Ètò ìbúra fún Cyril Ramaphosa sí ipò Ààrẹ lẹ́ẹ̀kejì wáyé ní South Africa

Oríṣun àwòrán, Getty image
Aarẹ Cyril Ramaphosa ti orilẹ-ede South Africa ni wọn ti bura fun lẹẹkeji bayii gẹgẹ bii ẹni ti yoo tun maa tukọ ilu naa lọ.
Ninu ile agbara, Union Buildings, ni eto ibura naa ti wọn pe akori ẹ ni “30 Years of Democracy, Partnership and Growth.” ti waye l’’Ọjọru, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹfa ọdun 2024.
Adajọ agba Raymond Zondo to dari eto, na ọwọ Aarẹ Ramaphosa soke bii aarẹ tuntun lẹyin ibura naa.
Aṣeyọri Aarẹ Ramaphosa lẹẹkeji yii waye lẹyin to fẹyin ẹgbẹ African National Congress (ANC), ti i ṣe alatako rẹ nalẹ ninu eto idibo to waye lorilẹ-ede naa.
Akojọpọ ẹgbẹ ANC, Democractic Alliance atawọn ẹgbẹ mi-in ni ijọba tuntun Ramaphosa ko sinu lẹẹkeji yii.
Ninu ọrọ iṣẹgun rẹ, Aarẹ Ramaphosa gboriyin fun ajọṣepọ ọhun.
O rọ gbogbo ọmọ ilu lati fọwọsowọpọ fun aṣeyori ijọba ati itẹsiwaju orilẹ-ede South Africa.
Lati fi atilẹyin wọn han, awọn aarẹ orilẹ-ede kan ti wa ni South Africa bayii, lara wọn ni Bọla Tinubu lati Naijiria, Mswati Kẹta lati Eswatini, Igbakeji aaré Cuba; Salvador Valdés Mesa, Aarẹ Zimbabwe; Emmerson Mnangagwa.
Awọn mi-in ni Samia Hassan lati Ilẹ OlominiraTanzania, Igbakeji aarẹ Côte d’Ivoire ;Tiemoko Meyliet Koné, Aarẹ Ghana; Nana Akufo ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, SABCNEWS/@LEBOTSHANGELA

Oríṣun àwòrán, SABCNEWS/@LEBOTSHANGELA
Àwọn wo ni yóò wà níjọba Ramaphosa?
Lasiko ti a n kọ iroyin yii, Aarẹ Ramaphosa ko ti i kede awon ti yoo ba a ṣejọba rẹ ti i ṣe ẹlẹẹkeje iru ẹ lorilẹ-ede naa.
Bakan naa ni òye ko ti i foju han rara nipa igba ti yoo ṣe ikede ọhun.
Bo tilẹ jẹ pe awọn ẹgbẹ bii DA, IFP, Patriotic Alliance (PA) ati awọn ẹgbẹ kekere yooku yoo maa nireti ati kopa ninu ijọba tuntun yii, ki wọn le jẹre iṣẹ ti wọn ṣe .
Ni 2019 ti Ramaphosa kọkọ gbapo aarẹ South Africa, o fẹrẹ to ọjọ kẹrin ko too kede awọn ti yoo ba a ṣejọba.












