'Ibi iṣẹ́ òòjọ́ ni ọ̀rẹ́ mi lọ ti àkìtan fi wó pa á'

Aworan Ọgbẹni Okuku Prince
Àkọlé àwòrán, Aworan Ọgbẹni Okuku Prince
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ọna ọfun ọna ọrun ti Yoruba n wi ki i ṣe ẹfẹ rara, ewu wa loju ọna ati ri ọwọ mu lọ sẹnu, ki eeyan ma ṣe kongẹ aburu nikan ni agba adua.

Iṣẹ oojọ ni ọdọkunrin kan, Sanya Kezia, ẹni ọdun mọkanlelogun,(21), wa lọ si ori akitan ti wọn n da idọti si lorilẹede Uganda, nibẹ ni awọn idọti ti wọn da jọ ti ya bo o mọlẹ, to si ku.

Nigba to n ṣalaye pẹlu omije loju nipa iku ọrẹ rẹ fun BBC, Okuku Prince, ti oun naa jẹ ẹni to n ṣa ilẹ lori akitan ko too le jẹun, sọ pe abẹ idọti rẹpẹtẹ ni wọn ti fa oku ọrẹ oun yọ.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ibudo idalẹ si to ti le logun ọdun si asiko yii, eyi to wa Kiteezi ni Kampala, olu ilu Uganda, ni iku ka Kezia mọ nigba to lọ sibẹ lati ṣa ohun ti awọn eeyan da sori aatan ṣugbọn to ṣi wulo.

Ọpọ ọdọ ni Uganda lo maa n lọ ṣa awọn nnkan bii ike, igo, nnkan elo ile, aṣọ ati bẹẹ bẹẹ lọ ti awọn eeyan ba da sori akitan.

Wọn yoo fọ awọn nnkan elo naa yoo mọ toni, wọn yoo si tun un ta fawọn to ba nilo rẹ, ibi ti wọn ti n ri ọwọ mu lọ sẹnu niyẹn.

Eyi ni Oloogbe Kezia lọọ ṣe lori aatan lọjọ naa bi ọrẹ rẹ ṣe wi, nigba naa ni òketè ilẹ to ti ga bii oke si ya lulẹ, to bo Kezia ati awọn eeyan to to ọgbọn (30) mi-in mọlẹ, ti gbogbo wọn ku pata si oko iwa-nnkan-jẹ loṣu Kẹjọ ọdun 2024!

"O da bii pe awọn eeyan kan ṣi wa labẹ okete ilẹ to wo naa, ti wọn ko ti i ri wọn yọ."

Okuku lo sọ bẹẹ fun BBC.

Kí ló dé táwọn ọ̀dọ́ di aṣalẹ̀jẹun ní Uganda?

Ori akitan naa pẹlu awọn ẹrọ katakata to n ṣiṣẹ nibẹ

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ori akitan naa pẹlu awọn ẹrọ katakata to n ṣiṣẹ nibẹ
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Airi iṣẹ ṣe awọn ọdọ gbilẹ pupọ lorilẹ ede Uganda, o si ti di ohun to n fa ọpọ awọn ọdọ lọ sibi iṣẹ ẹgbin to tun mu iku lọwọ yii.

Nigba ti idọti pa ọpọ eeyan yii, ijọba ibilẹ ati ti apapọ bẹrẹ si i naka aleebu sira wọn.

Ikini n sọ pe ikeji ni ko ṣe ojuṣe rẹ, bẹẹ ni ikeji naa n sọ pe ẹni akọkọ ni ko gbe igbesẹ to yẹ.

Bẹẹ ni oku awọn eeyan mi-in ṣi wa labẹ akitan naa di asiko yii, ti ko sẹni kan ti yoo gbe wọn sin, debi ti wọn yoo tilẹ gba ẹyẹ ikẹyin.

Loootọ ni wọn ti sanwoo gba-ma-binu fawọn to padanu eeyan wọn bi wọn ṣe wi, ṣugbọn wọn ko fun awọn to padanu ile nitosi akitan ni nnkan kan.

Ninu alaye to ṣe fun BBC, Okuku to n kẹkọọ nipa imofin ni Yunifasiti Islamic, ni Uganda tẹlẹ ko too di aṣalẹjẹun, sọ pe:

" Ààbò ko si fun wa nibi rara. Afi ti wọn ba tun un ṣe (Akitan naa lo n mẹnuba), abi ti wọn ba jẹ ko di ilẹẹlẹ, ko ma ga mọ. Ai jẹ bẹẹ, ẹmi awọn eeyan ko de rara ni."

Ai ri owo ileewe san mọ lo sọ Okuku di ẹni to n ṣa idọti lori akitan ko too le jẹun, owo to si n ri nibẹ naa ko ju owo ounjẹ lọ.

