Wo ọ̀pọ̀ ìgbésẹ̀ tàwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà gbé láti dáààbò bo ìbò wọn

Oríṣun àwòrán, Mr Macaroni/Twitter
Ètò ìdìbò sípò ààrẹ àti àwọn aṣojú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àpàpọ̀ ìlú Abuja tó wáyé ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ni ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn jáde láti lọ ṣe ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ Nàìjíríà rere.
Ìgbà àkọ́kọ́ rèé ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí ẹgbẹ́ òṣèlú mẹ́ta sí mẹ́rin yóò máa léwájú nínú àwọn tó ń díje dupò ààrẹ.
Bí ìbò dídì ṣe di ohun tó ń di alẹ́ ọjọ́ Àìkú kó tó parí ní ọ̀pọ̀ àwọn ibùdó ìdìbò nítorí àwọn kùdìẹ̀kudiẹ kan tí ọ̀gá àgbà àjọ INEC, Mahmmod Yakubu fi orí rẹ̀ sọ ìpèníjà láti kó àwọn ohun èlò lọ sí ibùdó ìdìbò, ọ̀pọ̀ àwọn olùdìbò ló dúró sí ibùdó ìdì bò láti dá ààbò bo ìbò wọn.
Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn lọ dúró sí ibùdó ìdìbò àti ibi tí wọ́n ti ń ṣe àkójọ àwọn èsì ìbò láti ri dájú pé àwọn òṣìṣẹ́ INEC fi èsì ìbò wọn ṣọwọ́ sórí ìtàkùn ayélujára INEC ìyẹn IREV.
Gẹ́gẹ́ bí ìgbésẹ̀ láti dín ṣíṣe èèrú ìbò kù, gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ INEC ní ibùdó ìdìbò lábẹ́ òfin gbọ́dọ̀ fi èsì ìbò ṣọwọ́ sí IREV yìí fún gbogbo ènìyàn láti rí.
Ẹ̀wẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbò dídì tètè parí ní àwọn ibùdó ìdìbò kan síbẹ̀ àwọn òṣìṣẹ́ INEC yìí kò ríbi fi èsì ìbò ṣọwọ́ sórí IREV lẹ́yìn tí wọ́n kéde wọn tán ní àwọn ibùdó ìdìbò yìí.
Iléeṣẹ́ ìròyìn BBC wòye pé títí di nǹkan bíi aago mẹ́jọ alẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta tí ètò ìbò wáyé, kò ì tíì sí èsì ìbò ààrẹ kankan ní gbogbo àwọn ibùdó ìbò 176,848 lórí IREV bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ti àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àpapọ̀ ti wà níbẹ̀.
Gbogbo nǹkan tó bá gbà la máa fún-un
Adewale Adebayo, gbajúgbajà adẹ́rìnínpòṣónú nnì tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Mr Macaroni ní òun wà ní ibùdó ìdìbò òun títí di aago mọ́kànlá kọjá ìṣẹ̀jú mẹ́rìnlá láti ri pé àwọn òṣìṣẹ́ INEC fi èsì ìbò náà ṣọwọ́ sí IREV.
Ó kọ sójú òpó Twitter rẹ̀ pé “Ìfẹ́ àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ ṣẹ fún Nàìjíríà rere.”
Ní ibùdó ìdìbò Lugard/Barrow yúníìtì 003 ní agbègbè Ikoyi, ìpínlẹ̀ Eko, Stella Chisom tó ń dìbò fún ìgbà àkọ́kọ́ ní òun dúró fún wákàtí mẹ́wàá gbáko láti lè ri pé òun dá ààbò bo ìbò òun.
“Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí yóò ṣiṣẹ́ fún gbogbo ènìyàn ni mo ń fẹ́, èyí tí inú àwọn ọ̀dọ́ yóò máa fi ìdùnnú dárúkọ wí pé ibẹ̀ ni àwọn ti wá, èyí tó ṣe é fi kalẹ̀ fún ìran tó ń bọ̀”, ó sọ fún BBC.
Olùdìbò mìíràn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Emma gbé omi, àga, tábìlì fún àwọn òṣìṣẹ́ INEC lásìkò tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ wọn.
Emma ní òun náà ti ṣiṣẹ́ fún INEC nígbà tí òun ń sin ilẹ̀ baba òun lọ́dún 2019 àti pé kìí ṣe ohun tó pọ̀ jù fún ènìyàn láti ṣe láti mú àyípadà rere bá Nàìjíríà.
Mo fi ọkọ̀ mi pèsè iná fún ìbò dídì

Oríṣun àwòrán, @FlyGirl_Sue/Twitter
Ní Durumi II ní Abuja, arábìnrin kan àti àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà mìíràn ní láti dúró di aago méjìlá alẹ́ kọjá láti ri pé èsì ìbò wọn fífi ṣọwọ́ sórí IREV.
Nígbà tí iná mọ̀nàmọ́ná lọ, Susan tan iná ọkọ̀ rẹ̀ láti lè fi pèsè iná fún àwọn òṣìṣẹ́ INEC láti lè fi èsì ìbò náà sórí ayélujára.
“Mi ò ní ẹgbẹ̀rún $120 láti fi ra ìwé ìgbélùú orílẹ̀ èdè mìíràn , orílẹ̀ èdè tí mo ní rèé, ibi ni a máa wà tí gbogbo rẹ̀ fi máa parí”, ó kọ sójú òpó rẹ̀ ní Twitter.












