Ṣé lóòótọ́ ni àdó olóró tí ológun Chad jù fún Boko Haram pa ọ̀pọ̀ apẹja ọmọ Naijiria?

Awon to wọsọ ologun, we ọja mọ ori. Awọn kan wa ninu ọkọ, ọkan jokoo le ori ọkọ, ẹnikan si duro niwaju ọkọ wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Ọpọ awọn ọmọ Naijiria ti wọn jẹ apẹja ni iroyin sọ pe wọn ti di oloogbe bayii lẹyin ti ado oloro ti ikọ ologun Chad ju fun awọn Boko Haram lagbegbe Lake Chad ba wọn.

Olori awon apẹja kan fidi eyi mulẹ.

Ikọlu yii n waye lẹyin ọjọ diẹ ti ikọ agbesunmọmi Boko Haram kọlu ileeṣẹ ologun Chad nigba meji.

Ikọlu Boko Haram naa ni iroyin ṣo pe o kere tan, o pa ṣọja ilẹ Chad mẹrinlelogun ati awọn ọga ologun meji.

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ Aarẹ ilẹ Chad fi sita lọjọ Aiku, ọjọ kẹwaa, oṣu Karun-un yii ni wọn ti kede pe:

Ileeṣẹ ologun ilẹ Chad ti kọlu ikọ Boko Haram lọna to lagbara, lagbegbe Lake Chad, lati da ikọlu ti wọn ṣe lọjọ kẹrin ati ikẹfa oṣu Karun-un pada fun wọn.

Bawo ni ado oloro ṣọja ṣe pa awọn apẹja ọmọ Naijiria?

Nigba to n ṣalaye ohun to ṣẹlẹ, Abubakar Gamandi Usman, Alaga ẹgbẹ awọn apẹja ọmọ Naijiria kan lagbegbe naa, sọ fun BBC pe ọpọ araalu ni ikọlu ọhun ba.

O ni eyi ri bẹẹ nitori niṣe ni awọn Boko Haram n ṣọṣẹ kiri awọn erekusu agbegbe Lake Chad.

"Lẹyin ti awon Boko Haram kọlu ologun Chad, wọn pada si awon erekusu ti wọn ti n huwa laabi wọn, awọn apẹja si n gbe lawọn erekusu yii kan naa."

Usman, Alaga awon apẹja naa lo sọ bẹẹ.

O ni o pẹ ti awọn eeṣin-o-kọku yii ti n daamu iṣẹ awọn apẹja nibẹ, paapaa ni Chad ti ikọlu ti waye yii.

"Boko Haram lo n dari irin awon apẹja si odo ti won ba ti fẹ pa ẹja, wọn maa n gbe won lati ọja ẹja lọ sodo ti wọn a ti pa ẹja mi-in ni.

"Boko Haram n gba owo ori lọwọ awọn apẹja."

Bẹẹ ni Usman ṣalaye.

Awọn Boko Haram sa lọ nigba ti ọkọ ofurufu ologun Chad de

Ni itẹsiwaju alaye naa, Usman sọ pe awọn agbesunmọmi naa wa niluu nigba ti ọkọ ofufuru ologun Chad bẹrẹ si I doyi ka ilu lọjọ Ẹti.

"Nigba ti ọkọ ofurufu naa bẹrẹ si I yipo, awọn Boko Haram sa lọ, awon apẹja kan naa si rọna sa nipa lilo ọkọ oju omi kekere ."

"Ibẹrubojo gba ọkan awon eeyan bi kaluku ṣe n wa ọna lati sa asala fun ẹmi rẹ.

"Awọn ọkọ oju omi kan ko ero to pọju, wọn si yi si agbami nibi ti wọn ti n gbiyanju lati sa lọ."

Alaga awọn apẹja naa sọ pe ọpọ eeyan lo ri sodo, nigba ti ado oloro pa awọn mi-in.

O ni awọn gba pe o ṣee ṣe ko to eeyan ogoji ( 40), to ti ku latari rogbodiyan yii, nipasẹ ọkọ oju omi wọn to ri somi, atawọn ti ado oloro pa.

"Ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ wa ni a ko ti I ri, awọn kan le pada wale, awọn mi-in si le ṣe bẹẹ di ẹni ti a ko ni I ri mọ."

Bẹẹ ni Alaga awọn apẹja naa wi.

Ijọba Naijiria ati Chad ko ti i kede pe awon apẹja wa lara awon to di oloogbe titi ti a fi pari akojọpọ iroyin yii.

Eyi kọ ni igba akọkọ ti ẹnu yoo kun ikọ ologun Chad pe wọn fa iku araalu

Iku ojiji to pa araalu lasiko yii kọ ni akọkọ iru rẹ to ṣẹlẹ lati ọwọ ikọ ologun Chad.