"Mo maa n wa sori aatan yii laaarọ lati ṣa lailọọnu, mo maa fọ wọn ma a si i ta a . Mo n pa ẹgbẹrun mẹwaa ṣilẹ lori ẹ " (10,000 shillings) owo yii jẹ $2.70, tabi £2.10]lojumọ."

Okuku lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.

Nigba ti ori akitan ti wọn ti n rowo ounjẹ oojọ si ti wo bayii, ọna atijẹ ti duro, ọna aabo fun ẹmi rẹ lo ṣe pataki si i bayii .

"Awọn alaṣẹ n reti esi lori akitan to wo naa ati bi wọn yoo ṣe nawo lorii rẹ."

Dokita Sarah Karen Zalwango, olori tuntun lẹka to n ri si itọju araalu ni Kampala, 'Kampala Capital City' Authority (KCCA) lo sọ bẹẹ.

'Ọgbọ́n orí ni kò tó tí àkìtàn fi ya lé àwọn èèyàn lórí'

O le ni igba eeyan to padanu ile wọn nigba ti akitan Kiteezi wo loṣu kẹjọ.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, O fẹrẹ to igba eeyan to padanu ile wọn nigba ti akitan Kiteezi wo loṣu kẹjọ.

Igbagbọ awọn eeyan kan ni Uganda lori iṣẹlẹ yii ni pe awọn to yẹ ko mojuto ori akitan naa ni ko lo ọgbọn ori wọn nibi to yẹ.

Awọn wọnyi sọ pe ko si bi akitan Kiteezi to ga bii oke ko ṣe ni i ya lulẹ lọjọ kan, nitori wọn ti fi ọgbọn to yẹ ki wọn lo ko ma baa ya tafala.

"Bawo lẹ ṣe maa ko eeyan miliọnu mẹrin pọ, ti ẹ si maa maa da gbogbo idọti ti wọn n ṣe si oju kan naa lai ya eyi to le di yẹpẹ ati eyi ti ko ni i yipada lailai si oju kan naa, kẹ ẹ si ro pe ko ni i ya lulẹ. Rara o.

"Bẹẹ yẹn kọ lo yẹ ka ṣe e, ṣugbọn a ti n ṣe bẹẹ bayii o ti ju ogun ọdun lọ."

Frank Muramuzi, alaato ilu to n gbe ni Kampala lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.

Ọdun 1996 ni wọn ti da ori akitan Kiteezi silẹ, banki agbaye si n pese owo iranwọ fun wọn lati ri i pe ori akitan kan ṣoṣo to wa ni Kampala naa n ri bo ṣe yẹ ko ri.

Ṣugbọn awọn eeyan ilu Kampala ti pọ si i, idọti ti wọn n ṣe naa ti ju ti tẹlẹ lọ pẹlu, ni ori akitan kan ṣoṣo

Lapa Ariwa to wa, o ti gba saare ilẹ mẹtadinlogoji (37 acres), eyi tobi to bẹẹ ti wọn le yọ ori papa bọọlu mejileologun (22) nibẹ.

Bẹẹ naa si ni ọlọkan-o-jọkan ẹyẹ kun ori akitan ọhun.

Idọti ti wọn n ṣe ni Kampala lojumọ bi onka ṣe wi, jẹ 2, 500, idaji rẹ lo n lọ sori aatan Kiteezi.

Ṣugbọn iṣoro ibẹ ni pe aatan Kiteezi ko ni ibi ti wọn ti n yi idọti pada di nnkan mi-in ti yoo tun wulo, bẹẹ ni ko si ilana ti wọn fi n sun ilẹ ti oyinbo n pe ni incineration.

"Bi wọn ṣe n da idọti to n ga si i, bẹẹ ni isalẹ ilẹ naa yoo maa dinku lagbara, ko ni I le ru ẹru to wuwo mọ.

Frank Muramuzi ni iṣoro yii ṣee koju nirọrun, bijọba ba ṣetan lati ṣabojuto ohun to n lọ layika ati ohun ti awọn eeyan ilu nilo.

O ni bi wọn ba ti ṣe bẹẹ ni, ijamba to fa iku ọpọ eeyan ni Kiteezi ko ba ma ṣẹlẹ.

James Bond Kunobere, ọga to n ri si itọju ẹgbin ni Kampala, loun gba pe itaniji ni ohun to ṣẹlẹ ni Kiteezi jẹ fun ijọba.

O ni ijọba Uganda ti ṣetan lati sọ idọti di nnkan mi-in to wulo, wọn yoo si fopin si idọti ti ko yẹ.

Ṣugbọn wọn fẹ ki araalu naa kopa nibẹ, wọn ni ki wọn maa ya idọti sọtọ.

Eyi to ṣee yipada di nnkan eelo ko gbọdọ maa wa pẹlu awọn idọti bii ajẹku ounjẹ ti ko wulo fun nnkan kan, gẹgẹ bi wọn ṣe sọ.