Gbàgede Alale rèé níbí tí Oyabiyi Ààrẹ Ọnakakanfo Kẹ́ta ilẹ̀ Yorùbá wọlẹ̀ sí

Àkọlé fídíò, Gbàgede Alale rèé níbí tí Oyabiyi Ààrẹ Ọnakakanfo Kẹ́ti ilẹ̀ Yorùbá wọlẹ̀ sí
Gbàgede Alale rèé níbí tí Oyabiyi Ààrẹ Ọnakakanfo Kẹ́ta ilẹ̀ Yorùbá wọlẹ̀ sí

Njẹ ẹyin ti gbọ nipa gbagede Alale nibi ti Oyabiyi, Aarẹ Ọnakakanfo Kẹta ilẹ Yoruba wọlẹ si ri?

BBC Yoruba ṣabẹwo si gbagede naa ti apa kan rẹ wa lori ilẹ orilẹede Naijiria,nigba ti apa keji si bọ si ori ilẹ orilẹede Benin Republic.

Olupitan Toluwalase Oguntosin sọ pe ‘’ibi ti gbagede yii wa ni wọn n pe ni ilu Farasinmi.

Ibi ni abawọle igbo Alalẹ ti a ti maa n bọ Ogun, nibi ti a ti maa sọ fun Ogun pe a n lọ, kaabọ laayọ ati alaafia.''

Ọgbẹni Oguntosin ṣalaye pe ‘’ laye atijọ, ẹnikẹni to ba n bọ wa si igbo Alalẹ yii ni lati jẹ ẹni ti o ni iṣoro ti o ni agbara pupọ.

Bakan naa, ẹgbọn ati aburo ko gbọdọ gba ọna kan naa ninu igbo Alalẹ, ọna ọtọtọtọ ni wọn gbọdọ gba.

Ko baa jẹ ọgunrun un ọdun, ko gbọdọ si koriko to maa hu ni gbagede Alalẹ.

Ile Irumọlẹ Odududuwa ni a kọ si gbagede Alalẹ yii.''

Oguntosin sọ pe ''nigba kugba ti a ba ti de gbagede Alalẹ ni a maa n ba odu Ifa nibẹ, ko si si ẹni ti o maa n mọ bi o ṣe de ibẹ.

Awọn to maa n wọle sibi ni lati jẹ ọba, tabi ijoye tabi ọlọla ilu, ita lawọn toku maa n duro si.

Ẹni to ba le fipa wọ ibi, ejo lo maa n le wọn nibi titi di oni yii.

Omi Alalẹ lo tun wa nibi, ẹnikẹni to ba n ṣe aisan ti wọn ba bu omi yii fun, ara rẹ maa ya.

Omi yii ko gbẹ ri lati bii ọdunrun un sẹyin.