Àìsàǹ onígbá méjì tàn dé ìpínlẹ̀ ọgbọ̀n ní Naijiria

Cholera

Oríṣun àwòrán, getty images

Aisan onigbameji ti tan de ipinlẹ ọgbọn kaakiri Naijiria bayii ti igbagbọ si wa pe o ṣeeṣe ko tunbọ fẹju si lasiko pọpọṣinṣin ọdun yii.

Awọn onimọ isegun oyinbo tọka sii pe, bi ọpọ ero ti n rin irin ajo lati ibi kan si ikeji lasiko ọdun yi lee jẹ ko pọ si.

Eyi lo waye lẹyin igba ti ijọba ipinlẹ Eko fidi rẹ mulẹ pe, aisan onigba meji ti gbẹmi lẹnu eeyan marundinlogun ọtọọtọ lọdọ wọn.

Ni Naijiria, aisan onigba meji maa n burẹkẹ lọdọọdun nigba ti ojo ba ti n rọ.

Ni pataki julọ awọn agbegbe ti imọtoto ko ti duro re, eeyan si lee lugbadi aisan ọhun nigba to ba jẹ ounjẹ tabi mu omi ti kokoro aifojuri ba wa.

Ajọ to n mojuto ajakalẹ aarun ni Naijiria (NCDC) naa ti ṣekilọ fun awọn eeyan ilu nipa alekun to ti ba itankalẹ aisan naa pẹlu bi asiko ojo ṣe wọle de.

Ajọ ọhun fi kun pe oun funra pe iye eeyan to ni aisan naa ti to 1,200, bẹẹ ni wọn ti fidi rẹ mulẹ pe eeyan 65 nipe ti awọn bii ọgbọn ti jade laye.

Awọn ijọba 96 ni ipinlẹ bii Ọgbọn kaakiri Naijiria ni wọn ni awọn ti ri aisan ọhun laarin ọjọ kini, oṣu Kini si ọjọ kọkanla, oṣu Kẹfa, ọdun 2024.

Awọn ipinlẹ mẹwa to ni ida lọna aadọrun ninu akọsilẹ aisan naa ni, Bayelsa, Zamfara, Abia, Cross River, Bauchi, Delta, Katisina, Imo, Nasarawa ati Eko.

Ọna lati dẹkun itankalẹ aisan onigba meji

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lọdun 2022 ajọ eleto ilera lagbaye, WHO, ṣe akọsilẹ aisan onigba meji bii 473,000, leyi ti alekun ba lọdun 2023 si 700,000.

Dokita Dele Abdullahi tii ṣe Aarẹ ẹgbẹ awọn dokita ni Naijiria salaye pe itankalẹ aisan naa lee fẹju kẹkẹ si lasiko ti aaye isimi lẹnu iṣẹ wa ati pọpọṣinṣin ọdun to wa lode.

O ni ki awọn oṣiṣẹ eleto ilera maa wa ni oju lalakan fi n ṣori nigba yowu ti wọn ba kẹẹfin awọn apẹrẹ aisan naa, bii ki eeyan maa bi tabi ṣe igbonsẹ leralera.

Adullahi tọka si ṣiṣe imọtoto gẹgẹ bii ọna kan gboogi ti eeyan lee fi kapa itankalẹ aisan ọhun, bẹẹ lo ni ki awọn eeyan yago fun ṣiṣe itọju latọwọ ara wọn.

Oludari agba yanyan fun ajọ to n mojuto ajakalẹ aarun ni Naijiria, Jide Idris, ṣalaye pe o ṣe pataki lati dena aisan naa bi ọwọ ojo ṣe tubọ n dunlẹ sii, leyi to ṣeeṣe ko muu pọ si laarin ilu.

Ṣaaju ni ajọ to n ri si oju ọjọ ni Naijiria ti kọkọ fi lede pe, ọwọ ojo yoo rinlẹ lọdun 2024 pẹlu iṣẹlẹ omiyale, leyi to lee sokunfa alekun itankalẹ aisan onigba meji lawujọ.

Idris sọ pe, iṣoro aisi imọtoto to munadoko lori ounjẹ, omi ati ayika lo maa n fa itankalẹ aisan naa ni kia kia.

Bẹẹ lo tun tọka si igbeṣẹ ọwọ fifọ pẹlu ọṣẹ ati omi to mọ geere lẹyin ti eeyan ba ti lo ile igbonsẹ tabi se ounjẹ tan.

Nidi eyi, Aarẹ NCDC naa wa ke si ijọba ni gbogbo ipele lati pese omi to mọ fun lilo awọn eeyan lawujọ ki itankalẹ aisan onigba meji lee dinku.