Ayẹyẹ Iléyá kò dùn nílé ọ̀pọ̀ Musulumi Naijiria lọ́dún yìí

Ileya

Oríṣun àwòrán, Ibrahim Balarabe Wambai

Bi ọgọọrọ awọn Musulin ṣe n ṣajọyọ pọpọṣinṣin ọdun Ileya kaakiri Naijiria, Mallam Kabiru Tudun, ẹni ọdun mejidinlọgọrin kan ti ni, ọdun naa ko dun lọdọ oun nitori iṣoro ọwọngogo to gbode.

Lọdọọdun ni awọn Musulumi kaakiri agbaye maa n pa ẹran agbo tabi ẹranko miran lati fi sajọyọ ọdun Ileya, leyi ti wọn n ṣe ni iranti bi Anọbi Ibrahim ṣe gbọran si aṣẹ Ọlọrun lati fi ọmọkunrin rẹ rubọ.

Ẹran naa ni wọn saba maa n fi ṣe ase nla fun gbogbo ẹbi, ọrẹ ati awọn ara adugbo to ba wa ki wọn fun ti ayẹyẹ ọdun ọhun, bakan naa ni awọn adari ẹlẹsin sọ pe o dara lati maa fun awọn to ba ku diẹ kaato fun lawujọ ni ẹran naa.

Ọgbẹni Wada sọ fun BBC nigboro ilu Kano to jẹ ilu to tobi julọ ni Ariwa Naijiria, ti ọpọ wọn si jẹ Musulumi pe, nnkan le diẹ lọdun yii, yatọ fun bo ti ri lọdun atẹyinwa nigba ti owo ẹran agbo rọju fun rira.

Wada tọka sii pe orilẹ ede Naijiria n koju ipenija eto ọrọ aje lọwọ lọwọ leyi to n ṣokunfa bi ilu ṣe le koko, o ni agbara ọpọlọpọ ni ko gbe owo ti wọn n ta agbo lọja nitori bi iye rẹ ti gbẹnusoke.

Ọmọ Naijiria miran, Mallam Auwal Yakasai ẹni ọdun mẹrindinlaadọrin ṣalaye wi pe, awọn meji lo dawo papọ lati ra ẹran agbo kan ṣoṣo lọdun yii.

O ṣalaye wi pe, ode le lasiko yii, bẹẹ nipasẹ ẹran pipa naa ni ọna kan gboogi ti ọpọ fi n ṣe saara.

Adari ẹlẹsin Islam kan, Idris Garba Sokoto sọ fun BBC pe, igbesẹ ẹran agbo, ewurẹ tabi rakunmi pipa lo jẹ ohun to wuyi julọ ti eeyan lee ṣe fun Ọlọrun lasiko ọdun.

Idris fidi ọrọ mulẹ pe aṣa ẹran pipa lo ti bẹrẹ ninu ẹsin Islam lati igba ti Anọbi Ibrahim ti gbe igbesẹ igbọran lati tẹle asẹ Ọlọrun nipa fifi ọmọ rẹ rubọ ṣugbọn ti wọn fi ẹran agbo rọpo fun.

Bakan naa ni Idris mẹnubaa pe ẹsin Islam faaye gba ki eeyan marun un tabi meje parapọ kowojọ ra ẹran maalu tabi rakunmi kan ki wọn si pin laarin ara wọn ti wọn ba pa tan.

Kini iyatọ to wa laarin ọdun mejeeji ti awọn Musulumi maa n ṣe?

Shamsu Mohammed ẹni ọdun mẹrinlelaadọta kan sọ pe ounjẹ lo ṣe koko fun ọpọ awọn Muslumi orilẹede Naijiria lasiko yi, tori pe ẹran rira ni awọn miran ka si apọju inawo.

O tọka sii pe, awọn ounjẹ ti ko fi bẹẹ wọn ni ohun yoo fi owo tẹnikẹni ba fun oun lati fi ra ẹran agbo kojọ sile, toripe pipa ẹran kii ṣe dandan fun ẹni ti ko ba lagbara rẹ.

Ibrahim Balarabe Wambai to n fi ẹran agbo tita ṣowo lasiko yoowu ti ọdun ba ti wọle, mẹnuba bi nnkan ti yatọ fun owo oun lọdun yi.

Wambai sọ pe “Ẹran agbo marundinlogun ni mo ta lọdun to kọja, Ṣugbọn meje pere ni mo ta, Ọja yatọ lọdun yi."

Ijọba orilẹede Naijiria sọ pe iṣẹ ti n lọ lọwọ lati mu ki nnkan duro deede lẹka eto ọrọ aje.

Adura awọn Musulumi ilẹ Naijiria bi wọn ti n pada sile lati mọṣalaṣi ni wi pe, ki igba ọtun wọle, ki ọsan si so didun fun wọn lọdun Ileya to n bọ lati pa ẹran, pẹlu rira aṣọ tuntun sọrun lasiko ọdun naa.