Loṣu Kẹwaa ọdun 2024, wọn fẹsun kan ikọ ologun Chad pe wọn pa ọpọ eeyan ti won jẹ apẹja ọmọ Naijiria.

Ikọlu naa waye nigba ti ologun Chad ju ado oloro lati pa Boko Haram, lerekusu Tilma, Lake Chad.

Bèbè odo Chad yii to tobi pupọ, o jẹ apa kan omi ati apa kan irà .

O jẹ ibi kan ti Naijiria, Chad, Niger ati Cameroon n ṣe ajọpin rẹ.

Ibẹ ti fi igba pipẹ jẹ ibudo awọn Boko Haram atawọn ẹgbẹ alatako wọn ti a mọ si Islamic State West Africa Province (ISWAP).

Alekun ti ba bi ikọlu ṣe n waye ni ẹkun naa lẹnu lọọlọ yii, bi wọn ṣe n ji awon eeyan gbe nibẹ ni wọn n jẹ ọpọlọpọ agbegbe run.

Èèyàn 12 kú báwọn sọ́jà ṣe ju àdó olóró, àmọ́ iléeṣẹ́ ológun ní agbébọn ni àwọn pa

Awon omo ogun to gbe ibon dani

Oríṣun àwòrán, Others

Ileeṣẹ Ologun Naijiria ti jiyan ṣiṣe ikọlu sawon araalu lasiko ti wọn n gbiyanju lati fi ado oloro tu ibuba awọn agbeṣumọmi ka lati oju ofurufu ni ipinlẹ Niger.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ Ologun Naijiria, Michael Onoja fi lede lọjọ Aiku, ọjọ Kẹwaa, oṣu Karun-un sọ pe awọn agbeṣumọmi ati agbebọn ni awọn ṣe ikọlu si lati oju ofurufu naa.

Onoja ni ileeṣẹ Ologun ṣe iwadii wọn daadaa ti awọn si fidi rẹ mulẹ pe awọn agbebọn n fi ilu Lukupe atawọn ilu mii ni ijọba ibilẹ Shiroro, ipinlẹ Niger ṣe ibugbe ki awọn to lọ ṣekọlu si wọn.

Wọn ni eyi lo mu awọn ṣe oniruuru ikọlu sawọn ilu bii Katerna, Bokko, Kusasu ati Kuduru ni oru mọju ọjọ Abamẹta si ọjọ Aiku.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O fi kun pe iwadii ti awọn ṣe lẹyin ikọlu naa fi han pe ikọlu naa ṣe deedee awọn agbebọn naa paapaa ni awọn ilu bii Kusasu, Katerma ati Bokko.

Amọ niṣe ni awọn araalu kan n fẹsun kan pe ikọlu ti ileeṣẹ Ologun ṣe naa ṣokunfa iku awọn araalu ni ilu Kusasu.

Awọn eeyan naa fẹsun kan pe awọn agbeṣumọmi to n gbiyanju lati sa wọ ipinlẹ Niger lati ipinlẹ Zamfara ni awọn Ologun naa fẹ ṣe ikọlu amọ ti awọn araalu fara gba nibẹ.

Araalu kan to ba awọn akọroyin sọrọ ṣugbọn ti ko fẹ ki wọn darukọ oun sọ pe bii eeyan mejila ni ado oloro awọn ọmọ ba, to si jẹ pe mejila ninu wọn ni ado oloro naa ran lo sọrun lati inu yara wọn ti wọn wa.

Ẹlomiran to tun ba awọn akọroyin sọrọ sọ pe awọn agbebọn ni awọn ọmọ ogun naa fẹ ṣe ikọlu si lati oju ofurufu ṣugbọn to lọ ṣeeṣi ba awaọn araalu.

O ni loootọ ni awọn n gbọ finfin pe awọn agbebọn kan ti ko ara wọn jọ lati ṣekọlu si ilu Erena atawọn ilu mii ni agbegbe naa ti awọn ọmọ si gbiyanju lati fi ado oloro tu wọn ka ki wọn to tẹsiwaju pẹlu ikọlu naa.

O ni lẹyin naa ni awọn agbebọn naa sa kuro, ti wọn si morile awọn ilu to wa ni ijọba ibilẹ Munya.

O fi kun pe ootọ ibẹ ni pe ado oloro awọn ọmọ ogun naa ba awọn araalu nitori awọn agbebọn atawọn araalu jọ n gbe ni agbegbe naa ni ati o maa ṣoro fun awọn ọmọ ogun lati le da awọn agbebọn mọ yatọ sawọn araalu lasan.

