DR Congo kéde ẹ̀bùn $5m fún ẹnikẹ́ni tó bá báwọn mú olórí ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀

Oríṣun àwòrán, AFP
Ìjọba orílẹ̀ èdè Democratic Republic of Congo ti kéde fífún ẹnikẹ́ni tó bá le nawọ́ ìjọba sí ibi tí àwọn olórí ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ mẹ́ta tó ń gba ìlú mọ́ wọn ní ẹkùn ìlà oòrùn orílẹ̀ èdè náà láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí ní owó $5m.
Adarí àjọ ètò ìdìbò DR Congo tẹ́lẹ̀ rí, Corneille Nangaa tó ń darí ikọ̀ Congo River Alliance èyí tí ikọ̀ ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ M23 náà wà nínú rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn mẹ́ta tí ìjọba kéde pé wọ́n ń wá.
Bákan náà ni àwọn olórí ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ méjì míì, Sultani Makenga àti Bertrand Bisimwa ló fi jẹ́ àwọn mẹ́ta tí owó náà wà fún.
Ní ọdún tó kọjá, ilé ẹjọ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn ológún ṣe ìdájọ́ àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà láì sí wón níbẹ̀, tí ilé ẹjọ́ náà sì dájọ́ ikú fún wọn fẹ́sùn ìdìtẹ̀ mọ́ ìjọba.
Ìjọba tún kéde fífún ẹni tó bá le ṣe atọ́nà bí wọ́n ṣe le mú àwọn abẹ́ṣinkáwọ́ wọn ní owó $4m.
Àmọ́ ó jọ wí pé ó ṣòro gidi láti fi páńpẹ́ òfin gbé àwọn afurasí náà.
Láti bíi ọ̀sẹ̀ mélòó kan sẹ́yìn, ó ṣòro fún iléeṣẹ́ ológun DR Congo láti kojú àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ tí orílẹ̀ èdè Rwanda ń ṣe àtìlẹyìn fún, tí wọ́n sì ti gba ọ̀pọ̀ ìlú táwọn ohun àlùmọ́nì pọ̀ níbẹ̀ lẹ́ka ìlà oòrùn DR Congo tó fi mọ́ àwọn ìlú méjì tó tóbi jùlọ ní ẹkùn náà Goma àti Bukavu.
Ààrẹ DR Congo, Félix Tshisekedi ti ń gbìyànjú láti mú kí àwọn orílẹ̀èdè àgbáyé kojú oro sí Rwanda fún ṣíṣe àtìlẹyìn fáwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ náà.
Ní ọdún tó kójá, ìjábọ̀ àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé kan sọ pé kò dín ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) àwọn ọmọ ogun Rwanda tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ikọ̀ M23 ní DR Congo.
Ẹ̀gbẹ̀lẹ́gbẹ̀ àwọn èèyàn ni wọ́n ti bá ogun lọ láti ìgbà tí ìjà tí wáyé, tí ọ̀pọ̀ sì ti di aláìnílé lórí mọ́ bí wọ́n ṣe ń sá kúrò ní ilé wọn.
Ìjọba DR Congo tún ń pè fún àtìlẹyìn orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà láti kojú àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ náà pẹ̀lú àdéhùn pé àwọn yóò jẹ́ kí Amẹ́ríkà ní àǹfàní sí ohun àlùmọ́nì àwọn.
DR Congo ń fẹ̀sùn kan Rwanda pé ó fẹ́ gba àkóso àwọn ohun àlùmọ́nì àwọn tó fi mọ́ wúrà àti coltan tí wọ́n máa ń lò láti fi pèsè àwọn ohun ẹ̀rọ bíi fóònù àti kọ̀mpútà.
Nígbà tó ń fèsì lórí ẹ̀sùn pé ìjọba DR Congo ń gbèrò láti fún Amẹ́ríkà láṣẹ sí ohun àlùmọ́nì rẹ̀ láti kojú àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀, agbẹnusọ fún ìjọba, Tina Salama sọ lójú òpó X rẹ̀ pé ààrẹ Tshisekedi ń ránṣẹ́ sí iléeṣẹ́ Amẹ́ríkà tó ń ra àwọn ohun àlùmọ́nì tí Rwanda ń jí kó ní DR Congo lọ sí Rwanda láti máa rà á lọ́wọ́ àwọn tó jẹ́ ojúlówó ẹni tó ni wọ́n gangan.
Àmọ́ Rwanda ti jiyàn pé àwọn kò jí ohun alùmọ́nì DR Congo wà.
Ṣùgbọ́n Rwanda kò jiyàn mọ́ pé àwọn ń ṣe àtìlẹyìn fún ikọ̀ M23 àmọ́ tó ní àwọn ń gbìyànjú láti rip é aáwọ̀ tó ń wáyé ní DR Congo kò dé ẹkùn ohun.
Rwanda tún fẹ̀sùn ìjọba DR Congo pé wọ́n ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ológun kan ní DR Congo, èyí tí wọ́n gbàgbọ́ pé ó lọ́wọ́ nínú ìpànìyàn tó wáyé ní Rwanda lọ́dún 1994.
Èèyàn tó tó 800,000 ni wọ́n pàdánù ẹ̀mí lásìkò náà, tí ọ̀pọ̀ wọn sì jẹ́ ẹ̀yà Tutsi.
Àwọn ẹ̀yà Tutsi ló ń darí ikọ̀ ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ M23 àti ìjọba Rwanda.
Ìjọba DR Congo ní àwọn kò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ikọ̀ FDLR tí Rwanda ń fẹ̀sùn kàn pé ó ṣekúpa àwọn èèyàn òhun.















