mo ti ṣe ipade pẹlu awọn ikọ mi lori ati jẹ Olubadan tuntun, bakan naa ni Gomina ti buwọlu ọrọ naa nipa titẹle awọn ilana to yẹ lori ọrọ naa.
Ladoja tọka sii pe, oun faramọọ ti Gomina Makinde ba sọ pe, o digba ti ilera ẹni ti wọn fa kalẹ fun ipo naa ba duro re, ki ọpa aṣe to dọwọ rẹ.
Awọn eeyan ilu nikan lo lagbara fifi Olubadan tuntun jẹ, ko si lọwọ ijọba rara.















