Ṣé lóòtọ́ ni àwọn kan lára àwọn olùwọ́de EndSARS ṣì wà látìmọ́lé ọlọ́pàá?

Oríṣun àwòrán, getty images
Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti sọ pe ko si eyikeyii ninu awọn oluwọde EndSARS to waye logunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020 to ṣi wa ni atimọle rẹ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Olumuyiwa Adejobi lo sọ bẹẹ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin.
Adejobi lo sọrọ naa lati fesi fun sẹnetọ aringbungbun Kaduna tẹlẹ, Shehu Sani, to sọ pe awọn kan lara awọn oluwọde naa ṣi wa ni atimọle ọlọpaa.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọdun 2020 lawọn ọdọ yari mọ ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ ni Naijiria latari iṣekupani ati iwa ifiyajẹni ẹka rẹ to n gbogun ti idigunjale, SARS.
Amọ o ṣeni laanu pe ọpọ nnkan lo bajẹ lasiko iwọde naa, ti ọpọ ẹmi si sọnu, eyii to mu ki ọlọpaa fi ṣikun ofin mu awọn eeyan kan.
Bo tilẹ jẹ pe ọlọpaa fi awọn kan silẹ lẹyin ti wọn ti wọn mọle tan, wọn fi awọn kan silẹ ni ahamọ ni itẹsiwaju iwadii ti wọn n ṣe, gẹgẹ bii wọn ṣe sọ.
Wayi o, nibi wẹjẹwẹmu kan to waye niluu Abuja lọjọ kejila, oṣu Kẹfa ọdun 2024 yii, Shehu Sani sọ pe o yẹ ki wọn gboriyin fun awọn to kopa ninu iwọde EndSARS gẹgẹ bii awọn to jẹ ki ijọba awarawa duro dede ni Naijiria.
Sani rọ Aarẹ Bola Tinubu nibi apejẹ naa pe ko darijin awọn to ṣi wa ni ahamọ ọlọpaa latari iwọde ọhun.
Ṣugbọn ninu ọrọ rẹ, ọlọpaa ni ọrọ naa ti pari, araalu ati ọlọpaa si ti kọ awọn to yẹ ki wọn kọ nipa rẹ.
Adejobi ni “Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria fẹ fi da araalu loju pe ko si ẹnikẹni ni ahamọ ọlọpaa tabi ni ahamọ ileeṣẹ agbofinro mii lọna to lodi si ofin latari iwọde ENdSARS.
“A ti ṣe gbogbo ohun to yẹ ni ilana ofin pẹlu awọn ti a mu, ko si si ẹnikẹni ninu wọn to ṣi wa lahamọ lọna to lodi si ofin, niluu Eko, gomina Babajide Sanwo-Olu darijin afurasi ọgọrun ti ọlọpaa mu lasiko iwọde naa.
“Fun alaye ni kikun, ko si ẹnikẹni ni Naijiria to wa ni ahamọ ọlọpaa tabi to n jẹjọ lọna to lodi si ofin nitori pe wọn kopa ninu iwọde EndSARS... A ti darinjin ara wa, a si ti kuro lori ọrọ naa.”