Agbebon to le ni aadoje ni a pa ni ilu Kusasu nikan - Ilee

Amọ ileeṣẹ Ologun ninu atẹjade wọn sọ pe agbebọn to le ni aadoje ni awọn sekupa ni ilu Kusasu nikan, tawọn si ri bawọn yooku ṣe n gbiyanju lati sin oku awọn to padanu emi wọn.

O ni awọn tun ṣawari rẹ pe awọn agbebọn to le ni igba ni wọn fi ọkada salọ si agbegbe Zango, tawọn mii si n yọju lati Bokko pẹlu erongba lati ṣekọlu sawọn ilu to sunmọ ibẹ.

Onoja fi kun pe awọn tun ri awọn ikọ agbebọn mii ti wọn korajọ si Kopa, eyi to ṣeeṣe ko jẹ pe wọn fẹ ṣe ikọlu sawọn ohun ini ijọba to w ani agbegbe naa eyi to mu ki ileeṣẹ Ologun tete dawọn lẹkun.

O ni lodi si iroyin to n ja lori ayelujara pe awọn ṣekọlu sawọn araalu lasiko ikọlu naa, o ni gbogbo awọn araalu to n gbe ni ilu naa ni wọn ti ko lọ si Sarkin Pawa fun aabo ẹmi ṣaaju ki ikọlu naa to waye rara.

O woye pe irọ to jina si ootọ ni ẹsun pe ileeṣẹ Ologun ṣekupa awọn araalu.

Agbẹnusọ ileeṣẹ Ologun naa sọ pe sibẹ, awọn ti bẹrẹ iwadii lati fidi rẹ mulẹ tawọn araalu b awa lara awọn ti ado oloro ba, to si jẹjẹ lati tunbọ maa da aabo bo awọn araalu to ba ti n tẹlẹ ofin atawọn ilana ti ijọba ba ti la kalẹ.

Ìgbà mẹ́fà ọ̀tọ̀tọ̀ tí bàálù ológun ti ṣèṣì ju àdó olóró sí aráàlú

  • Oṣu kinni, ọdun 2023

Ko din ni eeyan mẹtadinlaadọta to jade laye lagbege Rukubi, nipinlẹ Nasarawa, nigba ti ado oloro ileeṣẹ ọmọ ogun balẹ sibẹ.

Agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye sunmọ ala ilẹ ipinlẹ Benue ati Nasarawa.

  • Oṣu Keji ọdun 2022

Ninu oṣu keji, ọdun 2022 ni ọkọ ofurufu ọmọ ogun Naijiria ṣekupa ọmọde meje, ti ọpọ eeyan mii si farapa lorilẹ-ede Niger.

Iroyin ni awọn janduklu ni ikọlu naa dojukọ amọ awọn araalu ba a lọ.

  • Oṣu kejila, ọdun 2022

Ninu oṣu Kejila ọdun ni ado oloro ọmọ ogun Naijiria ṣekupa eeyan mẹrinlelọgọta ni ilu Mutumji, ni ijọba ibilẹ Zamfara.

Awọn eeyan to wa nibẹ sọ pe pupọ lara awọn to ku lo jẹ janduku amọ ọpọ araalu naa jade laye ninu ikọlu ọhun.

Lara awọn to ku ni obinrin atawọn ọmọde wa.

  • Oṣu Kẹfa, ọdun 2022

Ileeṣẹ ọmọ ogun sọ nigba naa pe awọn janduku loun n dojukọ ogun naa kọ, kii ṣe araalu.

Agọ awọn janduku ni awọn ọmọ ogun n doju ija kọ ninu oṣu Kẹfa, ọdun 2022 ko to ṣẹṣi pa awọn araalu.

Abule Kunkuna, nijọba ibilẹ Safana to wa ni ipinlẹ Katsina ni iṣẹlẹ ọhun ti waye.

Ọpọ eeyan lo jade laye nibẹ.

  • Ọdun Kẹrin 2021

Ọkọ ofurufu ọmọ ogun kan to n lọ koju ikọ Boko Haram ninu oṣu Kẹrin, ọdun 2021, ṣeṣi sọ ado oloro si awọn akẹgbẹ rẹ.

Iroyin ni ko din ni ogun (20) ọmọ ogun to ba iṣẹlẹ ọhun lọ.

  • Oṣu Kẹsan an, ọdun 2021

Ninu oṣu Kẹsan an, ọdun 2021 kan na, ọkọ ofurufu ọmọ ogun Naijiria ju ado oloro si aarin abule kan ni ijọba ibilẹ Yunusari, nipinlẹ Yobe.

Eeyan mẹwaa lo ba iṣẹlẹ naa lọ.